Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Psalms

896 ẹsẹ · 16 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ẹ má ṣe gbe ìwo yín sókè sí ọ̀run; ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọrùn líle.”

  2. Nítorí ìgbéga kò ti ìlà-oòrùn wá tàbí ní ìwọ̀-oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe láti gúúsù wá.

  3. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni olùdájọ́; Ó ń rẹ ẹnìkan sílẹ̀, ó sì ń gbé ẹlòmíràn ga.

  4. Ní ọwọ́ Olúwa ni ago kan wà, ọtí wáìnì náà sì pọ́n, ó kún fún àdàlú, ó fún ọtí àdàlú tí a pò mọ́ òórùn dídùn tí ó tú jáde, àwọn ènìyàn búburú ayé gbogbo mú u pátápátá.

  5. Ṣùgbọ́n èmi, ó máa ròyìn rẹ títí láé; èmi ó kọrin ìyìn sí Ọlọ́run Jakọbu.

  6. Èmi ó gé ìwo gbogbo ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n ìwo àwọn olódodo ni a ó gbéga.

  7. Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu ti Asafu. Orin. Ní Juda ni a mọ Ọlọ́run; orúkọ rẹ̀ sì lágbára ní Israẹli

  8. Àgọ́ rẹ̀ wà ní Salẹmu, ibùgbé rẹ̀ ni Sioni.

  9. Níbẹ̀ ni ó ṣẹ́ ọfà, asà àti àwọn idà, ohun ìjà ogun. Sela.

  10. Ìwọ ni ògo àti ọlá, ju òkè ńlá ìkógun wọ̀nyí lọ.

  11. A kó àwọn alágídí ọkàn ní ìkógun wọ́n sun oorun ìgbẹ̀yìn wọn; kò sí ọ̀kan nínú àwọn akọni tó lè gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè.

  12. Ní ìfibú rẹ, Ọlọ́run Jakọbu, àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun sì dùbúlẹ̀ síbẹ̀.

  13. Ìwọ nìkan ni ó yẹ kí a bẹ̀rù. Ta ló lé dúró níwájú rẹ, nígbà tí ìwọ bá ń bínú?

  14. Ìwọ ń ṣe ìdájọ́ láti ọ̀run, ilé ayé bẹ̀rù, ó sì dúró jẹ́ẹ́,

  15. nígbà tí, ìwọ Ọlọ́run, bá dìde láti ṣe ìdájọ́, láti gba àwọn ẹni ìnilára ilẹ̀ náà. Sela.

  16. Lóòótọ́, ìbínú rẹ sí àwọn ènìyàn ń mú ìyìn wá fún ọ, ẹni tí ó yọ nínú ìbínú rẹ ní a dá nígbà tí ìwọ bá fi ìbínú ìyókù di ara rẹ ni àmùrè.

  17. Jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì mú un ṣẹ; kí gbogbo àwọn tí ó yí i ká mú ẹ̀bùn wá fún ẹni tí ó tọ́ láti bẹ̀rù.

  18. Ó ké ẹ̀mí àwọn aládé kúrò; àwọn ọba ayé sì ń bẹ̀rù rẹ̀.

  19. Saamu ti Asafu. Ọlọ́run, àwọn orílẹ̀-èdè ti wá ilẹ̀ ìní rẹ; wọ́n ti ba tẹmpili mímọ́ rẹ jẹ́, wọn di Jerusalẹmu kù sí òkìtì àlàpà.

  20. Wọn ti fi ara òkú àwọn ìránṣẹ́ rẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ní oúnjẹ, ẹran-ara àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ fún ẹranko ilẹ̀.

  21. Wọ́n tu ẹ̀jẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí omi yí Jerusalẹmu ká, kò sì ṣí àwọn tí yóò sìn wọ́n.

  22. Àwa di ohun ẹ̀gàn sí àwọn tí ó yí wa ká, àbùkù àti ìfiṣe ẹlẹ́yà sí àwọn tí ó yí wa ká.

  23. Nígbà wo, Olúwa? Ní ìwọ ó máa bínú títí láé? Yóò ti pẹ́ tó ti owú rẹ yóò ha jò bí iná?

  24. Tú ìbínú rẹ jáde sí orílẹ̀-èdè tí kò ní ìmọ̀ rẹ, lórí àwọn ìjọba tí kò pe orúkọ rẹ;

  25. nítorí wọ́n ti run Jakọbu wọ́n sì sọ ibùgbé rẹ di ahoro.