- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Psalms
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Ìwọ dá wa lóhùn pẹ̀lú ohun ìyanu ti òdodo, Ọlọ́run olùgbàlà wa, ẹni tí ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé gbogbo òpin ayé àti àwọn tí ó jìnnà nínú òkun,
ìwọ tí ó dá òkè nípa agbára rẹ, tí odi ara rẹ ní àmùrè agbára,
ẹni tí ó mú rírú omi òkun dákẹ́, ríru ariwo omi wọn, àti ìdágìrì àwọn ènìyàn.
Àwọn tí ó ń gbé òkèrè bẹ̀rù, nítorí àmì rẹ wọ̀n-ọn-nì; ìwọ mú ìjáde òwúrọ̀ àti ti àṣálẹ́ yọ̀, ìwọ pè fún orin ayọ̀.
Ìwọ bẹ ayé wò, o sì bomirin; ìwọ mú un ọ̀rọ̀ púpọ̀. Odò Ọlọ́run kún fún omi láti pèsè ọkà fún àwọn ènìyàn, nítorí ibẹ̀ ni ìwọ ti yàn án.
Ìwọ fi bomirin sí aporo rẹ̀ ìwọ tẹ́ ògúlùtu rẹ̀; ìwọ fi òjò mú ilẹ̀ rẹ̀ rọ̀, o sì bùkún ọ̀gbìn rẹ̀.
Ìwọ fi oore rẹ dé ọdún ní adé, ọ̀rá ń kán ní ipa ọ̀nà rẹ.
Pápá tútù ní aginjù ń kan àwọn òkè kéékèèké fi ayọ̀ di ara wọn ní àmùrè.
Agbo ẹran ni a fi wọ pápá tútù náà ní aṣọ; àfonífojì ni a fi ọkà bò mọ́lẹ̀, wọ́n hó fún ayọ̀, wọ́n ń kọrin pẹ̀lú.
Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu. Orin. Kí Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún wa kí ó sì bùkún fún wa, kí ó sì jẹ́ kí ojú rẹ̀ tàn yí wa ká,
kí ọ̀nà rẹ le di mí mọ̀ ní ayé, ìgbàlà rẹ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.
Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run; kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́!
Kí orílẹ̀-èdè kí ó yọ̀, kí ó sì kọrin fún ayọ̀, nítorí ìwọ fi òdodo darí àwọn ènìyàn, ìwọ sì jẹ ọba àwọn orílẹ̀-èdè ní ayé.
Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run; kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́. Sela.
Nígbà náà ní ilẹ̀ yóò mú ìkórè rẹ̀ wá, Ọlọ́run, Ọlọ́run wa, yóò bùkún fún wa.
Ọlọ́run yóò bùkún fún wa, àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò sì máa bẹ̀rù rẹ̀.
Fún adarí orin. Ti Dafidi. Ẹ̀bẹ̀. Yára, Ọlọ́run, láti gbà mí là, Olúwa, wá kánkán láti ràn mí lọ́wọ́.
Kí àwọn tí ń wá ọkàn mi kí a dójútì wọ́n, kí wọn sì dààmú; kí àwọn tó ń wá ìparun mi yí ẹ̀yìn padà nínú ìtìjú.
Kí a pa wọ́n ní ẹ̀yìn dà fún èrè ìtìjú àwọn tí ń wí pé, “Háà! Háà!”
Ṣùgbọ́n kí àwọn tí ó ń wá ọ ó máa yọ̀ kí inú wọn kí ó sì máa dùn nípa rẹ, kí àwọn tí ó ń fẹ́ ìgbàlà rẹ máa wí pé, “Jẹ́ kí a gbé Ọlọ́run ga!”
Ṣùgbọ́n mo jẹ́ òtòṣì àti aláìní; wa kánkán sí ọ̀dọ̀ mi, Ọlọ́run. Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àti olùdáǹdè mi; Olúwa, má ṣe dúró pẹ́.
Fún adarí orin. Tí ohùn, “Má ṣe parun.” Saamu ti Asafu. Orin. A fi ìyìn fún ọ, Ọlọ́run, a yìn ọ́, nítorí orúkọ rẹ súnmọ́ tòsí; àwọn ènìyàn ń sọ ti ìyanu rẹ.
Ìwọ wí pé, “Mo yan àkókò ìyàsọ́tọ̀; Èmi ni ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ òdodo.
Nígbà tí ayé àti àwọn ènìyàn ibẹ̀ wárìrì, Èmi ni mo di òpó rẹ̀ mú ṣinṣin.
Èmí wí fún àwọn agbéraga pé, ẹ má ṣe gbéraga mọ́; àti sí ènìyàn búburú; ẹ má ṣe gbé ìwo yín sókè.