Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Paul: Visits Amphipolis, and Apollonia, and Thessalonica, preaches in the synagogue

4 ẹsẹ · 103 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Visits Amphipolis, and Apollonia, and Thessalonica, preaches in the synagogue

  1. Nígbà tí wọn sì ti kọjá Amfipoli àti Apollonia, wọ́n wá sí Tẹsalonika, níbi tí Sinagọgu àwọn Júù wà.

  2. Àti Paulu, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, ó wọlé tọ̀ wọ́n lọ, ni ọjọ́ ìsinmi mẹ́ta ó sì ń bá wọn fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ nínú ìwé mímọ́.

  3. Ó ń túmọ̀, ó sì ń fihàn pé, Kristi kò lè ṣàìmá jìyà, kí o sì jíǹde kúrò nínú òkú; àti pé, “Jesu yìí ẹni tí èmi ń wàásù fún yin, òun ni Kristi náà.”

  4. A sì yí nínú wọn lọ́kàn padà, wọ́n sì darapọ̀ mọ́ Paulu àti Sila, bákan náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn olùfọkànsìn Helleni àti nínú àwọn obìnrin ọlọ́lá, kì í ṣe díẹ̀.