Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Psalms

896 ẹsẹ · 16 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Moabu ní ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi, lórí Edomu ní mo bọ́ bàtà mi sí; lórí Filistia ni mo kígbe ayọ̀.”

  2. Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi nì? Ta ni yóò tọ́ mí lọ sí Edomu?

  3. Kì í ha ń ṣe ìwọ, Ọlọ́run, tí ó ti kọ̀ wá sílẹ̀ tí o kò sì bá ogun wa jáde mọ́?

  4. Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ lórí àwọn ọ̀tá, nítorí asán ni ìrànlọ́wọ́ ènìyàn.

  5. Nípa Ọlọ́run ni a óò ní ìṣẹ́gun, yóò sì tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.

  6. Fún adarí orin. Ohun èlò orin olókùn. Ti Dafidi. Gbọ́ ẹkún mi, Ọlọ́run; tẹ́tí sí àdúrà mi.

  7. Láti òpin ayé wá ni èmi yóò pè ọ́, mo pè nígbà àyà mi ń ṣàárẹ̀; mú mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ.

  8. Nítorí ìwọ ti jẹ́ ibi ààbò mi, ilé ìṣọ́ agbára àwọn ọ̀tá.

  9. Mo ń lépa láti máa gbé nínú àgọ́ rẹ títí láé kí n sì rí ààbò níbi ìyẹ́ apá rẹ.

  10. Nítorí ìwọ ti gbọ́ àwọn ẹ̀jẹ́ mi, Ọlọ́run; Ìwọ ti fún mi ní ogún àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ.

  11. Jẹ́ kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn, ọdún rẹ̀ fún ìrandíran.

  12. Kí ó máa jẹ ọba níwájú Ọlọ́run títí láé; pèsè àánú àti òtítọ́ rẹ tí yóò máa ṣe ìtọ́jú rẹ.

  13. Nígbà náà ni èmi ó máa kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ títí láé kí n san ẹ̀jẹ́ mi ní ojoojúmọ́.

  14. Fún adarí orin. Fun Jedutuni. Saamu Dafidi. Nínú Ọlọ́run nìkan ni ọkàn mi ti rí ìsinmi; ìgbàlà mi ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá.

  15. Òun nìkan ní àpáta mi àti ìgbàlà mi; Òun ni ààbò mi, a kì yóò sí mi ní ipò padà.

  16. Ẹ̀yin ó ti máa kọ́lú ènìyàn kan pẹ́ tó? Gbogbo yín ni ó fẹ́ pa á, bí ògiri tí ó fẹ́ yẹ̀, àti bí ọgbà tí ń wó lọ?

  17. Kìkì èrò wọn ni láti bì ṣubú kúrò nínú ọlá rẹ̀; inú wọn dùn sí irọ́. Wọ́n ń fi ẹnu wọn súre, ṣùgbọ́n wọ́n ń gégùn ún nínú ọkàn wọn. Sela.

  18. Nínú Ọlọ́run nìkan ni ìsinmi wà, ìwọ Ọlọ́run mi. Ìrètí mi wá láti ọ̀dọ̀ rẹ.

  19. Òun nìkan ní àpáta àti ìgbàlà mi; Òun ni ààbò mi, a kì yóò ṣí mi ní ipò.

  20. Ìgbàlà mi àti ògo mi dúró nínú Ọlọ́run; Òun ní àpáta ńlá mi, àti ààbò mi.

  21. Gbẹ́kẹ̀lé ní gbogbo ìgbà, ẹ̀yin ènìyàn; tú ọkàn rẹ jáde sí i, nítorí Ọlọ́run ni ààbò wa.

  22. Nítòótọ́, asán ni àwọn ọmọ ènìyàn, èké sì ni àwọn olóyè, wọ́n gòkè nínú ìwọ̀n, lápapọ̀ wọ́n jẹ́ èémí.

  23. Má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ìnilára, tàbí gbéraga nínú olè jíjà, nítòótọ́ bí ọrọ̀ rẹ̀ ń pọ̀ sí i, má ṣe gbẹ́kẹ̀ rẹ lé wọn.

  24. Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kejì, ni mo gbọ́ èyí pé, “Ti Ọlọ́run ni agbára,

  25. pẹ̀lúpẹ̀lú, Olúwa, tìrẹ ni àánú; nítorí tí ìwọ san án fún olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.”