- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Isaiah 9:1nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi
Síbẹ̀síbẹ̀, kò ní sí ìpòrúru kankan mọ́ fún àwọn tí ó wà nínú ìbànújẹ́. Nígbà kan rí ó rẹ ilẹ̀ Sebuluni sílẹ̀ àti ilẹ̀ Naftali pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ iwájú, yóò bu ọ̀wọ̀ fún Galili ti àwọn aláìkọlà, ní ọ̀nà Òkun, ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ Jordani.
- Isaiah 9:2nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi
Àwọn ènìyàn tí ń rìn nínú òkùnkùn ti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá; lórí àwọn tí ń gbé nínú ilẹ̀ òjìji ikú, ní ara wọn ni ìmọ́lẹ̀ mọ́ sí.
- Isaiah 9:3nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi
Ìwọ ti sọ orílẹ̀-èdè di ńlá; wọ́n sì yọ̀ níwájú rẹ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ti í yọ ayọ̀ ìkórè, gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ti í yọ̀ nígbà tí à ń pín ìkógun.
- Isaiah 9:4nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi
Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí a ṣẹ́gun Midiani, ìwọ ti fọ́ ọ túútúú àjàgà ti ń pa wọ́n lẹ́rù, ọ̀pá tí ó dábùú èjìká wọn, ọ̀gọ aninilára wọn.
- Isaiah 9:5nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi
Gbogbo bàtà jagunjagun tí a ti lò lójú ogun àti gbogbo ẹ̀wù tí a yí nínú ẹ̀jẹ̀, ni yóò wà fún ìjóná, àti ohun èlò iná dídá.
- Isaiah 9:6nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi
Nítorí a bí ọmọ kan fún wa, a fi ọmọkùnrin kan fún wa, ìjọba yóò sì wà ní èjìká rẹ̀. A ó sì máa pè é ní Ìyanu Olùdámọ̀ràn, Ọlọ́run Alágbára, Baba ayérayé, Ọmọ ọba aládé Àlàáfíà.
- Isaiah 9:7nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi
Ní ti gbígbòòrò Ìjọba rẹ̀ àti àlàáfíà rẹ̀ ni kì yóò ní ìpẹ̀kun. Yóò jẹ ọba lórí ìtẹ́ Dafidi àti lórí ẹ̀kún un rẹ̀ gbogbo, nípa ìfìdímúlẹ̀ àti ìgbéró rẹ̀, pẹ̀lú òtítọ́ àti òdodo láti ìgbà náà lọ àti títí láéláé. Ìtara Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú èyí ṣẹ.
- Isaiah 9:8nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi
Olúwa ti dojú iṣẹ́ kan kọ Jakọbu; yóò sì wá sórí Israẹli.
- Isaiah 9:9nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi
Gbogbo ènìyàn ni yóò sì mọ̀ ọ́n— Efraimu àti gbogbo olùgbé Samaria— tí ó sọ pẹ̀lú ìgbéraga àti gààrù àyà pé.
- Isaiah 9:10nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi
Àwọn bíríkì ti wó lulẹ̀ ṣùgbọ́n a ó tún un kọ́ pẹ̀lú òkúta dídán, a ti gé àwọn igi sikamore lulẹ̀ ṣùgbọ́n igi kedari ní a ó fi dípò wọn.
- Isaiah 9:11nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n Olúwa fún àwọn ọ̀tá Resini ní agbára láti dojúkọ wọ́n ó sì ti rú àwọn ọ̀tá wọn sókè.
- Isaiah 9:12nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi
Àwọn ará Aramu láti ìlà-oòrùn àti Filistini láti ìwọ̀-oòrùn. Wọ́n sì fi gbogbo ẹnu jẹ Israẹli run. Ní gbogbo èyí ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ nà jáde síbẹ̀.
- Isaiah 9:13nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kò tí ì yípadà sí ẹni náà tí ó lù wọ́n bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kò wá Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
- Isaiah 9:14nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi
Nítorí náà ni Olúwa yóò ṣe ké àti orí àti ìrù kúrò ní Israẹli, àti ọ̀wá ọ̀pẹ àti koríko odò ní ọjọ́ kan ṣoṣo,
- Isaiah 9:15nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi
àwọn àgbàgbà, àti àwọn gbajúmọ̀ ní orí, àwọn wòlíì tí ń kọ́ni ní irọ́ ni ìrù.
- Isaiah 9:16nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi
Àwọn tí ó ń tọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣì wọ́n lọ́nà, àwọn tí a sì tọ́ ni a ń sin sí ìparun.
- Isaiah 9:17nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi
Nítorí náà, Olúwa kì yóò dunnú sí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tàbí kí ó káàánú àwọn aláìní baba àti opó, nítorí pé gbogbo wọn jẹ́ ìkà àti aláìmọ Ọlọ́run, ibi ni ó ti ẹnu wọn jáde. Síbẹ̀, fún gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò ọwọ́ rẹ̀ sì wà ní gbígbéró.
- Isaiah 9:18nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi
Nítòótọ́ ìwà búburú ń jóni bí iná, yóò jó ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún run, yóò sì rán nínú pàǹtí igbó, tó bẹ́ẹ̀ tí yóò fi gòkè lọ bí ọ̀wọ́n èéfín ti í gòkè.
- Isaiah 9:19nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi
Nípasẹ̀ ìbínú Olúwa àwọn ọmọ-ogun ilẹ̀ náà yóò di gbígbẹ àwọn ènìyàn yóò sì di ohun ìdáná, ẹnìkan kì yóò sì dá arákùnrin rẹ̀ sí.
- Isaiah 9:20nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi
Ní apá ọ̀tún wọn yóò jẹrun, síbẹ̀ ebi yóò sì máa pa wọ́n, ní apá òsì, wọn yóò jẹ, ṣùgbọ́n, kò ní tẹ́ wọn lọ́rùn. Ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò sì máa jẹ ẹran-ara apá rẹ̀.
- Isaiah 9:21nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi
Manase yóò máa jẹ Efraimu, nígbà tí Efraimu yóò jẹ Manase wọn yóò parapọ̀ dojúkọ Juda. Síbẹ̀síbẹ̀, ìbínú un rẹ̀ kò yí kúrò Ọwọ́ọ rẹ̀ sì wà ní gbígbéró.
- Isaiah 10:1nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Ègbé ni fún àwọn ti ń ṣe òfin àìṣòdodo,
- Isaiah 10:2nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
láti dún àwọn aláìní ní ẹ̀tọ́ wọn àti láti fa ọwọ́ ìdájọ́ sẹ́yìn kúrò níwájú àwọn olùpọ́njú ènìyàn mi, wọ́n sọ àwọn ọ̀pọ̀ di ìjẹ fún wọn, wọ́n sì ń ja àwọn aláìní baba lólè.
- Isaiah 10:3nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Kí ni ìwọ yóò ṣe ní ọjọ́ ìṣirò nígbà tí ìparun bá ti ọ̀nà jíjìn wá? Ta ni ìwọ yóò sá tọ̀ fún ìrànlọ́wọ́? Níbo ni ìwọ yóò fi ọrọ̀ rẹ sí?
- Isaiah 10:4nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Ohunkóhun kò ní ṣẹ́kù mọ́ bí kò ṣe láti tẹ̀ ba láàrín àwọn ìgbèkùn tàbí kí o ṣubú sáàrín àwọn tí a pa. Pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ìbínú rẹ̀ kò kúrò, ọwọ́ rẹ̀ sì tún gbé sókè.