- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Isaiah 10:5nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
“Ègbé ni fún àwọn ará Asiria, ọ̀gọ ìbínú mi, ní ọwọ́ ẹni tí kùmọ̀ ìbínú mi wà!
- Isaiah 10:6nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Mo rán an sí orílẹ̀-èdè aláìní Ọlọ́run, mo dojú rẹ̀ kọ àwọn ènìyàn tí ó mú mi bínú láti já ẹrù gbà, àti láti kó ìkógun láti tẹ̀ mọ́lẹ̀ bí amọ̀ ní ojú òpópó.
- Isaiah 10:7nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n, èyí kì í ṣe ohun tí ó fẹ́ ṣe, èyí kọ́ ni ohun tí ó ní lọ́kàn; èrò rẹ̀ ni láti parun, láti fi òpin sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè.
- Isaiah 10:8nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
‘Kì í ha ṣe pé ọba ni gbogbo àwọn aláṣẹ mi?’ ni Olúwa wí.
- Isaiah 10:9nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
‘Kì í ha ṣe pé Kalno dàbí i Karkemiṣi? Hamati kò ha dàbí i Arpadi, àti Samaria bí i Damasku?
- Isaiah 10:10nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ mi ti gbá ìjọba àwọn òrìṣà mú, ìjọba tí ère rẹ̀ pọ̀ ju ti Jerusalẹmu àti Samaria lọ.
- Isaiah 10:11nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Èmi kì yóò a bá Jerusalẹmu wí àti àwọn ère rẹ̀?’ ” Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ṣe sí Samaria àti àwọn ère rẹ̀?
- Isaiah 10:12nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Nígbà tí Olúwa ti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ sí òkè Sioni àti Jerusalẹmu, yóò sọ wí pé, “Èmi yóò fi ìyà jẹ ọba Asiria nítorí gààrù àyà rẹ̀ àti ìgbéraga ojú rẹ̀.
- Isaiah 10:13nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Nítorí ó sọ pé: “ ‘Pẹ̀lú agbára ọwọ́ mi ni mo fi ṣe èyí àti pẹ̀lú ọgbọ́n ọ̀n mi, nítorí mo ní òye. Mo mú ààlà àwọn orílẹ̀-èdè kúrò, mo sì ti kó ìṣúra wọn. Gẹ́gẹ́ bí alágbára kan, mo borí àwọn ọba wọn.
- Isaiah 10:14nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Bí ènìyàn ti í tọwọ́ bọ ìtẹ́ ẹyẹ, bẹ́ẹ̀ ni ọwọ́ mi tẹ ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè. Bí ènìyàn ti í kó ẹyin tí a kọ̀sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni mo kó àwọn orílẹ̀-èdè kò sí èyí tí ó fi apá lu apá, tàbí kí ó ya ẹnu láti dún.’ ”
- Isaiah 10:15nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Ǹjẹ́ àáké le gbé ara rẹ̀ sókè kọjá ẹni tí ó ń fì í, tàbí kí ayùn fọ́nnu sí ẹni tí ó ń lò ó? Àfi bí ẹni pé ọ̀pá ó na ẹni tí ó gbé e sókè, tàbí kí kùmọ̀ lu èyí tí kì í ṣe igi.
- Isaiah 10:16nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Nítorí náà, ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, yóò rán ààrùn ìrẹ̀dànù sórí àwọn akíkanjú jagunjagun, lábẹ́ ògo rẹ̀ ni iná kan yóò ti sọ gẹ́gẹ́ bí iná ajónirun.
- Isaiah 10:17nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Ìmọ́lẹ̀ Israẹli yóò di iná, Ẹni Mímọ́ rẹ̀ yóò jẹ́ ọ̀wọ́-iná, ní ọjọ́ kan ṣoṣo yóò jó yóò sì run àti ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n.
- Isaiah 10:18nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Gbogbo ẹwà igbó o rẹ̀, àti àwọn pápá ọlọ́ràá gbogbo rẹ̀ ni yóò run pátápátá, gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ṣàìsàn ti í ṣòfò dànù.
- Isaiah 10:19nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Àwọn igi tí yóò kù nínú igbó o rẹ̀ yóò kéré níye, tí ọ̀dọ́mọdé yóò fi le kọ̀ wọ́n sílẹ̀.
- Isaiah 10:20nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ náà, àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Israẹli, àwọn tí ó yè ní ilé e Jakọbu, kò ní gbẹ́kẹ̀lé ẹni náà tí ó lù wọ́n bolẹ̀, ṣùgbọ́n ní òtítọ́ yóò gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, Ẹni Mímọ́ Israẹli.
- Isaiah 10:21nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Àwọn ìyókù yóò padà, àwọn ìyókù ti Jakọbu yóò padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Alágbára.
- Isaiah 10:22nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn rẹ, ìwọ Israẹli dàbí yanrìn ní Òkun, ẹni díẹ̀ ni yóò padà. A ti pàṣẹ ìparun, àkúnwọ́sílẹ̀ àti òdodo.
- Isaiah 10:23nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú un ṣẹ, ìparun tí a ti pàṣẹ rẹ̀ lórí gbogbo ilẹ̀ náà.
- Isaiah 10:24nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Nítorí náà, báyìí ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “Ẹ̀yin ènìyàn mi tí ó ń gbé Sioni, ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn Asiria, tí ó ń fi ọ̀pá lù yín, tí wọ́n sì ń gbé ọ̀gọ tì yín bí Ejibiti ti ṣe.
- Isaiah 10:25nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Láìpẹ́, ìbínú mi sí i yín yóò wá sí òpin n ó sì dojú ìrunú mi kọ wọ́n, fún ìparun wọn.”
- Isaiah 10:26nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò nà wọ́n ní ẹgba. Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe lu Midiani ní òkè Orebu, yóò sì gbé ọ̀pá rẹ̀ lé orí omi gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní Ejibiti.
- Isaiah 10:27nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ náà, a ó gbé ẹrù wọn kúrò ní èjìká a yín, àti àjàgà a wọn kúrò ní ọrùn un yín a ó fọ́ àjàgà náà, nítorí pé ẹ̀yin ó ti sanra.
- Isaiah 10:28nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Wọ́n wọ Aiati, wọ́n gba Migroni kọjá, wọ́n kó nǹkan pamọ́ sí Mikmasi.
- Isaiah 10:29nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Wọ́n ti rékọjá ọ̀nà, wọ́n wí pé, “Àwa ó tẹ̀dó sí Geba lóru yìí.” Rama mì tìtì Gibeah ti Saulu sálọ.