Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Paul: Persecutes the Christians; present at, and gives consent to, the stoning of Stephen
Àwọn ẹsẹ nípa Persecutes the Christians; present at, and gives consent to, the stoning of Stephen
wọ́n sì wọ́ ọ sẹ́yìn òde ìlú, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sísọ ọ́ ní òkúta; àwọn ẹlẹ́rìí sì fi aṣọ wọn lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ ọmọkùnrin kan tí a ń pè ní Saulu.
Saulu sì wà níbẹ̀, ó sì fi àṣẹ sí ikú rẹ̀. Ní àkókò náà, inúnibíni ńlá kan dìde sí ìjọ tí ó wà ni Jerusalẹmu, gbogbo wọn sì túká káàkiri agbègbè Judea àti Samaria, àyàfi àwọn aposteli.
Ṣùgbọ́n Saulu bẹ̀rẹ̀ sí da ìjọ ènìyàn Ọlọ́run rú. Ó ń wọ ilé dé ilé, ó sì ń mú àwọn ọkùnrin àti obìnrin, ó sì ń fi wọn sínú túbú.
Ṣùgbọ́n síbẹ̀, Saulu sí ń tẹ̀síwájú nínú mímí èémí ìhalẹ̀ mọ́ni àti ìpani sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Olúwa. Ó tọ olórí àlùfáà lọ,
Mo sì ṣe inúnibíni sí àwọn ènìyàn tí ń tọ ọ̀nà yìí dé ojú ikú wọn, mo dè tọkùnrin tobìnrin wọ́n, mo sì fi wọ́n sínú túbú,