Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Syria

235 ẹsẹ · 61 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Èmi yóò ṣẹ́ ọ̀pá ìdábùú Damasku; Èmi yóò sì pa ọba tí ó wà ní àfonífojì Afeni run àti ẹni tí ó di ọ̀pá aládé mú ní Beti-Edeni. Àwọn ará a Aramu yóò lọ sí ìgbèkùn sí Kiri,” ni Olúwa wí.

  2. Ọ̀rọ̀-ìmọ̀. Ọ̀rọ̀ Olúwa kọjú ìjà sí Hadiraki, Damasku ni yóò sì jẹ́ ibi ìsinmi rẹ̀; nítorí ojú Olúwa ń bẹ lára ènìyàn, àti lára gbogbo ẹ̀yà Israẹli.

  3. Òkìkí rẹ̀ sì kàn yí gbogbo Siria ká; wọ́n sì gbé àwọn aláìsàn tí ó ní onírúurú ààrùn, àwọn tí ó ní ìnira ẹ̀mí èṣù, àti àwọn ti o ní wárápá àti àwọn tí ó ní ẹ̀gbà; ó sì wò wọ́n sàn.

  4. (Èyí ni ìkọ sínú ìwé èkínní tí a ṣe nígbà tí Kirene fi jẹ baálẹ̀ Siria.)

  5. Ní ìdáhùn sí èyí ó wí pé, “Ẹ̀yin arákùnrin àti ẹ̀yin baba, ẹ fetísílẹ̀ sí mi! Ọlọ́run ògo fi ara hàn fún Abrahamu baba wa, nígbà tí ó wà ni Mesopotamia, kí ó to ṣe àtìpó ni Harani.

  6. Wọn sì kọ ìwé lé wọn lọ́wọ́ báyìí pé, Àwọn aposteli, àti àwọn alàgbà, tí ó jẹ́ ti aláìkọlà tí ó wà ní Antioku, àti ní Siria, àti ní Kilikia.

  7. Ó sì la Siria àti Kilikia lọ, ó ń mú ìjọ ní ọkàn le.

  8. Paulu sì dúró sí i níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, nígbà tí ó sì dágbére fún àwọn arákùnrin, ó bá ọkọ̀ ojú omi lọ si Siria, àti Priskilla àti Akuila pẹ̀lú rẹ̀; ó tí fá orí rẹ̀ ni Kenkerea, nítorí tí ó ti jẹ́ ẹ̀jẹ́.

  9. Nígbà tí àwa sì ń wo Saipurọsi lókèèrè, a sì fi í sí ọwọ́ òsì, a fi orí ọ́kọ̀ le Siria, a sì gúnlẹ̀ ni Tire; nítorí níbẹ̀ ni ọkọ̀ yóò tí já ẹrù sílẹ̀.

  10. Lẹ́yìn náà mo sì wá sí agbègbè Siria àti ti Kilikia.