Philistia
A tún mọ̀ ọ́n sí: Palestina
33.5600, 35.3600 Wo lórí Google Maps
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Philistia
Orílẹ̀-èdè yóò gbọ́ wọn yóò wárìrì. Ìkáàánú yóò mi àwọn ènìyàn Filistia.
Moabu ní ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi, lórí Edomu ní mo bọ́ bàtà mi sí; lórí Filistia ni mo kígbe ayọ̀.”
“Èmi ó dárúkọ Rahabu àti Babeli láàrín àwọn tí ó jẹ́wọ́ mi: Filistia pẹ̀lú, àti Tire, pẹ̀lú Kuṣi, yóò sọ pé, ‘Èyí ni a bí ní Sioni.’ ”
Moabu sì ni ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi, lórí Edomu ni èmi ó bọ́ bàtà mi sí, lórí òkè Filistia ni èmi yóò hó ìhó ayọ̀.”
Má ṣe yọ̀, gbogbo ẹ̀yin Filistia, pé ọ̀pá tí ó lù ọ́ ti dá; láti ibi gbòǹgbò ejò náà ni paramọ́lẹ̀ yóò ti hù jáde, èso rẹ̀ yóò sì jẹ́ oró ejò tí í jóni.
Hu, ìwọ ẹnu-ọ̀nà! Kígbe, ìwọ ìlú! Yọ́ kúrò, gbogbo ẹ̀yin Filistia! Èéfín kurukuru kan ti àríwá wá, kò sì ṣí amóríbọ́ kan nínú ẹgbẹ́ wọn.