Fò sí àkóónú

circa 1010–970 BC

The Reign of David

David unites the tribes, conquers Jerusalem, and establishes Israel's golden age—even through deep personal failure.

1,230 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. 2 Samuẹli 23:20nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi

    Benaiah, ọmọ Jehoiada, ọmọ akọni ọkùnrin kan tí Kabṣeeli, ẹni tí ó pọ̀ ní iṣẹ́ agbára, òun pa àwọn ọmọ Arieli méjì ti Moabu; ó sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ó sì pa kìnnìún kan nínú ihò lákoko òjò-dídì.

  2. 2 Samuẹli 23:21nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi

    Ó sì pa ará Ejibiti kan, ọkùnrin tí ó dára láti wò, ará Ejibiti náà sì ní ọ̀kọ̀ kan ní ọwọ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n Benaiah sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ, pẹ̀lú ọ̀pá ní ọwọ́, ó sì gba ọ̀kọ̀ náà lọ́wọ́ ará Ejibiti náà, ó sì fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ pa á.

  3. 2 Samuẹli 23:22nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi

    Nǹkan wọ̀nyí ní Benaiah ọmọ Jehoiada ṣe, ó sì ní orúkọ nínú àwọn ọkùnrin alágbára mẹ́ta náà.

  4. 2 Samuẹli 23:23nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi

    Nínú àwọn ọgbọ̀n náà, òun ní ọlá jùlọ, ṣùgbọ́n òun kò tó àwọn mẹ́ta ti ìṣáájú. Dafidi sì fi í ṣe ìgbìmọ̀ rẹ̀.

  5. 2 Samuẹli 23:24nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi

    Ọ̀kan nínú àwọn ọgbọ̀n náà: Asaheli arákùnrin Joabu sì Jásí Elhanani ọmọ Dodo ti Bẹtilẹhẹmu;

  6. 2 Samuẹli 23:25nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi

    Ṣamma ará Haroditi, Elika ará Harodi.

  7. 2 Samuẹli 23:26nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi

    Helesi ará Palti, Ira ọmọ Ikẹsi ará Tekoa;

  8. 2 Samuẹli 23:27nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi

    Abieseri ará Anatoti, Sibekai ará Huṣati;

  9. 2 Samuẹli 23:28nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi

    Salmoni ará Ahohi, Maharai ará Netofa;

  10. 2 Samuẹli 23:29nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi

    Heledi ọmọ Baanah, ará Netofa, Ittai ọmọ Ribai to Gibeah ti àwọn ọmọ Benjamini;

  11. 2 Samuẹli 23:30nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi

    Benaiah ará Piratoni, Hiddai ti àfonífojì Gaaṣi,

  12. 2 Samuẹli 23:31nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi

    Abi-Alboni ará Arbati, Asmafeti Barhumiti;

  13. 2 Samuẹli 23:32nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi

    Eliaba ará Ṣaalboni, àwọn ọmọ Jaṣeni, Jonatani;

  14. 2 Samuẹli 23:33nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi

    ọmọ Ṣamma ará Harari, Ahiamu ọmọ Ṣarari ará Harari;

  15. 2 Samuẹli 23:34nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi

    Elifeleti ọmọ Ahasbai, ọmọ ará Maakati, Eliamu ọmọ Ahitofeli ará Giloni;

  16. 2 Samuẹli 23:35nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi

    Hesro ará Karmeli, Paarai ará Arba;

  17. 2 Samuẹli 23:36nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi

    Igali ọmọ Natani ti Soba, Bani ará Gadi;

  18. 2 Samuẹli 23:37nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi

    Seleki ará Ammoni, Naharai ará Beeroti, ẹni tí ń ru ìhámọ́ra Joabu ọmọ Seruiah;

  19. 2 Samuẹli 23:38nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi

    Ira ará Itri, Garebu ará Itri.

  20. 2 Samuẹli 23:39nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi

    Uriah ará Hiti. Gbogbo wọn jẹ́ mẹ́tàdínlógójì.

  21. 2 Samuẹli 24:1nǹkan bí 1017 ṣáájú Kristi

    Ìbínú Olúwa sì ru sí Israẹli, ó sì ti Dafidi sí wọn, pé, “Lọ ka iye Israẹli àti Juda!”

  22. 2 Samuẹli 24:2nǹkan bí 1017 ṣáájú Kristi

    Ọba sì wí fún Joabu olórí ogun, tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Lọ ní ìsinsin yìí sí gbogbo ẹ̀yà Israẹli láti Dani títí dé Beerṣeba, kí ẹ sì ka iye àwọn ènìyàn, kí èmi lè mọ iye àwọn ènìyàn náà!”

  23. 2 Samuẹli 24:3nǹkan bí 1017 ṣáájú Kristi

    Joabu sì wí fún ọba pé, “Kí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi kún iye àwọn ènìyàn náà, iyekíye tí ó wù kí wọn jẹ́, ní ọ̀rọ̀ọ̀rún, ojú olúwa mi ọba yóò sì rí i, ṣùgbọ́n èétiṣe tí olúwa mi ọba fi fẹ́ nǹkan yìí?”

  24. 2 Samuẹli 24:4nǹkan bí 1017 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ọba borí ti Joabu, àti ti àwọn olórí ogun. Joabu àti àwọn olórí ogun sì jáde lọ kúrò níwájú ọba, láti lọ ka àwọn ènìyàn Israẹli.

  25. 2 Samuẹli 24:5nǹkan bí 1017 ṣáájú Kristi

    Wọ́n sì kọjá odò Jordani, wọ́n sì pàgọ́ ní Aroeri, ní ìhà apá ọ̀tún ìlú tí ó wà láàrín àfonífojì Gadi, àti sí ìhà Jaseri.