Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Psalms

896 ẹsẹ · 16 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.

  2. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu. Orin. Ó ti fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ sórí òkè mímọ́;

  3. Olúwa fẹ́ràn ẹnu-ọ̀nà Sioni ju gbogbo ibùgbé Jakọbu lọ.

  4. Ohun ológo ni a sọ nípa rẹ̀, ìlú Ọlọ́run,

  5. “Èmi ó dárúkọ Rahabu àti Babeli láàrín àwọn tí ó jẹ́wọ́ mi: Filistia pẹ̀lú, àti Tire, pẹ̀lú Kuṣi, yóò sọ pé, ‘Èyí ni a bí ní Sioni.’ ”

  6. Nítòótọ́, ti Sioni ni a ó sọ, “Eléyìí àti eléyìí ni a bí nínú rẹ̀, àti Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo ni yóò fìdí rẹ̀ múlẹ̀.”

  7. Olúwa yóò kọ nínú àkọsílẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀: “Eléyìí ni a bí ní Sioni.”

  8. Àti àwọn olórin àti àwọn tí ń lu ohun èlò orin yóò wí pé, “Gbogbo orísun mi ń bẹ nínú rẹ.”

  9. Saamu. Orin. Fún Ọjọ́ Ìsinmi. Ohun rere ni láti máa fi ọpẹ́ fún Olúwa àti láti máa kọrin sí orúkọ rẹ̀, Ọ̀gá-ògo,

  10. láti kéde ìfẹ́ rẹ̀ ní òwúrọ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ ní alẹ́,

  11. lára ohùn èlò orin olókùn mẹ́wàá àti lára ohun èlò orin haapu.

  12. Nítorí ìwọ ni ó mú inú mi dùn nípa iṣẹ́ rẹ Olúwa; èmi kọrin ayọ̀ sí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

  13. Báwo ni iṣẹ́ rẹ tí tóbi tó, Olúwa? Èrò inú rẹ ìjìnlẹ̀ ni!

  14. Òpè ènìyàn kò mọ̀ ọ́n, aṣiwèrè kò sì mọ̀ ọ́n,

  15. nígbà tí àwọn ènìyàn búburú bá rú jáde bí i koríko àti gbogbo àwọn olùṣe búburú gbèrú, wọn yóò run láéláé.

  16. Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa ni a ó gbéga títí láé.

  17. Nítorí nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ, Olúwa, nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ yóò ṣègbé; gbogbo àwọn olùṣe búburú ni a ó fọ́nká.

  18. Ìwọ ti gbé ìwo mi ga bí i ti màlúù igbó; òróró dídára ni a dà sí mi ní orí.

  19. Ojú mi ti rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi; ìparun sí àwọn ènìyàn búburú tí ó dìde sí mi.

  20. Olódodo yóò gbèrú bí i igi ọ̀pẹ, wọn yóò dàgbà bí i igi kedari Lebanoni,

  21. tí a gbìn sí ilé Olúwa, Wọn yóò rúwé nínú àgbàlá Ọlọ́run wa.

  22. Wọn yóò máa so èso ní ìgbà ogbó, wọn yóò dúró ní àkọ̀tun, wọn yóò sì tutù nini,

  23. láti fihàn pé, “Ẹni ìdúró ṣinṣin ni Olúwa; òun ni àpáta mi, kò sì ṣí aburú kankan nínú rẹ̀.”

  24. Olúwa ń jẹ ọba, ọláńlá ni ó wọ̀ ní aṣọ; ọláńlá ni Olúwa wọ̀ ní aṣọ àti ìhámọ́ra rẹ̀ pẹ̀lú agbára. Ó fi ìdí ayé múlẹ̀; kò sì le è yí.

  25. Ìjọba rẹ̀ wà láti ọjọ́ pípẹ́; ìwọ wà títí ayérayé.