Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Psalms: Penitential Psalms

41 ẹsẹ · 16 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Penitential Psalms

  1. Fún adarí orin. Fún ohun èlò orin olókùn. Gẹ́gẹ́ bí ti ṣeminiti. Saamu ti Dafidi. Olúwa, má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ kí ìwọ má ṣe nà mí nínú gbígbóná ìrunú rẹ.

  2. Ṣàánú fún mi, Olúwa, nítorí èmi ń kú lọ; Olúwa, wò mí sán, nítorí egungun mi wà nínú ìnira.

  3. Ọkàn mi wà nínú ìrora. Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa, yóò ti pẹ́ tó?

  4. Yípadà, Olúwa, kí o sì gbà mí; gbà mí là nípa ìfẹ́ rẹ tí kì í ṣákì í.

  5. Ẹnikẹ́ni kò ni rántí rẹ nígbà tí ó bá kú. Ta ni yóò yìn ọ́ láti inú isà òkú?

  6. Agara ìkérora mi dá mi tán. Gbogbo òru ni mo wẹ ibùsùn mi pẹ̀lú ẹkún, mo sì fi omi rin ibùsùn mi pẹ̀lú omijé.

  7. Ojú mi di aláìlera pẹ̀lú ìbànújẹ́; wọ́n kùnà nítorí gbogbo ọ̀tá mi.

  8. Kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe iṣẹ́ ibi, nítorí Olúwa ti gbọ́ igbe mi.

  9. Olúwa ti gbọ́ ẹkún mi fún àánú; Olúwa ti gba àdúrà mi.

  10. Gbogbo àwọn ọ̀tá mi lójú yóò tì, wọn yóò sì dààmú; wọn yóò sì yípadà nínú ìtìjú àìròtẹ́lẹ̀.

  11. Ti Dafidi. Maskili. Ìbùkún ni fún àwọn tí a dárí ìrékọjá wọn jì, tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.

  12. Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà ẹni tí Olúwa kò ka ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sí i lọ́rùn àti nínú ẹ̀mí ẹni tí kò sí ẹ̀tàn.

  13. Nígbà tí mo dákẹ́, egungun mi di gbígbó dànù nípa ìkérora mi ní gbogbo ọjọ́.

  14. Nítorí pé ni ọ̀sán àti ní òru ọwọ́ rẹ̀ wúwo sí mi lára; agbára mi gbẹ tán gẹ́gẹ́ bí ooru ẹ̀ẹ̀rùn. Sela.

  15. Èmi jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọ àti pé èmi kò sì fi àìṣòdodo mi pamọ́. Èmi wí pé, “Èmi yóò jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Olúwa,” ìwọ sì dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí. Sela.

  16. Nítorí náà jẹ́ kí gbogbo àwọn olódodo máa gbà àdúrà sí ọ ní ìgbà tí a lè rí ọ; nítòótọ́ nígbà tí ìṣàn omi ńlá bá ru sókè, wọn kì yóò lè dé ọ̀dọ̀ rẹ̀.

  17. Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi; ìwọ yóò pa mí mọ́ kúrò nínú ìyọnu; ìwọ yóò fi orin ìgbàlà yí mi ka. Sela.

  18. Èmi yóò kọ́ ọ, èmi yóò sì fi ẹsẹ̀ rẹ lé ọ̀nà tí ìwọ yóò rìn èmi yóò máa gbà ọ́ ní ìyànjú, èmi yóò sì máa fi ojú mi tọ́ ọ.

  19. Má ṣe dàbí ẹṣin tàbí ìbáaka, tí kò ní òye ẹnu ẹni tí a gbọdọ̀ fi ìjánu bọ̀, kí wọn má ba à súnmọ́ ọ.

  20. Ọ̀pọ̀ ìkáàánú ní yóò wà fún ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa tí ó dúró ṣinṣin ni yóò yí àwọn tí ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa ká.

  21. Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, kí ẹ sì ní inú dídùn, ẹ̀yìn olódodo; ẹ sì máa kọrin, gbogbo ẹ̀yìn tí àyà yín dúró ṣinṣin.

  22. Orin fún ìgòkè. Láti inú ibú wá ni èmi ń ké pè é ọ́ Olúwa

  23. Olúwa, gbóhùn mi, jẹ́ kí etí rẹ kí o tẹ́ sílẹ̀ sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.

  24. Olúwa, ìbá ṣe pé kí ìwọ máa sàmì ẹ̀ṣẹ̀, Olúwa, tá ni ìbá dúró.

  25. Nítorí ìdáríjì wà lọ́dọ̀ rẹ, kí a lè máa bẹ̀rù rẹ.