Fò sí àkóónú

circa 1010–970 BC

The Reign of David

David unites the tribes, conquers Jerusalem, and establishes Israel's golden age—even through deep personal failure.

1,230 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. 2 Samuẹli 20:19nǹkan bí 1022 ṣáájú Kristi

    Èmi ni ọ̀kan nínú àwọn ẹni àlàáfíà àti olóòtítọ́ ní Israẹli, ìwọ ń wá ọ̀nà láti pa ìlú kan run tí ó jẹ́ ìyá ní Israẹli, èéṣe tí ìwọ ó fi gbé ìní Olúwa mì.”

  2. 2 Samuẹli 20:20nǹkan bí 1022 ṣáájú Kristi

    Joabu sì dáhùn wí pé, “Kí a má rí i, kí a má rí i lọ́dọ̀ mi pé èmi gbé mì tàbí èmi sì parun.

  3. 2 Samuẹli 20:21nǹkan bí 1022 ṣáájú Kristi

    Ọ̀ràn náà kò sì rí bẹ́ẹ̀; ṣùgbọ́n ọkùnrin kan láti òkè Efraimu, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣeba, ọmọ Bikri, ni ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí ọba, àní sí Dafidi: fi òun nìkan ṣoṣo lé wa lọ́wọ́, èmi ó sì fi ìlú sílẹ̀.” Obìnrin náà sì wí fún Joabu pé, “Wò ó, orí rẹ̀ ni a ó sì sọ láti inú odi wá.”

  4. 2 Samuẹli 20:22nǹkan bí 1022 ṣáájú Kristi

    Obìnrin náà sì mú ìmọ́ràn rẹ̀ tọ gbogbo àwọn ènìyàn náà, wọ́n sì bẹ Ṣeba ọmọ Bikri lórí, wọ́n sì sọ ọ́ sí Joabu. Òun sì fún ìpè, wọ́n sì túká ní ìlú náà, olúkúlùkù sí àgọ́ rẹ̀. Joabu sí padà lọ sí Jerusalẹmu àti sọ́dọ̀ ọba.

  5. 2 Samuẹli 20:23nǹkan bí 1022 ṣáájú Kristi

    Joabu sì ni olórí gbogbo ogun Israẹli; Benaiah ọmọ Jehoiada sì jẹ́ olórí àwọn Kereti, àti ti àwọn Peleti.

  6. 2 Samuẹli 20:24nǹkan bí 1022 ṣáájú Kristi

    Adoniramu sì jẹ́ olórí àwọn agbowó òde; Jehoṣafati ọmọ Ahiludi sì jẹ́ olùkọsílẹ̀ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní ìlú.

  7. 2 Samuẹli 20:25nǹkan bí 1022 ṣáájú Kristi

    Ṣefa sì jẹ́ akọ̀wé; Sadoku àti Abiatari sì ni àwọn àlùfáà.

  8. 2 Samuẹli 20:26nǹkan bí 1022 ṣáájú Kristi

    Ira pẹ̀lú, ará Jairi ni ń ṣe àlùfáà lọ́dọ̀ Dafidi.

  9. 2 Samuẹli 21:1nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi

    Ìyàn kan sì mú lọ́jọ́ Dafidi ní ọdún mẹ́ta, láti ọdún dé ọdún; Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa, Olúwa sì wí pé, “Nítorí ti Saulu ni, àti nítorí ilé rẹ̀ tí ó kún fún ẹ̀jẹ̀, nítorí pé ó pa àwọn ará Gibeoni.”

  10. 2 Samuẹli 21:2nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi

    Ọba sì pe àwọn ará Gibeoni, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀; àwọn ará Gibeoni kì í ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Israẹli, ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ àwọn tí ó kù nínú àwọn ọmọ Amori; àwọn ọmọ Israẹli sì ti búra fún wọn, Saulu sì ń wá ọ̀nà àti pa wọ́n ní ìtara rẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli àti Juda.

  11. 2 Samuẹli 21:3nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi

    Dafidi sì bi àwọn ará Gibeoni léèrè pé, “Kí ni èmi ó ṣe fún un yín? Àti kín ni èmi ó fi ṣe ètùtù, kí ẹ̀yin lè súre fún ilẹ̀ ìní Olúwa?”

  12. 2 Samuẹli 21:4nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi

    Àwọn ará Gibeoni sì wí fún un pé, “Kì í ṣe ọ̀rọ̀ fàdákà tàbí wúrà láàrín wa àti Saulu tàbí ìdílé rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì fẹ́ kí ẹ pa ẹnìkan ní Israẹli.” Dafidi sì wí pé, “Èyí tí ẹ̀yin bá wí ni èmi ó ṣe?”

  13. 2 Samuẹli 21:5nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi

    Wọ́n sì wí fún ọba pé, “Ọkùnrin tí ó run wá, tí ó sì rò láti pa wá rẹ́ ki a má kù níbikíbi nínú gbogbo agbègbè Israẹli.

  14. 2 Samuẹli 21:6nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi

    Mú ọkùnrin méje nínú àwọn ọmọ rẹ̀ fún wá, àwa ó sì so wọ́n rọ̀ fún Olúwa ní Gibeah ti Saulu ẹni tí Olúwa ti yàn.” Ọba sì wí pé, “Èmi ó fi wọ́n fún yín.”

  15. 2 Samuẹli 21:7nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n ọba dá Mefiboṣeti sí, ọmọ Jonatani, ọmọ Saulu, nítorí ìbúra Olúwa tí ó wà láàrín Dafidi àti Jonatani ọmọ Saulu.

  16. 2 Samuẹli 21:8nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi

    Ọba sì mú àwọn ọmọkùnrin méjèèjì tí Rispa ọmọbìnrin Aiah bí fún Saulu, àní Ammoni àti Mefiboṣeti àwọn ọmọkùnrin márààrún ti Merabu, ọmọbìnrin Saulu, àwọn tí ó bí fún Adrieli ọmọ Barsillai ará Mehola.

  17. 2 Samuẹli 21:9nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi

    Ó sì fi wọ́n lé àwọn ará Gibeah lọ́wọ́, wọ́n sì so wọ́n rọ̀ lórí òkè níwájú Olúwa: àwọn méjèèjì sì ṣubú lẹ́ẹ̀kan, a sì pa wọ́n ní ìgbà ìkórè, ní ìbẹ̀rẹ̀, ìkórè ọkà barle.

  18. 2 Samuẹli 21:10nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi

    Rispa ọmọbìnrin Aiah sì mú aṣọ ọ̀fọ̀ kan, ó sì tẹ́ fún ará rẹ̀ lórí àpáta ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè, títí omi fi dà sí wọn lára láti ọ̀run wá, kò sì jẹ́ kí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run bà lé wọn lọ́sàn, tàbí àwọn ẹranko igbó lóru.

  19. 2 Samuẹli 21:11nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi

    A sì ro èyí, tí Rispa ọmọbìnrin Aiah obìnrin Saulu ṣe, fún Dafidi.

  20. 2 Samuẹli 21:12nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi

    Dafidi sì lọ ó sì kó egungun Saulu, àti egungun Jonatani ọmọ rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọkùnrin Jabesi Gileadi, àwọn tí ó jí wọn kúrò ní ìta Beti-Ṣani, níbi tí àwọn Filistini gbé so wọ́n rọ̀, nígbà tí àwọn Filistini pa Saulu ní Gilboa.

  21. 2 Samuẹli 21:13nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi

    Ó sì mú egungun Saulu àti egungun Jonatani ọmọ rẹ̀ láti ibẹ̀ náà wá; wọ́n sì kó egungun àwọn tí a ti so rọ̀ jọ.

  22. 2 Samuẹli 21:14nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi

    Wọ́n sì sin egungun Saulu àti ti Jonatani ọmọ rẹ̀ ní ilé Benjamini, ní Ṣela, nínú ibojì Kiṣi baba rẹ̀, wọ́n sì ṣe gbogbo èyí tí ọba paláṣẹ, lẹ́yìn èyí ni Ọlọ́run si gba ẹ̀bẹ̀ nítorí ilẹ̀ náà.

  23. 2 Samuẹli 21:15nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi

    Ogun sì tún wà láàrín àwọn Filistini àti Israẹli; Dafidi sì sọ̀kalẹ̀, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì bá àwọn Filistini jà, ó sì rẹ Dafidi.

  24. 2 Samuẹli 21:16nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi

    Iṣbi-Benobu sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn Rafa, ẹni tí ọ̀kọ̀ rẹ̀ wọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ṣékélì idẹ, ó sì sán idà tuntun, ó sì gbèrò láti pa Dafidi.

  25. 2 Samuẹli 21:17nǹkan bí 1018 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n Abiṣai ọmọ Seruiah ràn án lọ́wọ́, ó sì kọlu Filistini náà, ó sì pa á. Nígbà náà ni àwọn ìránṣẹ́ Dafidi sì búra fún un pé, “Ìwọ kì yóò sì tún bá wa jáde lọ sí ibi ìjà mọ́ kí ìwọ má ṣe pa iná Israẹli.”