Fò sí àkóónú

circa 800–400 BC

The Hebrew Prophets

God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.

3,706 ẹsẹ · 14 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Isaiah 51:7nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    “Ẹ gbọ́ mi, ẹ̀yin tí ó mọ ohun òtítọ́, ẹ̀yin ènìyàn tí ó ní òfin mi ní àyà yín. Ẹ má ṣe bẹ̀rù ẹ̀gàn àwọn ènìyàn tàbí kí ẹ̀rù èébú wọn já a yín láyà.

  2. Isaiah 51:8nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Nítorí kòkòrò yóò mú wọn lá bí aṣọ, ìdin yóò sì mú wọn jẹ bí ẹ̀gbọ̀n òwú. Ṣùgbọ́n òdodo mi yóò wà títí ayérayé, àti ìgbàlà mi láti ìrandíran.”

  3. Isaiah 51:9nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Dìde, dìde! Kí o sì wọ ara rẹ ní agbára ìwọ apá Olúwa; dìde gẹ́gẹ́ bí i ti ọjọ́ ìgbà n nì, àti gẹ́gẹ́ bí i ti ìran àtijọ́. Ìwọ kọ́ lo ké Rahabu sí wẹ́wẹ́ tí o sì fa ẹ̀mí búburú ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ?

  4. Isaiah 51:10nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Ìwọ kọ́ ni ó gbẹ omi Òkun bí àti àwọn omi inú ọ̀gbun, tí o sì ṣe ọ̀nà nínú ìsàlẹ̀ Òkun tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ẹni ìràpadà yóò fi le là á kọjá?

  5. Isaiah 51:11nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Àwọn ẹni ìràpadà Olúwa yóò padà wá. Wọn yóò wọ Sioni wá pẹ̀lú orin kíkọ; ayọ̀ ayérayé ni yóò sì bo orí wọn. Ayọ̀ àti inú dídùn yóò sì bà lé wọn ìbànújẹ́ àti ìtìjú yóò sì sá kúrò.

  6. Isaiah 51:12nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    “Èmi, àní Èmi, èmi ni ẹni tí ó tù ọ́ nínú. Ta ni ọ́ tí o fi ń bẹ̀rù ènìyàn ẹlẹ́ran ara, àti ọmọ ènìyàn, tí ó jẹ́ koríko lásán,

  7. Isaiah 51:13nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    tí ìwọ sì gbàgbé Olúwa ẹlẹ́dàá rẹ, ẹni tí ó ta àwọn ọ̀run tí ó sì fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, tí ẹ sì ń gbé nínú ìpayà lójoojúmọ́ nítorí ìbínú àwọn aninilára, tí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀lé ìpanirun? Nítorí ibo ni ìbínú àwọn aninilára gbé wà?

  8. Isaiah 51:14nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí ń ṣojo la ó dá sílẹ̀ ní àìpẹ́ jọjọ wọn kò ní kú sínú túbú wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ṣe aláìní àkàrà.

  9. Isaiah 51:15nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ó ń ru Òkun sókè tó bẹ́ẹ̀ tí ìgbì rẹ̀ fi ń pariwo Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.

  10. Isaiah 51:16nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ẹnu rẹ mo sì ti fi òjìji ọwọ́ mi bò ọ́, Èmi tí mo tẹ́ àwọn ọ̀run sí ààyè rẹ̀, ẹni tí ó fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé lélẹ̀, àti ẹni tí ó sọ fún Sioni pé, ‘Ẹ̀yin ni ènìyàn mi.’ ”

  11. Isaiah 51:17nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Jí, jí! Gbéra nílẹ̀ ìwọ Jerusalẹmu, ìwọ tí o ti mu láti ọwọ́ Olúwa ago ìbínú rẹ̀, ìwọ tí o ti fà á mu dé gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ tí ó n mú kí ènìyàn ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n.

  12. Isaiah 51:18nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Nínú gbogbo ọmọ tí ó bí kò sí ọ̀kankan tí ó lè tọ́ ọ ṣọ́nà nínú gbogbo ọmọ tí ó tọ́ kò sí èyí tí ó le fà á lọ́wọ́.

  13. Isaiah 51:19nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Àjálù ìlọ́po ìlọ́po yìí ti dé bá ọ— ta ni yóò tù ọ́ nínú? Ìparun àti ìdahoro, ìyàn àti idà ta ni yó pẹ̀tù sí ọ lọ́kàn?

  14. Isaiah 51:20nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọkùnrin rẹ ti dákú; wọ́n sùn sí oríta gbogbo òpópónà, gẹ́gẹ́ bí etu tí a dé mọ́nú àwọ̀n. Ìbínú Olúwa ti kún inú wọn fọ́fọ́ àti ìbáwí Ọlọ́run yín.

  15. Isaiah 51:21nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí a ti ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́, tí ọtí ń pa, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún wáìnì.

  16. Isaiah 51:22nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Ohun tí Olúwa Olódùmarè yín wí nìyìí, Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó ń pa ènìyàn rẹ̀ mọ́, “Kíyèsi i, mo ti mú un kúrò ní ọwọ́ rẹ ago tí ó mú ọ ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n; láti inú ago náà, ẹ̀kún ìbínú mi, ni ìwọ kì yóò mu mọ́.

  17. Isaiah 51:23nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò fi lé àwọn apọ́nilójú rẹ lọ́wọ́, àwọn tí ó wí fún ọ pé, ‘Dọ̀bálẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí a ó fi máa rìn lórí rẹ.’ Ìwọ náà ṣe ẹ̀yìn rẹ gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òpópónà láti máa rìn lórí i rẹ̀.”

  18. Isaiah 52:1nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Jí, jí, ìwọ Sioni, wọ ara rẹ ní agbára. Gbé aṣọ ògo rẹ wọ̀, ìwọ Jerusalẹmu, ìlú mímọ́ n nì. Àwọn aláìkọlà àti aláìmọ́ kì yóò wọ inú rẹ mọ́.

  19. Isaiah 52:2nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Gbọn eruku rẹ kúrò; dìde sókè, kí o sì gúnwà, ìwọ Jerusalẹmu. Bọ́ ẹ̀wọ̀n tí ń bẹ lọ́rùn rẹ kúrò, ìwọ ọ̀dọ́mọbìnrin ìgbèkùn Sioni.

  20. Isaiah 52:3nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí, “Ọ̀fẹ́ ni a tà ọ́, láìsanwó ni a ó sì rà ọ́ padà.”

  21. Isaiah 52:4nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí. “Ní ìgbà àkọ́kọ́ àwọn ènìyàn mi sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti láti gbé; láìpẹ́ ni Asiria pọ́n wọn lójú.

  22. Isaiah 52:5nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    “Àti ní àkókò yìí, kí ni mo ní níbí?” ni Olúwa wí. “Nítorí a ti kó àwọn ènìyàn mi lọ lọ́fẹ̀ẹ́, àwọn tí ó sì ń jẹ ọba lórí wọn fi wọ́n ṣẹlẹ́yà,” ni Olúwa wí. “Àti ní ọjọọjọ́ orúkọ mi ni asọ̀rọ̀-òdì sí nígbà gbogbo.

  23. Isaiah 52:6nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóò mọ orúkọ mi; nítorí ní ọjọ́ náà, wọn yóò mọ̀ pé, Èmi ni ó ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, Èmi ni.”

  24. Isaiah 52:7nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Báwo ni ó ṣe dára tó lórí òkè ẹsẹ̀ àwọn tí ó mú ìyìnrere ayọ̀ wá, tí wọ́n kéde àlàáfíà, tí ó mú ìyìnrere wá, tí ó kéde ìgbàlà, tí ó sọ fún Sioni pé, “Ọlọ́run rẹ ń jẹ ọba!”

  25. Isaiah 52:8nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Tẹ́tí sílẹ̀! Àwọn olùṣọ́ rẹ gbé ohùn wọn sókè wọ́n kígbe papọ̀ fún ayọ̀. Nígbà tí Olúwa padà sí Sioni, wọn yóò rí i pẹ̀lú ojú u wọn.