Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Psalms: Didactic Psalms

225 ẹsẹ · 16 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Didactic Psalms

  1. Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà, tí kò rìn ní ìmọ̀ àwọn ènìyàn búburú, ti kò dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tàbí tí kò sì jókòó ní ibùjókòó àwọn ẹlẹ́gàn.

  2. Ṣùgbọ́n ayọ̀ inú rẹ̀ wà nínú òfin Olúwa àti nínú òfin rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti òru.

  3. Ó dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń sàn, tí ń so èso rẹ̀ jáde ní àkókò rẹ̀ tí ewé rẹ̀ kì yóò rẹ̀. Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé, ni yóò máa yọrí sí rere.

  4. Kò le rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn búburú! Wọn yóò dàbí ìyàngbò ọkà tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ dànù.

  5. Nítorí náà àwọn ènìyàn búburú kì yóò le è dìde dúró ní ìdájọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kì yóò le è dúró ní àwùjọ àwọn olódodo.

  6. Nítorí Olúwa ń ṣọ́ ọ̀nà àwọn olódodo, ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.

  7. Fún adarí orin. Fún ohun èlò orin fífọn. Saamu ti Dafidi. Fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, Olúwa, kíyèsi àròyé mi.

  8. Fi etí sílẹ̀ sí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́, ọba mi àti Ọlọ́run mi, nítorí ìwọ ni mo gba àdúrà sí.

  9. Ní òwúrọ̀, Olúwa, ìwọ yóò gbọ́ ohùn mi; ní òwúrọ̀, èmi yóò gbé ẹ̀bẹ̀ mi sí iwájú rẹ̀ èmi yóò sì dúró ní ìrètí.

  10. Nítorí ìwọ kì í ṣe Ọlọ́run tí ó ní inú dídùn sí búburú; bẹ́ẹ̀ ni ẹni ibi kò le è bá ọ gbé.

  11. Àwọn agbéraga kò le è dúró níwájú rẹ̀. Ìwọ kórìíra gbogbo àwọn aṣebi;

  12. ìwọ yóò pa àwọn tí ń ṣe èké run. Apani àti ẹni ẹ̀tàn ènìyàn ni Olúwa yóò kórìíra.

  13. Ṣùgbọ́n èmi, nípa títóbi àánú rẹ̀, èmi yóò wá sínú ilé rẹ̀; ní tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni èmi yóò tẹríba sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀.

  14. Tọ́ mi, Olúwa, nínú òdodo rẹ, nítorí àwọn ọ̀tá mi, mú ọ̀nà rẹ tọ́ níwájú mi.

  15. Kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ẹnu wọn tí a lè gbàgbọ́; ọkàn wọn kún fún ìparun. Ọ̀nà ọ̀fun wọn ni isà òkú tí ó ṣí sílẹ̀; pẹ̀lú ahọ́n wọn ni wọ́n ń sọ ẹ̀tàn.

  16. Dá wọn lẹ́bi Ọlọ́run! Jẹ́ kí rìkíṣí wọn jẹ́ ìṣubú wọn. Lé wọn jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nítorí wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ.

  17. Ṣùgbọ́n, jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó sádi ọ́ kí ó yọ̀; jẹ kí wọn máa kọrin fún ayọ̀ títí. Tan ààbò rẹ sórí wọn, àti àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ yóò máa yọ̀ nínú rẹ.

  18. Dájúdájú, Olúwa, ìwọ bùkún olódodo; ìwọ fi ojúrere rẹ yí wọn ká bí asà.

  19. Fún adarí orin. Ti Dafidi. Ìgbẹ́kẹ̀lé mi wà nínú Olúwa. Báwo ní ẹ̀yin ó ṣe sọ fún ọkàn mi pé, “Fò gẹ́gẹ́ bi ẹyẹ lọ si orí òkè rẹ.

  20. Wò ó nítorí náà, ènìyàn búburú fa ọfà rẹ̀; wọn ti fi ọfà wọn sí ojú okùn láti tafà níbi òjìji sí àyà ẹni ìdúró ṣinṣin.

  21. Nígbà tí ìpìlẹ̀ bá bàjẹ́ kí ni olódodo yóò ṣe?”

  22. Olúwa ń bẹ nínú tẹmpili mímọ́ rẹ̀; Olúwa ń bẹ lórí ìtẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run. Ó ń wo àwọn ọmọ ènìyàn; ojú rẹ̀ ń yẹ̀ wọ́n wò.

  23. Olúwa ń yẹ olódodo wò, ṣùgbọ́n ènìyàn búburú àti àwọn tí o fẹ́ ìwà ipá ni ọkàn rẹ̀ kórìíra.

  24. Sí orí àwọn ènìyàn búburú ni yóò rọ̀jò ẹ̀yín iná àti imí-ọjọ́ tí ń jó; àti ìjì gbígbóná ní yóò jẹ ìpín wọn.

  25. Nítorí, olódodo ní Olúwa, o fẹ́ràn òdodo; ẹni ìdúró ṣinṣin yóò sì rí i.