- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Paul
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
“Ará, èéṣe ti ẹ̀yin fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? Ènìyàn bí ẹ̀yin náà ni àwa ń ṣe pẹ̀lú, ti a sì ń wàásù ìyìnrere fún yín, kí ẹ̀yin ba à lè yípadà kúrò nínú ohun asán wọ̀nyí sí Ọlọ́run alààyè, tí ó dá ọ̀run àti ayé, òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn.
Ní ìran tí ó ti kọjá, ó faradà á fún gbogbo orílẹ̀-èdè, láti máa rìn ni ọ̀nà tiwọn.
Ṣùgbọ́n kò fi ara rẹ̀ sílẹ̀ ní àìní ẹ̀rí, ní ti pé ó ṣe rere, ó ń fún yín lójò láti ọ̀run wá, àti ni àkókò èso, ó ń fi oúnjẹ àti ayọ̀ kún ọkàn yín.”
Díẹ̀ ni ó kù kí wọn má le fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dá àwọn ènìyàn dúró, kí wọn má ṣe rú ẹbọ bọ wọ́n.
Àwọn Júù kan sì ti Antioku àti Ikoniomu wá, nígbà tí wọ́n yí àwọn ènìyàn lọ́kàn padà, wọ́n sì sọ Paulu ní òkúta, wọ́n wọ́ ọ kúrò sí ẹ̀yin odi ìlú náà, wọn ṣe bí ó ti kú.
Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn dúró ti i yíká, ó dìde ó sì padà wọ inú ìlú náà lọ. Ní ọjọ́ kejì ó bá Barnaba lọ sí Dabe.
Nígbà tí wọ́n sì ti wàásù ìyìnrere fún ìlú náà, tí wọ́n sì ni ọmọ-ẹ̀yìn púpọ̀, wọn padà lọ sí Lysra, àti Ikoniomu, àti Antioku,
wọn sì ń mú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn lọ́kàn le, wọ́n sì ń gbà wọ́n níyànjú láti dúró nínú ìgbàgbọ́, àti pé nínú ìpọ́njú púpọ̀, ni àwa ó fi wọ ìjọba Ọlọ́run.
Nígbà tí wọ́n sì ti yan àwọn alàgbà fún olúkúlùkù ìjọ, tí wọn sì ti fi àwẹ̀ gbàdúrà, wọn fi wọ́n lé Olúwa lọ́wọ, ẹni tí wọn gbàgbọ́.
Nígbà tí wọn sí la Pisidia já, wọ́n wá sí Pamfilia.
Nígbà tí wọn sì ti sọ ọ̀rọ̀ náà ni Perga, wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí Atalia.
Àti láti ibẹ̀ lọ wọ́n ṣíkọ̀ lọ sí Antioku ní ibi tí a gbé ti fi wọ́n lé oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run lọ́wọ́, fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣe parí.
Nígbà tí wọ́n sì dé, tí wọ́n sì pé ìjọ jọ, wọ́n ròhìn gbogbo ohun tí Ọlọ́run fi wọ́n ṣe, àti bí ó ti ṣí ìlẹ̀kùn ìgbàgbọ́ fún àwọn aláìkọlà.
Níbẹ̀ ni wọ́n ń gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ni ọjọ́ púpọ̀.
Àwọn ọkùnrin kan tí Judea sọ̀kalẹ̀ wá, wọ́n sì kọ́ àwọn arákùnrin pé, “Bí kò ṣe pé a bá kọ yín ni ilà bí ìṣe Mose, ẹ̀yin kí yóò lè là.”
Nígbà tí Paulu àti Barnaba ni ìyapa àti ìyàn jíjà tí kò mọ níwọ̀n pẹ̀lú ara wọn, wọ́n yan Paulu àti Barnaba àti àwọn mìíràn nínú aposteli kí wọn gòkè lọ sí Jerusalẹmu, sọ́dọ̀ àwọn alàgbà nítorí ọ̀ràn yìí.
Nígbà tí wọn sì dé Jerusalẹmu, ìjọ àti àwọn aposteli àti àwọn alàgbà tẹ́wọ́gbà wọ́n, wọ́n sì ròyìn ohun gbogbo tí Ọlọ́run ti ṣe nípasẹ̀ wọn.
Gbogbo àjọ sí dákẹ́, wọ́n sì fi etí sí Barnaba àti Paulu, tí wọn ń ròyìn iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ àmì tí Ọlọ́run tí ti ọwọ́ wọn ṣe láàrín àwọn aláìkọlà.
Nígbà nà án ni ó tọ́ lójú àwọn aposteli, àti àwọn alàgbà pẹ̀lú gbogbo ìjọ, láti yan ènìyàn nínú wọn, àti láti rán wọ́n lọ sí Antioku pẹ̀lú Paulu àti Barnaba: Judasi ti a ń pè àpèlé rẹ̀ ní Barsaba, àti Sila, ẹni tí ó lórúkọ nínú àwọn arákùnrin.
Ó yẹ lójú àwa, bí wa ti fi ìmọ̀ ṣọ̀kan láti yan ènìyàn láti rán wọn sí yín, pẹ̀lú Barnaba àti Paulu àwọn olùfẹ́ wa.
Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, Paulu sì sọ fún Barnaba pé, “Jẹ́ kí a tún padà lọ bẹ àwọn arákùnrin wa wò, bí wọn ti ń ṣe sí ni ìlú gbogbo tí àwa ti wàásù ọ̀rọ̀ Olúwa.”
Barnaba sì pinnu rẹ̀ láti mú Johanu lọ pẹ̀lú wọn, ẹni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Marku.
Ṣùgbọ́n Paulu rò pé, kò yẹ láti mú un lọ pẹ̀lú wọn, ẹni tí ó fi wọn sílẹ̀ ni Pamfilia, tí kò sì bá wọn lọ sí iṣẹ́ náà.
Ìjà náà sì pọ̀ tó bẹ́ẹ̀, tí wọn ya ara wọn sì méjì, Barnaba sì mu Marku ó tẹ ọkọ́ létí lọ sí Saipurọsi.
Ṣùgbọ́n Paulu yan Sila, ó sì lọ, bí a ti fi lé oore-ọ̀fẹ́ Olúwa lọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin.