Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Paul: Supports himself
Àwọn ẹsẹ nípa Supports himself
Nítorí tí òun náà jẹ́ oníṣẹ̀-ọwọ́ kan náà, ó bá wọn jókòó, ó sì ń ṣiṣẹ́: nítorí àgọ́ pípa ni iṣẹ́ ọwọ́ wọn.
Èmí kò ṣe ojúkòkòrò fàdákà, tàbí wúrà, tàbí aṣọ ẹnikẹ́ni.
Ẹ̀yin tìkára yín sá à mọ̀ pé, ọwọ́ mi wọ̀nyí ni mo fi ṣiṣẹ́ láti fi pèsè fún àìní mi, àti tí àwọn tí ó wà pẹ̀lú mi.
Nínú ohun gbogbo mo fi àpẹẹrẹ fún un yín pé, nípa ṣíṣe iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ẹ máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́, ki ẹ sì máa rántí ọ̀rọ̀ Jesu Olúwa, bí òun tìkára rẹ̀ tí wí pé, ‘Láti fún ni ní ìbùkún ju láti gbà lọ.’ ”