Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Psalms: Didactic songs composed by Moses, celebrating the providence, righteousness, and judgments of God

43 ẹsẹ · 16 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Didactic songs composed by Moses, celebrating the providence, righteousness, and judgments of God

  1. Fetísílẹ̀, ẹ̀yin ọ̀run, èmi yóò sọ̀rọ̀; ẹ gbọ́, ìwọ ayé, ọ̀rọ̀ ẹnu mi.

  2. Jẹ́ kí ẹ̀kọ́ ọ̀ mi máa rọ̀ bí òjò, kí àwọn ọ̀rọ̀ mi máa sọ̀kalẹ̀ bí ìrì, bí òjò wíníwíní sára ewéko tuntun, bí ọ̀wààrà òjò sára ohun ọ̀gbìn.

  3. Èmi yóò kókìkí orúkọ Olúwa. Ẹyin títóbi Ọlọ́run wa!

  4. Òun ni àpáta, iṣẹ́ ẹ rẹ̀ jẹ́ pípé, gbogbo ọ̀nà an rẹ̀ jẹ́ òdodo. Ọlọ́run olóòtítọ́ tí kò ṣe àṣìṣe kan, Ó dúró ṣinṣin, òdodo àti òtítọ́ ni òun.

  5. Wọ́n ti ṣe iṣẹ́ ìbàjẹ́ sọ́dọ̀ ọ rẹ̀; fún ìtìjú u wọn, wọn kì í ṣe ọmọ rẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n ìran tí ó yí sí apá kan tí ó sì dorí kodò.

  6. Ṣé báyìí ni ẹ̀yin yóò ṣe san an fún Olúwa, ẹ̀yin aṣiwèrè àti aláìgbọ́n ènìyàn? Ǹjẹ́ òun kọ́ ni baba yín, Ẹlẹ́dàá yín, tí ó dá a yín tí ó sì mọ yín?

  7. Rántí ìgbà láéláé; wádìí àwọn ìran tí ó ti kọjá. Béèrè lọ́wọ́ baba à rẹ yóò sì sọ fún ọ, àwọn àgbàgbà rẹ, wọn yóò sì ṣàlàyé fún ọ.

  8. Nígbà tí Ọ̀gá-ògo fi ogún àwọn orílẹ̀-èdè fún wọn, nígbà tí ó pín onírúurú ènìyàn, ó sì gbé ààlà kalẹ̀ fún àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí iye ọmọkùnrin Israẹli.

  9. Nítorí ìpín Olúwa ni àwọn ènìyàn an rẹ̀, Jakọbu ni ìpín ìní i rẹ̀.

  10. Ní aginjù ni ó ti rí i, ní aginjù níbi tí ẹranko kò sí. Ó yíká, ó sì tọ́jú rẹ̀, ó pa á mọ́ bí ẹyin ojú u rẹ̀.

  11. Bí idì ti í ru ìtẹ́ rẹ̀ ti ó sì ń rábàbà sórí ọmọ rẹ̀, tí ó na ìyẹ́ apá rẹ̀ láti gbé wọn ki ó sì gbé wọn sórí ìyẹ́ apá rẹ̀.

  12. Olúwa ṣamọ̀nà; kò sì sí ọlọ́run àjèjì pẹ̀lú rẹ̀.

  13. Ó mú gun ibi gíga ayé ó sì fi èso oko bọ́ ọ. Ó sì jẹ́ kí ó mú oyin láti inú àpáta wá, àti òróró láti inú akọ òkúta wá.

  14. Pẹ̀lú u wàràǹkàṣì àti wàrà àgùntàn àti ti àgbò ẹran àti pẹ̀lú ọ̀rá ọ̀dọ́-àgùntàn àti ewúrẹ́, pẹ̀lú àgbò irú u ti Baṣani tí ó sì mu ẹ̀jẹ̀ èso àjàrà, àní àti wáìnì.

  15. Jeṣuruni sanra tán ó sì tàpá; ìwọ sanra tán, ìwọ ki tan, ọ̀rá sì bò ọ́ tán. O kọ Ọlọ́run tí ó dá ọ o sì kọ àpáta ìgbàlà rẹ.

  16. Wọ́n sì fi òrìṣà mú un jowú, ohun ìríra ni wọ́n fi mú un bínú.

  17. Wọ́n rú ẹbọ sí iwin búburú, tí kì í ṣe Ọlọ́run, ọlọ́run tí wọn kò mọ̀ rí, ọlọ́run tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ farahàn láìpẹ́, ọlọ́run tí àwọn baba yín kò bẹ̀rù.

  18. Ìwọ kò rántí àpáta, tí ó bí ọ; o sì gbàgbé Ọlọ́run tí ó dá ọ.

  19. Olúwa sì rí èyí ó sì kọ̀ wọ́n, nítorí tí ó ti bínú nítorí ìwà ìmúnibínú àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ.

  20. Ó sì wí pé, “Èmi yóò pa ojú mi mọ́ kúrò lára wọn, èmi yóò sì wò ó bí ìgbẹ̀yìn in wọn yóò ti rí; nítorí wọ́n jẹ́ ìran alágídí, àwọn ọmọ tí kò sí ìgbàgbọ́ nínú wọn.

  21. Wọ́n fi mí jowú nípa ohun tí kì í ṣe Ọlọ́run, wọ́n sì fi ohun asán an wọn mú mi bínú. Èmi yóò mú wọn kún fún ìlara láti ọ̀dọ̀ àwọn tí kì í ṣe ènìyàn; èmi yóò sì mú wọn bínú láti ọ̀dọ̀ aṣiwèrè orílẹ̀-èdè.

  22. Nítorí pé iná kan ràn nínú ìbínú mi, yóò sì jó dé ipò ikú ní ìsàlẹ̀. Yóò sì run ayé àti ìkórè e rẹ̀ yóò sì tiná bọ ìpìlẹ̀ àwọn òkè ńlá.

  23. “Èmi yóò kó àwọn ohun búburú lé wọn lórí èmi ó sì na ọfà mi tán sí wọn lára.

  24. Èmi yóò mú wọn gbẹ, ooru gbígbóná àti ìparun kíkorò ni a ó fi run wọ́n. Pẹ̀lú oró ohun tí ń rákò nínú erùpẹ̀.

  25. Idà ní òde, àti ẹ̀rù nínú ìyẹ̀wù, ni yóò run ọmọkùnrin àti wúńdíá. Ọmọ ẹnu ọmú àti arúgbó eléwú irun pẹ̀lú.