- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Isaiah 48:16nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
“Ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi kí ẹ sì dẹtí sí èyí: “Láti ìgbà ìkéde àkọ́kọ́ èmi kò sọ̀rọ̀ ní ìkọ̀kọ̀; ní àsìkò tí ó sì ṣẹlẹ̀, Èmi wà níbẹ̀.” Àti ní àkókò yìí, Olúwa Olódùmarè ni ó ti rán mi, pẹ̀lú ẹ̀mí rẹ̀.
- Isaiah 48:17nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Èyí ni ohun tí Olúwa wí, Olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli: “Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ó kọ́ ọ ní ohun tí ó dára fún ọ, tí ó tọ́ ọ ṣọ́nà tí ó yẹ kí o máa rìn.
- Isaiah 48:18nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Bí ó bá ṣe pé ìwọ bá ti tẹ́tí sílẹ̀ sí àṣẹ mi, àlàáfíà rẹ kì bá ti dàbí ì ti odò, àti òdodo rẹ bí ìgbì Òkun.
- Isaiah 48:19nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Àwọn ọmọ rẹ ìbá ti dàbí iyanrìn, àwọn ọmọ yín bí i hóró ọkà tí a kò lè kà tán; orúkọ wọn ni a kì yóò ké kúrò tàbí kí a pa wọ́n run níwájú mi.”
- Isaiah 48:20nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Fi Babeli sílẹ̀, sá fún àwọn ará Babeli, ṣe ìfilọ̀ èyí pẹ̀lú ariwo ayọ̀ kí o sì kéde rẹ̀. Rán an jáde lọ sí òpin ilẹ̀ ayé; wí pé, “Olúwa ti dá ìránṣẹ́ rẹ̀ Jakọbu nídè.”
- Isaiah 48:21nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Òrùngbẹ kò gbẹ wọ́n nígbà tí ó kó wọn kọjá nínú aginjù; ó jẹ́ kí omi ó sàn fún wọn láti inú àpáta; ó fọ́ àpáta omi sì tú jáde.
- Isaiah 48:22nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
“Kò sí àlàáfíà,” ni Olúwa wí, “Fún àwọn ìkà.”
- Isaiah 49:1nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin erékùṣù: gbọ́ èyí, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè jíjìnnà réré: kí a tó bí mi Olúwa ti pè mí; láti ìgbà bíbí mi ni ó ti dá orúkọ mi.
- Isaiah 49:2nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ó ṣe ẹnu mi bí idà tí a pọ́n, ní abẹ́ òjìji ọwọ́ rẹ̀ ni ó ti pa mí mọ́: ó ṣe mí ní ọfà tí a ti dán, ó sì fi mí pamọ́ sínú àpò rẹ̀.
- Isaiah 49:3nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ó sọ fún mi pé, “Ìránṣẹ́ mi ni ìwọ í ṣe, Israẹli nínú ẹni tí n ó ti fi ògo mi hàn.”
- Isaiah 49:4nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n èmi sọ pé, “Mo ti ṣe wàhálà lórí asán; mo ti lo gbogbo ipá mi lórí asán àti ìmúlẹ̀mófo. Síbẹ̀síbẹ̀ ohun tí ó tọ́ sí mi ṣì wà lọ́wọ́ Olúwa, èrè mi sì ń bẹ pẹ̀lú Ọlọ́run mi.”
- Isaiah 49:5nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Nísinsin yìí Olúwa wí pé ẹni tí ó mọ̀ mí láti inú wá láti jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ láti mú Jakọbu padà tọ̀ mí wá àti láti kó Israẹli jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀, nítorí pé a bọ̀wọ̀ fún mi ní ojú Olúwa Ọlọ́run mi sì ti jẹ́ agbára mi,
- Isaiah 49:6nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Òun wí pé: “Ó jẹ́ ohun kékeré fún ọ láti jẹ́ ìránṣẹ́ mi láti mú ẹ̀yà Jakọbu padà bọ̀ sípò àti láti mú àwọn ti Israẹli tí mo ti pamọ́. Èmi yóò sì fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ fún àwọn kèfèrí, kí ìwọ kí ó lè mú ìgbàlà mi wá sí òpin ilẹ̀ ayé.”
- Isaiah 49:7nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ohun tí Olúwa wí nìyìí, Olùdáǹdè àti Ẹni Mímọ́ Israẹli— sí ẹni náà tí a gàn tí a sì kórìíra lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè, sí ìránṣẹ́ àwọn aláṣẹ: “Àwọn ọba yóò rí ọ wọn yóò sì dìde sókè, àwọn ọmọ ọba yóò rí i wọn yóò sì wólẹ̀, nítorí Olúwa ẹni tí í ṣe olóòtítọ́, Ẹni Mímọ́ Israẹli tí ó ti yàn ọ́.”
- Isaiah 49:8nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ohun tí Olúwa wí nìyìí: “Ní àkókò ojúrere mi, èmi yóò dá ọ lóhùn, àti ní ọjọ́ ìgbàlà, èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́; Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́ láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn, láti mú ilẹ̀ padà bọ̀ sípò àti láti ṣe àtúnpín ogún rẹ̀ tí ó ti dahoro,
- Isaiah 49:9nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
láti sọ fún àwọn ìgbèkùn pé, ‘Ẹ jáde wá,’ àti fún àwọn tí ó wà nínú òkùnkùn pé, ‘Ẹ gba òmìnira!’ “Wọn yóò máa jẹ ní ẹ̀bá ọ̀nà àti koríko tútù lórí òkè aláìléwéko.
- Isaiah 49:10nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ebi kì yóò pa wọ́n bẹ́ẹ̀ ni òǹgbẹ kì yóò gbẹ wọ́n, tàbí kí ooru inú aṣálẹ̀ tàbí oòrùn kí ó pa wọ́n. Ẹni tí ó ṣàánú fún wọn ni yóò máa tọ́ wọn, tí yóò sì mú wọn lọ sí ibi orísun omi.
- Isaiah 49:11nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Èmi yóò sọ gbogbo àwọn òkè ńlá mi di ojú ọ̀nà àti gbogbo òpópónà mi ni a ó gbé sókè.
- Isaiah 49:12nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Kíyèsi i, wọn yóò wá láti ọ̀nà jíjìn àwọn díẹ̀ láti àríwá àti àwọn díẹ̀ láti ìwọ̀-oòrùn, àwọn díẹ̀ láti ẹkùn Siene.”
- Isaiah 49:13nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ẹ hó fún ayọ̀, ẹyin ọ̀run; yọ̀, ìwọ ilẹ̀ ayé; bú sórin, ẹ̀yin òkè ńlá! Nítorí Olúwa tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú yóò sì ṣàánú fún àwọn ẹni tí a ń pọ́n lójú.
- Isaiah 49:14nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n Sioni sọ pé, “Olúwa ti kọ̀ mí sílẹ̀, Olúwa ti gbàgbé è mi.”
- Isaiah 49:15nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
“Ǹjẹ́ abiyamọ ha le gbàgbé ọmọ ọmú rẹ̀ kí ó má sì ṣàánú fún ọmọ rẹ̀ tí ó ti bí? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun le gbàgbé, Èmi kì yóò gbàgbé rẹ!
- Isaiah 49:16nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Kíyèsi i, mo ti kọ ọ́ sí àtẹ́lẹwọ́ mi ògiri rẹ wà níwájú mi nígbà gbogbo.
- Isaiah 49:17nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Àwọn ọmọ rẹ ti kánjú padà, àti àwọn tí ó sọ ọ́ dahoro ti padà lẹ́yìn rẹ.
- Isaiah 49:18nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Gbójú rẹ sókè kí o sì wò yíká; gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ kórajọ wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ. Níwọ́n ìgbà tí mo bá wà láààyè,” ni Olúwa wí, “Ìwọ yóò wọ gbogbo wọ́n gẹ́gẹ́ bí ohun ọ̀ṣọ́; ìwọ yóò wọ̀ wọ́n gẹ́gẹ́ bí ìyàwó.