circa 1010–970 BC
The Reign of David
David unites the tribes, conquers Jerusalem, and establishes Israel's golden age—even through deep personal failure.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- 2 Samuẹli 19:37nǹkan bí 1023 ṣáájú Kristi
Èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ padà, èmi ó sì kú ní ìlú mi, a ó sì sin mí ní ibojì baba àti ìyá mi. Sì wo Kimhamu ìránṣẹ́ rẹ, yóò bá olúwa mi ọba gòkè; ìwọ ó sì ṣe ohun tí ó bá tọ́ lójú rẹ fún un.”
- 2 Samuẹli 19:38nǹkan bí 1023 ṣáájú Kristi
Ọba sì dáhùn wí pé, “Kimhamu yóò bá mi gòkè, èmi ó sì ṣe èyí tí ó tọ́ lójú rẹ̀ fún un; ohunkóhun tí ìwọ bá sì béèrè lọ́wọ́ mi, èmi ó ṣe é fún ọ.”
- 2 Samuẹli 19:39nǹkan bí 1023 ṣáájú Kristi
Gbogbo àwọn ènìyàn sì gòkè odò Jordani ọba sì gòkè; ọba sì fi ẹnu ko Barsillai lẹ́nu, ó sì súre fún un; òun sì padà sí ilé rẹ̀.
- 2 Samuẹli 19:40nǹkan bí 1023 ṣáájú Kristi
Ọba sì ń lọ́ sí Gilgali, Kimhamu sì ń bà a lọ, gbogbo àwọn ènìyàn Juda sì ń ṣe ìkẹ́ ọba, àti ààbọ̀ àwọn ènìyàn Israẹli.
- 2 Samuẹli 19:41nǹkan bí 1023 ṣáájú Kristi
Sì wò ó, gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli sì tọ ọba wá, wọ́n sì wí fún ọba pé, “Èéṣe tí àwọn arákùnrin wa àwọn ọkùnrin Juda fi jí ọ kúrò, tí wọ́n sì fi mú ọba àti àwọn ará ilé rẹ̀ gòkè odò Jordani, àti gbogbo àwọn ènìyàn Dafidi pẹ̀lú rẹ?”
- 2 Samuẹli 19:42nǹkan bí 1023 ṣáájú Kristi
Gbogbo ọkùnrin Juda sì dá àwọn ọkùnrin Israẹli lóhùn pé, “Nítorí pé ọba bá wa tan ni; èéṣe tí ẹ̀yin fi bínú nítorí ọ̀ràn yìí? Àwa jẹ nínú oúnjẹ ọba rárá bí? Tàbí ó fi ẹ̀bùn kan fún wa bí?”
- 2 Samuẹli 19:43nǹkan bí 1023 ṣáájú Kristi
Àwọn ọkùnrin Israẹli náà sì dá àwọn ọkùnrin Juda lóhùn pé, “Àwa ní ipá mẹ́wàá nínú ọba, àwa sì ní nínú Dafidi jù yín lọ, èéṣì ṣe tí ẹ̀yin kò fi kà wá sí, tí ìmọ̀ wa kò fi ṣáájú láti mú ọba wa padà?” Ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin Juda sì le ju ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin Israẹli.
- 2 Samuẹli 20:1nǹkan bí 1022 ṣáájú Kristi
Ọkùnrin Beliali kan sì ń bẹ níbẹ̀ orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Ṣeba ọmọ Bikri ará Benjamini; ó sì fún ìpè ó sì wí pé, “Àwa kò ní ipa nínú Dafidi, bẹ́ẹ̀ ni àwa kò ni ìní nínú ọmọ Jese! Kí olúkúlùkù ọkùnrin lọ sí àgọ́ rẹ̀, ẹ̀yin Israẹli!”
- 2 Samuẹli 20:2nǹkan bí 1022 ṣáájú Kristi
Gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli sì lọ kúrò lẹ́yìn Dafidi, wọ́n sì ń tọ́ Ṣeba ọmọ Bikri lẹ́yìn, ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Juda sì fi ara mọ́ ọba wọn láti odò Jordani wá títí ó fi dé Jerusalẹmu.
- 2 Samuẹli 20:3nǹkan bí 1022 ṣáájú Kristi
Dafidi sì wà ní ilé rẹ̀ ní Jerusalẹmu; ọba sì mú àwọn obìnrin mẹ́wàá tí í ṣe àlè rẹ̀, àwọn tí ó ti fi sílẹ̀ láti máa ṣọ́ ilé, Ó sì há wọn mọ́ ilé, ó sì ń bọ́ wọn, ṣùgbọ́n kò sì tún wọlé tọ̀ wọ́n mọ́. A sì sé wọn mọ́ títí di ọjọ́ ikú wọn, wọ́n sì wà bí opó.
- 2 Samuẹli 20:4nǹkan bí 1022 ṣáájú Kristi
Ọba sì wí fún Amasa pé, “Pe àwọn ọkùnrin Juda fún mi ní ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta òní, kí ìwọ náà kí o sì wà níhìn-ín yìí.”
- 2 Samuẹli 20:5nǹkan bí 1022 ṣáájú Kristi
Amasa sì lọ láti pe àwọn ọkùnrin Juda; ṣùgbọ́n ó sì dúró pẹ́ ju àkókò tí a fi fún un.
- 2 Samuẹli 20:6nǹkan bí 1022 ṣáájú Kristi
Dafidi sì wí fún Abiṣai pé, “Nísinsin yìí Ṣeba ọmọ Bikri yóò ṣe wá ní ibi ju ti Absalomu lọ; ìwọ mú àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ, kí o sì lépa rẹ̀, kí ó má ba à rí ìlú olódi wọ̀, kí ó sì bọ́ lọ́wọ́ wa.”
- 2 Samuẹli 20:7nǹkan bí 1022 ṣáájú Kristi
Àwọn ọmọkùnrin Joabu sì jáde tọ̀ ọ́ lọ, àti àwọn Kereti, àti àwọn Peleti, àti gbogbo àwọn ọkùnrin alágbára, wọ́n sì ti Jerusalẹmu jáde lọ, láti lépa Ṣeba ọmọ Bikri.
- 2 Samuẹli 20:8nǹkan bí 1022 ṣáájú Kristi
Nígbà tí wọ́n dé ibi òkúta ńlá tí ó wà ní Gibeoni, Amasa sì ṣáájú wọn, Joabu sì di àmùrè sí agbádá rẹ̀ tí ó wọ̀, ó sì sán idà rẹ̀ mọ́ ìdí, nínú àkọ̀ rẹ̀, bí ó sì ti ń lọ, ó yọ́ jáde.
- 2 Samuẹli 20:9nǹkan bí 1022 ṣáájú Kristi
Joabu sì bi Amasa léèrè pé, “Àlàáfíà ha kọ́ ni bí, ìwọ arákùnrin mi?” Joabu sì na ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, di Amasa ní irùngbọ̀n mú láti fi ẹnu kò ó lẹ́nu.
- 2 Samuẹli 20:10nǹkan bí 1022 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n Amasa kò sì kíyèsi idà tí ń bẹ lọ́wọ́ Joabu, bẹ́ẹ̀ ni òun sì fi gún un ní ikùn, ìfun rẹ̀ sì tú dà sílẹ̀, òun kò sì tún gún un mọ́, Amasa sì kú. Joabu àti Abiṣai arákùnrin rẹ̀ sì lépa Ṣeba ọmọ Bikri.
- 2 Samuẹli 20:11nǹkan bí 1022 ṣáájú Kristi
Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ Joabu sì dúró tì Amasa, ó sì wí pé, “Ta ni ẹni tí ó fẹ́ràn Joabu? Ta ni ó sì ń ṣe ti Dafidi, kí ó máa tọ Joabu lẹ́yìn.”
- 2 Samuẹli 20:12nǹkan bí 1022 ṣáájú Kristi
Amasa sì ń yíràá nínú ẹ̀jẹ̀ láàrín ọ̀nà. Ọkùnrin náà sì rí i pé gbogbo ènìyàn sì dúró tì í, ó sì gbé Amasa kúrò lójú ọ̀nà lọ sínú igbó, ó sì fi aṣọ bò ó, nígbà tí ó rí i pé ẹnikẹ́ni tí ó bá dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, á dúró.
- 2 Samuẹli 20:13nǹkan bí 1022 ṣáájú Kristi
Nígbà tí ó sì gbé Amasa kúrò lójú ọ̀nà gbogbo ènìyàn sì tọ Joabu lẹ́yìn láti lépa Ṣeba ọmọ Bikri.
- 2 Samuẹli 20:14nǹkan bí 1022 ṣáájú Kristi
Ṣeba kọjá nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli sí Abeli-Beti-Maaka, àti gbogbo àwọn ará Beri; wọ́n sì kó ara wọn jọ, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn pẹ̀lú.
- 2 Samuẹli 20:15nǹkan bí 1022 ṣáájú Kristi
Wọ́n wá, wọ́n sì dó tì Ṣeba ní Abeli-Beti-Maaka, wọ́n sì mọ odi ti ìlú náà, odi náà sì dúró ti odi ìlú náà, gbogbo ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ Joabu sì ń gbìyànjú láti wó ògiri náà lulẹ̀.
- 2 Samuẹli 20:16nǹkan bí 1022 ṣáájú Kristi
Obìnrin ọlọ́gbọ́n kan sì kígbe sókè láti ìlú náà wá pé, “Fetísílẹ̀! Fetísílẹ̀! Èmi bẹ̀ yín, ẹ sọ fún Joabu pé, ‘Súnmọ́ ìhín yìí èmi ó sì bá a sọ̀rọ̀.’ ”
- 2 Samuẹli 20:17nǹkan bí 1022 ṣáájú Kristi
Nígbà tí òun sì súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, obìnrin náà sì wí pé, “Ìwọ ni Joabu bí?” Òun sì dáhùn wí pé, “Èmi náà ni.” Obìnrin náà sì wí fún un pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́bìnrin rẹ.” Òun sì dáhùn wí pé, “Èmi ń gbọ́.”
- 2 Samuẹli 20:18nǹkan bí 1022 ṣáájú Kristi
Ó sì sọ̀rọ̀ wí pé, “Wọ́n ti ń wí ṣáájú pé, ‘Gba ìdáhùn rẹ ní Abeli,’ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì parí ọ̀ràn náà.