Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Psalms: Psalms of Affliction

315 ẹsẹ · 16 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Psalms of Affliction

  1. Saamu ti Dafidi. Nígbà ti ó sá fún ọmọ rẹ̀ Absalomu. Olúwa, báwo ni àwọn ọ̀tá mi ṣe pọ̀ tó báyìí! Báwo ni àwọn ti ó dìde sí mi ṣe pọ̀ tó!

  2. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ń sọ ní ti tèmi, pé “Ọlọ́run kò nígbà á là.” Sela.

  3. Ṣùgbọ́n ìwọ ni asà yí mi ká, Olúwa; ìwọ fi ògo fún mi, ìwọ sì gbé orí mi sókè.

  4. Olúwa ni mo kígbe sókè sí, ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ rẹ̀ wá. Sela.

  5. Èmi dùbúlẹ̀, mo sì sùn; mo sì tún padà jí, nítorí Olúwa ni ó ń gbé mi ró.

  6. Èmi kì yóò bẹ̀rù ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn tí wọ́n rọ̀gbà yí mi ká.

  7. Dìde, Olúwa! Gbà mí, Ọlọ́run mi! Lu gbogbo àwọn ọ̀tá mi ní àgbọ̀n; kí o sì ká eyín àwọn ènìyàn búburú.

  8. Láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ìgbàlà ti wá. Kí ìbùkún rẹ wà lórí àwọn ènìyàn rẹ. Sela.

  9. Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu ti Dafidi. Dá mi lóhùn nígbà tí mo bá pè ọ́, ìwọ Ọlọ́run òdodo mi. Fún mi ní ìdáǹdè nínú ìpọ́njú mi; ṣàánú fún mi, kí o sì gbọ́ àdúrà mi.

  10. Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, ẹ̀yin ọmọ ènìyàn, tí ẹ ó ṣe sọ ògo mi di ìtìjú? Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, tí ẹ̀yin yóò ṣe fẹ́ràn ìtànjẹ àti tí ẹ̀yin yóò fi máa wá ọlọ́run èké?

  11. Ṣùgbọ́n kí ẹ mọ̀ pé, Olúwa ti ya ẹni olódodo sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀; Olúwa yóò gbọ́ nígbà tí mo bá pè é.

  12. Ẹ bínú ẹ má ṣe ṣẹ̀, nígbà tí ẹ bá wà lórí ibùsùn yín, ẹ bá ọkàn yín sọ̀rọ̀, kí ó sì dákẹ́ jẹ́.

  13. Ẹ rú ẹbọ òdodo kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.

  14. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló ń béèrè pé, “Ta ni yóò ṣe rere fún wa?” Olúwa, jẹ́ kí ojú rẹ mọ́lẹ̀ sí wa lára,

  15. Ìwọ ti fi ayọ̀ púpọ̀ kún ọkàn mi ju ìgbà tí hóró irúgbìn àti wáìnì tuntun wọ́n pọ̀ fún mi lọ.

  16. Èmi yóò dùbúlẹ̀, èmi ó sì sùn ní àlàáfíà, nítorí ìwọ nìkan, Olúwa, ni o mú mi gbé láìléwu.

  17. Fún adarí orin. Fún ohun èlò orin fífọn. Saamu ti Dafidi. Fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, Olúwa, kíyèsi àròyé mi.

  18. Fi etí sílẹ̀ sí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́, ọba mi àti Ọlọ́run mi, nítorí ìwọ ni mo gba àdúrà sí.

  19. Ní òwúrọ̀, Olúwa, ìwọ yóò gbọ́ ohùn mi; ní òwúrọ̀, èmi yóò gbé ẹ̀bẹ̀ mi sí iwájú rẹ̀ èmi yóò sì dúró ní ìrètí.

  20. Nítorí ìwọ kì í ṣe Ọlọ́run tí ó ní inú dídùn sí búburú; bẹ́ẹ̀ ni ẹni ibi kò le è bá ọ gbé.

  21. Àwọn agbéraga kò le è dúró níwájú rẹ̀. Ìwọ kórìíra gbogbo àwọn aṣebi;

  22. ìwọ yóò pa àwọn tí ń ṣe èké run. Apani àti ẹni ẹ̀tàn ènìyàn ni Olúwa yóò kórìíra.

  23. Ṣùgbọ́n èmi, nípa títóbi àánú rẹ̀, èmi yóò wá sínú ilé rẹ̀; ní tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni èmi yóò tẹríba sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀.

  24. Tọ́ mi, Olúwa, nínú òdodo rẹ, nítorí àwọn ọ̀tá mi, mú ọ̀nà rẹ tọ́ níwájú mi.

  25. Kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ẹnu wọn tí a lè gbàgbọ́; ọkàn wọn kún fún ìparun. Ọ̀nà ọ̀fun wọn ni isà òkú tí ó ṣí sílẹ̀; pẹ̀lú ahọ́n wọn ni wọ́n ń sọ ẹ̀tàn.