Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Paul: Visits Coos, Rhodes, Patara; takes ship for Tyre; tarries at Tyre seven days; is brought on his way by the disciples to the outskirts of the city; kneels down and prays; takes ship; comes to Ptolemais; salutes the brethren, and abides one day

7 ẹsẹ · 103 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Visits Coos, Rhodes, Patara; takes ship for Tyre; tarries at Tyre seven days; is brought on his way by the disciples to the outskirts of the city; kneels down and prays; takes ship; comes to Ptolemais; salutes the brethren, and abides one day

  1. Lẹ́yìn tí àwa ti kúrò lọ́dọ̀ wọn, tí a sì ṣíkọ̀, àwa bá ọ̀nà wa lọ tààrà sí Kosi. Ní ọjọ́ kejì a sì lọ sí Rodu, à si gba ibẹ̀ lọ sí Patara,

  2. A rí ọkọ̀ ojú omi kan tí ń rékọjá lọ sí Fonisia, a wọ inú ọkọ̀ náà, a sì ṣíkọ̀.

  3. Nígbà tí àwa sì ń wo Saipurọsi lókèèrè, a sì fi í sí ọwọ́ òsì, a fi orí ọ́kọ̀ le Siria, a sì gúnlẹ̀ ni Tire; nítorí níbẹ̀ ni ọkọ̀ yóò tí já ẹrù sílẹ̀.

  4. Nígbà tí a sì ti rí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn níbẹ̀, a dúró ní ọ̀dọ̀ wọn níbẹ̀ fún ọjọ́ méje: àwọn ẹni tí ó ti ipá Ẹ̀mí wí fún Paulu pé, kí ó má ṣe lọ sí Jerusalẹmu.

  5. Nígbà tí a sì tí lo ọjọ́ wọ̀nyí tan, àwa jáde, a sì mu ọ̀nà wá pọ̀n; gbogbo wọn sì sìn wá, pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé títí àwa fi jáde sí ẹ̀yìn ìlú, nígbà tí àwa sì gúnlẹ̀ ní èbúté, a sì gbàdúrà.

  6. Nígbà tí a sì ti dágbére fún ara wa, a bọ́ sí ọkọ̀; bẹ́ẹ̀ ni àwọn sì padà lọ sí ilé wọn.

  7. Nígbà tí a sì ti parí àjò wa láti Tire, àwa dé Pitolemai; nígbà ti a sì kí àwọn ará, a sì bá wọn gbé ní ọjọ́ kan.