Fò sí àkóónú

circa 800–400 BC

The Hebrew Prophets

God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.

3,706 ẹsẹ · 14 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Isaiah 47:6nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Inú bí mi sí àwọn ènìyàn mi tí mo sì ba ogún mi jẹ́, mo fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́, Ìwọ kò sì síjú àánú wò wọ́n. Lórí àwọn arúgbó pẹ̀lú ní o gbé àjàgà tí ó wúwo lé.

  2. Isaiah 47:7nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Ìwọ wí pé, ‘Èmi yóò tẹ̀síwájú títí láé— ọbabìnrin ayérayé!’ Ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsi nǹkan wọ̀nyí tàbí kí o ronú nípa ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀.

  3. Isaiah 47:8nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    “Nísinsin yìí, tẹ́tí sílẹ̀, ìwọ oníwọ̀ra ẹ̀dá tí o kẹ̀tẹ̀ǹfẹ̀ nínú ààbò rẹ tí o sì ń sọ fún ara rẹ pé, ‘Èmi ni, kò sì ṣí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi. Èmi kì yóò di opó tàbí kí n pàdánù àwọn ọmọ.’

  4. Isaiah 47:9nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Méjèèjì yìí ni yóò wá sórí rẹ láìpẹ́ jọjọ, ní ọjọ́ kan náà: pípàdánù ọmọ àti dídi opó. Wọn yóò wá sórí rẹ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ìṣe oṣó rẹ àti àwọn èpè rẹ tí ko lágbára.

  5. Isaiah 47:10nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Ìwọ ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìwà ìkà rẹ ó sì ti wí pé, ‘Kò sí ẹni tí ó rí mi?’ Ọgbọ́n àti òye rẹ ti ṣì ọ́ lọ́nà nígbà tí o wí fún ara rẹ pé, ‘Èmi ni, kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.’

  6. Isaiah 47:11nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Ìparun yóò dé bá ọ bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò mọ ọ̀nà láti ré e kúrò. Àjálù kan yóò ṣubú lù ọ́ tí o kì yóò le è fi ètùtù ré kúrò; òfò kan tí o kò le faradà ni yóò wá lójijì sí oríì rẹ.

  7. Isaiah 47:12nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    “Tẹ̀síwájú nígbà náà, pẹ̀lú àfọ̀ṣẹ rẹ àti pẹ̀lú ìwà oṣó rẹ gbogbo, tí o ti ń ṣiṣẹ́ fún láti ìgbà èwe rẹ wá. Bóyá o le è ṣàṣeyọrí, bóyá o le è dá rúgúdù sílẹ̀.

  8. Isaiah 47:13nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Gbogbo ìmọ̀ràn tí o ti gbà ni ó ti sọ ọ́ di akúrẹtẹ̀! Jẹ́ kí àwọn awòràwọ̀ rẹ bọ́ síwájú, àwọn awòràwọ̀ tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ láti oṣù dé oṣù, jẹ́ kí wọ́n gbà ọ́ lọ́wọ́ ohun tí ó ń bọ̀ wá bá ọ.

  9. Isaiah 47:14nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Lóòótọ́ wọ́n dàbí ìṣẹ́pẹ́ igi; iná ni yóò jó wọn dànù. Wọn kò kúkú lè gba ara wọn là lọ́wọ́ agbára iná náà. Kò sí èédú láti mú ara ẹnikẹ́ni gbóná níhìn-ín kò sí iná tí ènìyàn le jókòó tì.

  10. Isaiah 47:15nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe fún ọ nìyìí gbogbo èyí ní o tí ṣíṣẹ́ pẹ̀lú u rẹ̀ tí o sì ti ń rù kiri láti ìgbà èwe. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń lọ nínú àṣìṣe rẹ̀; kò sí ẹyọ ẹnìkan tí ó lè gbà ọ́.

  11. Isaiah 48:1nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    “Tẹ́tí sí èyí, ìwọ ilé e Jakọbu, ìwọ tí a ń pè pẹ̀lú orúkọ Israẹli tí o sì wá láti ẹ̀ka Juda, ìwọ tí ò ń búra ní orúkọ Olúwa tí o sì ń pe Ọlọ́run Israẹli ṣùgbọ́n kì í ṣe ní òtítọ́ àti òdodo,

  12. Isaiah 48:2nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    ìwọ tí ò ń pe ara rẹ ní ọmọ ìlú mímọ́ n nì tí o sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run Israẹli— Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.

  13. Isaiah 48:3nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Èmi sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn nǹkan ti tẹ́lẹ̀ lọ́jọ́ tó ti pẹ́, ẹnu mi ló ti kéde wọn, mo sì sọ wọ́n di mí mọ̀; lẹ́yìn náà lójijì mo gbé ìgbésẹ̀, wọ́n sì wá sí ìmúṣẹ.

  14. Isaiah 48:4nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Nítorí mo mọ bí ẹ ti jẹ́ olórí kunkun tó; àwọn iṣan ọrùn yín sì jẹ́ irin; bẹ́ẹ̀ ni iwájú yín idẹ ni.

  15. Isaiah 48:5nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà mo ti sọ nǹkan wọ̀nyí fún ọ ní ọjọ́ tí ó ti pẹ́; kí wọn ó tó ṣẹlẹ̀ mo ti kéde wọn fún un yín tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ kò fi lè sọ pé, ‘Àwọn ère mi ló ṣe wọ́n; àwọn ère igi àti òrìṣà irin ló fọwọ́sí i.’

  16. Isaiah 48:6nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Ìwọ ti gbọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí; wo gbogbo wọn. Ǹjẹ́ o kò nígbà wọ́n bí? “Láti ìsinsin yìí lọ, Èmi yóò máa sọ fún ọ nípa nǹkan tuntun, àwọn nǹkan tí ó fi ara sin tí ìwọ kò mọ̀.

  17. Isaiah 48:7nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    A dá wọn ní àkókò yìí kì í ṣe láti ìgbà pípẹ́ ìwọ kò tí ì gbọ́ nípa wọn títí di òní. Nítorí náà, ìwọ kò lè sọ pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ nípa wọn.’

  18. Isaiah 48:8nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Ìwọ a ha ti gbọ́ tàbí ó ti yé ọ bí láti ìgbà àtijọ́ etí kò ti di yíyà. Ǹjẹ́ mo mọ̀ bí o ti jẹ́ alárékérekè tó; a ń pè ọ́ ní ọlọ̀tẹ̀ láti ìgbà ìbí rẹ.

  19. Isaiah 48:9nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Nítorí orúkọ ara mi, mo dáwọ́ ìbínú mi dúró; nítorí ìyìn ara mi, mo fà á sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ, kí a má ba à ké ọ kúrò.

  20. Isaiah 48:10nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Wò ó, èmi ti tún ọ ṣe, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe bí i fàdákà; Èmi ti dán ọ wò nínú ìléru ìpọ́njú.

  21. Isaiah 48:11nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Nítorí orúkọ mi, nítorí orúkọ mi, mo ṣe èyí. Báwo ni mo ṣe lè jẹ́ kí a ba orúkọ mi jẹ́. Èmi kì yóò fi ògo mi fún ẹlòmíràn.

  22. Isaiah 48:12nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    “Tẹ́tí sí mi, ìwọ Jakọbu Israẹli ẹni tí mo pè. Èmi ni ẹni náà; Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn.

  23. Isaiah 48:13nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Ọwọ́ mi pàápàá ni ó fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, àti ọwọ́ ọ̀tún mi ni ó tẹ àwọn ọ̀run; nígbà tí mo pè wọ́n, gbogbo wọn dìde sókè papọ̀.

  24. Isaiah 48:14nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    “Gbogbo yín, ẹ péjọ kí ẹ sì gbọ́. Ta nínú wọn ni ó ti sọ nǹkan wọ̀nyí. Olúwa ti fẹ́ ẹ, yóò sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní Babiloni, apá rẹ̀ ni yóò sì wà ní ará àwọn ará Kaldea.

  25. Isaiah 48:15nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Èmi, àní Èmi ló ti sọ̀rọ̀; bẹ́ẹ̀ ni, mo ti pè é. Èmi yóò mú un wá, òun yóò sì ṣe àṣeyọrí nínú ìrìnàjò rẹ̀.