- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1010–970 BC
The Reign of David
David unites the tribes, conquers Jerusalem, and establishes Israel's golden age—even through deep personal failure.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- 2 Samuẹli 22:21nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi
“Olúwa sán án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi; ó sì san án fún mi gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi.
- 2 Samuẹli 22:22nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi
Nítorí pé èmi pa ọ̀nà Olúwa mọ́, èmi kò sì fi ìwà búburú yapa kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi.
- 2 Samuẹli 22:23nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi
Nítorí pé gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ ni ó wà níwájú mi; àti ní ti òfin rẹ̀, èmi kò sì yapa kúrò nínú wọn.
- 2 Samuẹli 22:24nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi
Èmi sì wà nínú ìwà títọ́ sí í, èmi sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi.
- 2 Samuẹli 22:25nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi
Olúwa sì san fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi, gẹ́gẹ́ bí ìwà mímọ́ mi níwájú rẹ̀.
- 2 Samuẹli 22:26nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi
“Fún aláàánú ni ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ni aláàánú, àti fún ẹni ìdúró ṣinṣin ní òdodo ni ìwọ ó fi ara rẹ hàn ní ìdúró ṣinṣin ní òdodo.
- 2 Samuẹli 22:27nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi
Fún onínú funfun ni ìwọ fi ara rẹ hàn ní funfun; àti fún ẹni wíwọ́ ni ìwọ ó fi ara rẹ hàn ní wíwọ́.
- 2 Samuẹli 22:28nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi
Àwọn ènìyàn tí ó wà nínú ìyà ni ìwọ ó sì gbàlà; ṣùgbọ́n ojú rẹ wà lára àwọn agbéraga, láti rẹ̀ wọ́n sílẹ̀.
- 2 Samuẹli 22:29nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi
Nítorí ìwọ ni ìmọ́lẹ̀ mi, Olúwa; Olúwa yóò sì sọ òkùnkùn mi di ìmọ́lẹ̀.
- 2 Samuẹli 22:30nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi
Bẹ́ẹ̀ ni nítorí nípa rẹ̀ ni èmi ti la àárín ogun kọjá; nípa Ọlọ́run mi èmi ti fo odi kan.
- 2 Samuẹli 22:31nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi
“Ọlọ́run yìí, pípé ni ọ̀nà rẹ̀; ọ̀rọ̀ Olúwa ni a ti dánwò. Òun sì ni asà fún gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e.
- 2 Samuẹli 22:32nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi
Nítorí ta ni Ọlọ́run, bí kò ṣe Olúwa? Ta ni àpáta, bí kò ṣe Ọlọ́run wa.
- 2 Samuẹli 22:33nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi
Ọlọ́run alágbára ni ó fún mi ní agbára, ó sì sọ ọ̀nà mi di títọ́.
- 2 Samuẹli 22:34nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi
Ó ṣe ẹsẹ̀ mi bí ẹsẹ̀ abo àgbọ̀nrín; ó sì mú mi dúró ní ibi gíga mi.
- 2 Samuẹli 22:35nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi
Ó kọ́ ọwọ́ mi ní ogun jíjà; tó bẹ́ẹ̀ tí apá mi fa ọrun idẹ.
- 2 Samuẹli 22:36nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi
Ìwọ sì ti fún mi ní asà ìgbàlà rẹ̀; ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ sì ti sọ mí di ńlá.
- 2 Samuẹli 22:37nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi
Ìwọ sì sọ ìtẹ̀lẹ̀ di ńlá ní abẹ́ mi; tó bẹ́ẹ̀ tí ẹsẹ̀ mi kò fi yọ̀.
- 2 Samuẹli 22:38nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi
“Èmi ti lépa àwọn ọ̀tá mi, èmi sì ti run wọ́n, èmi kò pẹ̀yìndà títí èmi fi run wọ́n.
- 2 Samuẹli 22:39nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi
Èmi ti pa wọ́n run, èmi sì ti fọ́ wọn, wọn kò sì le dìde mọ́, wọ́n ṣubú lábẹ́ mi.
- 2 Samuẹli 22:40nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi
Ìwọ sì ti fi agbára dì mí ní àmùrè fún ìjà; àwọn tí ó ti dìde sí mi ni ìwọ sì ti tẹ̀ lórí ba fún mi.
- 2 Samuẹli 22:41nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi
Ìwọ sì mú àwọn ọ̀tá mi pẹ̀yìndà fún mi, èmi ó sì pa àwọn tí ó kórìíra mi run.
- 2 Samuẹli 22:42nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi
Wọ́n wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan láti gbà wọ́n; wọ́n wo Olúwa, ṣùgbọ́n kò dá àwọn lóhùn.
- 2 Samuẹli 22:43nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni èmi sì gún wọn wẹ́wẹ́ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, èmi sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ ìta, èmi sì tẹ́ wọn gbọrọ.
- 2 Samuẹli 22:44nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi
“Ìwọ sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìjà àwọn ènìyàn mi, ìwọ pa mi mọ́ ki èmi lè ṣe olórí àwọn àjèjì orílẹ̀-èdè. Àwọn ènìyàn tí èmi kò tí mọ̀ yóò máa sìn mí.
- 2 Samuẹli 22:45nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi
Àwọn àjèjì wá láti tẹríba fún mi; bí wọ́n bá ti gbúròó mi, wọ́n á sì gbọ́ tèmi.