Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Psalms

896 ẹsẹ · 16 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wa sí wa lọ́rùn jẹ́ kí àánú rẹ wá kánkán láti bá wa, nítorí tí a rẹ̀ wá sílẹ̀ gidigidi.

  2. Ràn wá lọ́wọ́, Ọlọ́run Olùgbàlà wa, fún ògo orúkọ rẹ; gbà wá kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì nítorí orúkọ rẹ.

  3. Àwọn orílẹ̀-èdè yóò máa wí pé, “Níbo ni Ọlọ́run wọn wà?” Ní ojú wa, kí a mọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè kí ó sì gbẹ̀san àwọn ẹ̀jẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ tí a tú jáde.

  4. Jẹ́ kí ìmí ẹ̀dùn oǹdè náà wá síwájú rẹ, gẹ́gẹ́ bí títóbi agbára rẹ ìwọ ṣe ìtọ́jú àwọn ti a dá lẹ́bi ikú.

  5. San án padà sí àyà àwọn aládùúgbò wa nígbà méje nípa ẹ̀gàn tí wọn ti gàn ọ́ Olúwa.

  6. Nígbà náà àwa ènìyàn rẹ, àti àgùntàn pápá rẹ, yóò fi ọpẹ́ fún ọ títí láé; láti ìran dé ìran ni àwa ó fi ìyìn rẹ hàn.

  7. Saamu ti Asafu. Ọlọ́run ń ṣàkóso nínú ìpéjọpọ̀ ńlá, ó ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn “ọlọ́run òrìṣà”.

  8. “Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa gbèjà àwọn aláìṣòdodo kí ó sì ṣe ojú ìṣáájú sí àwọn ènìyàn búburú?

  9. Gbèjà àwọn aláìlágbára àti aláìní baba; ṣe ìtọ́jú ẹ̀tọ́ àwọn aláìní àti ẹni ìnilára.

  10. Gba àwọn aláìlágbára àti aláìní; gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú.

  11. “Wọn kò mọ̀ ohun kankan, wọn kò lóye ohun kankan. Wọn ń rìn kiri nínú òkùnkùn; à si mí gbogbo ìpìlẹ̀ ayé.

  12. “Mo wí pé, ‘Ẹyin ní “Ọlọ́run òrìṣà”; ẹ̀yin ní gbogbo ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ.’

  13. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ó kú bí ènìyàn lásán; ẹ̀yin ó ṣubú bí ọ̀kan nínú ọmọ-aládé.”

  14. Dìde, Ọlọ́run, ṣe ìdájọ́ ayé, nítorí gbogbo orílẹ̀-èdè ni ìní rẹ.

  15. Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu. Ibùgbé rẹ̀ ti lẹ́wà tó, Olúwa àwọn ọmọ-ogun!

  16. Ọkàn mi ń ṣàfẹ́rí nítòótọ́ ó tilẹ̀ pòǹgbẹ fún àgbàlá Olúwa àyà mi àti ara mi ń kọrin ayọ̀ sí Ọlọ́run alààyè.

  17. Nítòótọ́ ológoṣẹ́ ri ilé, ẹyẹ alápáǹdẹ̀dẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ fún ara rẹ̀, níbi tí yóò máa pa ọmọ rẹ̀ mọ́ sí: ibùgbé ní tòsí pẹpẹ rẹ̀, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ọba mí àti Ọlọ́run mi.

  18. Ìbùkún ní fún àwọn tí ó ń gbé inú ilé rẹ; wọn ó máa yìn ọ́ títí láé.

  19. Ìbùkún ni fún àwọn tí agbára wọn wà nínú rẹ àwọn tí wọ́n gbé ọkàn lé bíbẹ ibi mímọ́ wò.

  20. Àwọn tí ń la àfonífojì omijé lọ wọn sọ ọ́ di kànga àkọ́rọ̀ òjò sì fi ìbùkún bò ó.

  21. Wọ́n ń lọ láti ipa dé ipá títí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan fi farahàn níwájú Ọlọ́run ní Sioni.

  22. Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa Ọlọ́run Alágbára; tẹ́tí sí mi, Ọlọ́run Jakọbu.

  23. Wo asà wa, Ọlọ́run; fi ojú àánú wò àwọn ẹni àmì òróró rẹ.

  24. Dídára ní ọjọ́ kan ní ààfin rẹ ju ẹgbẹ̀rún (1,000) ọjọ́ lọ; èmi o kúkú máa ṣe aṣọ́nà nínú ilé Ọlọ́run mi jù láti gbé ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú.

  25. Nítorí Olúwa Ọlọ́run jẹ́ òòrùn àti asà; Olúwa fún ni ní ojúrere àti ọlá; kò sí ohun rere kan tí yóò fàsẹ́yìn fún àwọn tí ó rìn ní àìlábùkù.