- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Isaiah 49:19nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a tí run ọ́, a sì sọ ọ́ di ahoro tí gbogbo ilẹ̀ rẹ sì di ìparun, ní ìsinsin yìí, ìwọ yóò kéré jù fún àwọn ènìyàn rẹ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ó jẹ ọ́ run ni yóò wà láti ọ̀nà jíjìn réré.
- Isaiah 49:20nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Àwọn ọmọ tí a bí ní àkókò ọ̀fọ̀ rẹ yóò sọ ní etígbọ̀ọ́ rẹ, ‘Ibi yìí ti kéré jù fún wa; ẹ fún wa láyè sí i tí a ó máa gbé.’
- Isaiah 49:21nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ ní ọkàn rẹ pé, ‘Ta ló bí àwọn yìí fún mi? Mo ti ṣọ̀fọ̀ mo sì yàgàn; a sọ mi di àtìpó a sì kọ̀ mí sílẹ̀. Ta ló wo àwọn yìí dàgbà? A fi èmi nìkan sílẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí níbo ni wọ́n ti wá?’ ”
- Isaiah 49:22nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ohun tí Olúwa Olódùmarè wí nìyìí, “Kíyèsi i, Èmi yóò ké sí àwọn aláìkọlà, Èmi yóò gbé àsíá mi sókè sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn; wọn yóò kó àwọn ọmọkùnrin yín wá ní apá wọn wọn yóò sì gbé àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ní èjìká wọn.
- Isaiah 49:23nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Àwọn ọba ni yóò jẹ́ alágbàtọ́ baba fún ọ, àwọn ayaba wọn ni yóò sì jẹ́ ìyá-alágbàtọ́. Wọn yóò foríbalẹ̀ ní iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ojú wọn dídàbolẹ̀; wọn yóò máa lá erùpẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa; gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìrètí nínú mi ni a kì yóò jákulẹ̀.”
- Isaiah 49:24nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ǹjẹ́ a le gba ìkógun lọ́wọ́ jagunjagun, tàbí kí á gba ìgbèkùn lọ́wọ́ akíkanjú?
- Isaiah 49:25nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n ohun tí Olúwa wí nìyìí: “Bẹ́ẹ̀ ni, a ó gba àwọn ìgbèkùn lọ́wọ́ àwọn jagunjagun, àti ìkógun lọ́wọ́ àwọn akíkanjú; ẹni tí ó bá ọ jà ni èmi ó bá jà, àti àwọn ọmọ rẹ ni èmi ó gbàlà.
- Isaiah 49:26nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Èmi yóò mú kí àwọn aninilára rẹ̀ jẹ ẹran-ara wọn; wọn yóò mu ẹ̀jẹ̀ ara wọn yó bí ẹni mu wáìnì. Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn yóò mọ̀ pé, Èmi, Olúwa, èmi ni Olùgbàlà rẹ, Olùdáǹdè rẹ, Alágbára kan ṣoṣo ti Jakọbu.”
- Isaiah 50:1nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ohun tí Olúwa wí nìyìí: “Níbo ni ìwé-ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ ìyá rẹ wà èyí tí mo fi lé e lọ? Tàbí èwo nínú àwọn olùyánilówó mi ni mo tà ọ́ fún? Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ni a fi tà ọ́; nítorí àìṣedéédéé rẹ ni a fi lé ìyá rẹ lọ.
- Isaiah 50:2nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Nígbà tí mo wá, èéṣe tí a kò fi rí ẹnìkan? Nígbà tí mo pè, èéṣe tí kò fi sí ẹnìkan láti dáhùn? Ọwọ́ mi a kúrú láti gbà ọ́? Èmi kò ha ní agbára láti gbà ọ́ bí? Nípa ìbáwí lásán, Èmi gbẹ omi òkun, Èmi yí àwọn odò sí aṣálẹ̀; àwọn ẹja wọn rà fún àìsí omi wọ́n sì kú fún òǹgbẹ.
- Isaiah 50:3nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Èmi fi òkùnkùn bo sánmọ̀ mo sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ ṣe ìbòrí rẹ̀.”
- Isaiah 50:4nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Olúwa Olódùmarè ti fún mi ni ahọ́n tí a fi iṣẹ́ rán, láti mọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lè gbé àwọn aláàárẹ̀ ró. O jí mi láràárọ̀, o jí etí mi láti gbọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí à ń kọ́.
- Isaiah 50:5nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Olúwa Olódùmarè ti ṣí mi ní etí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ṣọ̀tẹ̀ rí; Èmi kò sì padà sẹ́yìn.
- Isaiah 50:6nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Mo ṣí ẹ̀yìn mi sílẹ̀ fún àwọn tí ó ń nà mí, àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ mi fún àwọn tí ń fa irùngbọ̀n mi; Èmi kò fi ojú mi pamọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́yà àti ìyọṣùtì sí.
- Isaiah 50:7nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Nítorí Olúwa Olódùmarè ràn mí lọ́wọ́, a kì yóò dójútì mí. Nítorí náà ni mo ṣe gbé ojú mi ró bí òkúta akọ èmi sì mọ pé, ojú kò ní tì mí.
- Isaiah 50:8nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ẹni tí ó dá mi láre wà nítòsí. Ta ni ẹni náà tí yóò fẹ̀sùn kàn mí? Jẹ́ kí a kojú ara wa! Ta ni olùfisùn mi? Jẹ́ kí ó kò mí lójú!
- Isaiah 50:9nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Olúwa Olódùmarè ni ó ń ràn mí lọ́wọ́. Ta ni ẹni náà tí yóò dá mi lẹ́bi? Gbogbo wọn yóò gbó bí aṣọ; kòkòrò ni yóò sì jẹ wọn run.
- Isaiah 50:10nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ta ni nínú yín tí ó bẹ̀rù Olúwa tí ó sì ń gbọ́rọ̀ sí ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nu? Jẹ́ kí ẹni tí ń rìn ní òkùnkùn tí kò ní ìmọ́lẹ̀, kí ó gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwa kí o sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run rẹ̀.
- Isaiah 50:11nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí, gbogbo ẹ̀yin ti ń tanná tí ẹ sì ń fi pèsè iná ìléwọ́ fún ara yín, ẹ lọ, kí ẹ sì máa rìn nínú ìmọ́lẹ̀ iná yín, àti nínú ẹta iná tí ẹ ti dá. Èyí ni yóò jẹ́ tiyín láti ọwọ́ mi wá. Ẹ̀yin ó dùbúlẹ̀ nínú ìrora.
- Isaiah 51:1nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
“Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin tí ó ń lépa òdodo àti ẹ̀yin tí ń wá Olúwa. Wo àpáta, nínú èyí tí a ti gé yín jáde àti ihò òkúta níbi tí a ti gbẹ́ yín jáde;
- Isaiah 51:2nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
ẹ wo Abrahamu baba yín, àti Sara, ẹni tó bí i yín. Nígbà tí mo pè é, òun nìkan ni, Èmi sì bùkún un, mo sì ṣọ́ ọ di ọ̀pọ̀lọpọ̀.
- Isaiah 51:3nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Dájúdájú, Olúwa yóò tu Sioni nínú yóò sì bojú àánú wo gbogbo ahoro rẹ̀; Òun yóò sọ gbogbo aṣálẹ̀ rẹ̀ di Edeni, àti aṣálẹ̀ rẹ̀ yóò rí bí ọgbà Olúwa. Ayọ̀ àti inú dídùn ni a ó rí nínú rẹ̀, ọpẹ́ àti ariwo orín kíkọ.
- Isaiah 51:4nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
“Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin ènìyàn mi; gbọ́ tèmi, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè mi. Òfin yóò ti ọ̀dọ̀ mi jáde wá; ìdájọ́ mi yóò di ìmọ́lẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè.
- Isaiah 51:5nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Òdodo mi ń bọ̀ wá kíkankíkan, ìgbàlà mi ń bọ̀ lójú ọ̀nà, àti apá mi yóò sì mú ìdájọ́ wá sí àwọn orílẹ̀-èdè. Àwọn erékùṣù yóò wò mí wọn yóò sì dúró ní ìrètí fún apá mi.
- Isaiah 51:6nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Gbé ojú rẹ sókè sí àwọn ọ̀run, wo ilẹ̀ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀; àwọn ọ̀run yóò pòórá bí èéfín, ilẹ̀ yóò sì gbó bí ẹ̀wù àwọn olùgbé inú rẹ̀ yóò kú gẹ́gẹ́ bí àwọn eṣinṣin. Ṣùgbọ́n ìgbàlà mi yóò wà títí láé, òdodo mi kì yóò yẹ̀ láé.