Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Psalms: Prophetic Psalms

49 ẹsẹ · 16 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Prophetic Psalms

  1. Èéṣe tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń dìtẹ̀, àti tí àwọn ènìyàn ń ṣe rìkíṣí asán?

  2. Àwọn ọba ayé péjọpọ̀ àti àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀ sí Olúwa àti sí ẹni àmì òróró rẹ̀.

  3. Wọ́n sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí a fa ẹ̀wọ̀n wọn já, kí a sì ju ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ wọn nù.”

  4. Ẹni tí ó gúnwà lórí ìtẹ́ lọ́run rẹ́rìn-ín; Olúwa fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà.

  5. Nígbà náà ni yóò bá wọn wí ní ìbínú rẹ̀ yóò sì dẹ́rùbà wọ́n ní ìrunú rẹ̀, ó wí pé,

  6. “Èmi ti fi ọba mi sí ipò lórí Sioni, òkè mímọ́ mi.”

  7. Èmi yóò sì kéde ìpinnu Olúwa: Ó sọ fún mi pé, “Ìwọ ni ọmọ mi; lónìí, èmi ti di baba rẹ.

  8. Béèrè lọ́wọ́ mi, Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀-èdè di ìní rẹ, òpin ilé ayé yóò sì jẹ́ ogún rẹ.

  9. Ìwọ yóò fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn ìwọ yóò sì rún wọn wómúwómú bí ìkòkò amọ̀.”

  10. Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n; ẹ gbọ́ ìkìlọ̀ ẹ̀yin alákòóso ayé.

  11. Ẹ sin Olúwa pẹ̀lú ìbẹ̀rù ẹ sì máa yọ̀ pẹ̀lú ìwárìrì.

  12. Fi ẹnu ko ọmọ náà ní ẹnu, kí ó má ba à bínú, kí ó má ba à pa yín run ní ọ̀nà yín, nítorí ìbínú rẹ̀ lè ru sókè ní ẹ̀ẹ̀kan. Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó fi í ṣe ibi ìsádi wọn.

  13. Miktamu ti Dafidi. Pa mí mọ́, Ọlọ́run, nítorí nínú rẹ ni ààbò mi wà.

  14. Mo sọ fún Olúwa, “Ìwọ ni Olúwa mi, lẹ́yìn rẹ èmi kò ní ìre kan.”

  15. Sí àwọn ènìyàn tí ó wà ní ayé, àwọn ni ológo nínú èyí tí ayọ̀ mí wà.

  16. Ìṣòro àwọn wọ̀n-ọn-nì yóò pọ̀ sí i, àní àwọn tí ń tọ ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn. Ẹbọ ohun mímu ẹ̀jẹ̀ wọn ni èmi kì yóò ta sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò dá orúkọ wọn lẹ́nu mi.

  17. Olúwa, ni ìpín ìní mi tí mo yàn àti ago mi, ó ti pa ohun tí í ṣe tèmi mọ́.

  18. Okùn ààlà ilẹ̀ ti bọ́ sí ọ̀dọ̀ mi ní ibi dídára; nítòótọ́ mo ti ní ogún rere.

  19. Èmi yóò yin Olúwa, ẹni tí ó gbà mí ní ìyànjú; ní òru, ọkàn mí ń bá mi sọ̀rọ̀.

  20. Mo ti gbé Olúwa síwájú mi ní ìgbà gbogbo. Nítorí tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mì mí.

  21. Nítorí èyí, ọkàn mi yọ̀, ahọ́n mi pẹ̀lú ń fò fáyọ̀; ara mi pẹ̀lú yóò sinmi ní ààbò,

  22. nítorí ìwọ kò ní fi ọ̀kan sílẹ̀ nínú isà òkú, tàbí kí ìwọ jẹ́ kí ẹni mímọ́ rẹ kí ó rí ìdíbàjẹ́.

  23. Ìwọ ti fi ipa ọ̀nà ìyè hàn mí; Ìwọ yóò kún mi pẹ̀lú ayọ̀ ní iwájú rẹ, pẹ̀lú ìdùnnú ayérayé ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.

  24. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu. Orin. Ó ti fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ sórí òkè mímọ́;

  25. Olúwa fẹ́ràn ẹnu-ọ̀nà Sioni ju gbogbo ibùgbé Jakọbu lọ.