circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Isaiah 52:9nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ẹ bú sí orin ayọ̀ papọ̀, ẹ̀yin ahoro Jerusalẹmu, nítorí Olúwa ti tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú, ó sì ti ra Jerusalẹmu padà.
- Isaiah 52:10nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Olúwa yóò ṣí apá mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀ ní ojú gbogbo orílẹ̀-èdè, àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò rí ìgbàlà Ọlọ́run wa.
- Isaiah 52:11nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ẹ túká, ẹ túká, ẹ jáde kúrò níhìn-ín yìí! Ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kan! Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀ kí ẹ sì di mímọ́, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ohun èlò Olúwa.
- Isaiah 52:12nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò yára kúrò tàbí kí ẹ sáré lọ; nítorí Olúwa ni yóò síwájú yín lọ, Ọlọ́run Israẹli ni yóò sì ṣe ààbò lẹ́yìn ín yín.
- Isaiah 52:13nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Kíyèsi i, ìránṣẹ́ mi yóò hùwà ọlọ́gbọ́n; òun ni a ó gbé sókè tí a ó sì gbéga a ó sì gbé e lékè gidigidi.
- Isaiah 52:14nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Gẹ́gẹ́ bí a ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n ń bu ọlá fún un— ìwò ojú rẹ ni a ti bàjẹ́ kọjá ti ẹnikẹ́ni àti ìrísí rẹ̀ ní a ti bàjẹ́ kọjá ohun tí ènìyàn ń fẹ́.
- Isaiah 52:15nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe bomirin àwọn orílẹ̀-èdè ká, àwọn ọba yóò sì pa ẹnu wọn mọ́ nítorí rẹ̀. Nítorí ohun tí a kò sọ fún wọn, wọn yóò rí i, àti ohun tí wọn kò tí ì gbọ́, ni yóò sì yé wọn.
- Isaiah 53:1nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ta ni ó ti gba ìròyìn in wa gbọ́ àti ta ni a ti fi apá Olúwa hàn fún?
- Isaiah 53:2nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Òun dàgbàsókè níwájú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ irúgbìn, àti gẹ́gẹ́ bí i gbòǹgbò tí ó jáde láti inú ìyàngbẹ ilẹ̀. Òun kò ní ẹwà tàbí ògo láti fà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, kò sí ohun kankan nínú àbùdá rẹ̀ tí ó fi yẹ kí a ṣàfẹ́rí i rẹ̀.
- Isaiah 53:3nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
A kẹ́gàn rẹ̀ àwọn ènìyàn sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀, ẹni ìbànújẹ́, tí ó sì mọ bí ìpọ́njú ti rí. Gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan tí àwọn ènìyàn ń fojú pamọ́ fún a kẹ́gàn rẹ, a kò sì bu ọlá fún un rárá.
- Isaiah 53:4nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Lóòtítọ́ ó ti ru àìlera wa lọ ó sì ti ru ìbànújẹ́ wa pẹ̀lú, síbẹ̀ a kà á sí ẹni tí Ọlọ́run lù, tí ó lù, tí a sì pọ́n lójú.
- Isaiah 53:5nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n a sá a lọ́gbẹ́ nítorí àìṣedéédéé wa a pa á lára nítorí àìṣòdodo wa; ìjìyà tí ó mú àlàáfíà wá fún wa wà lórí i rẹ̀, àti nípa ọgbẹ́ rẹ̀ ni a fi mú wa láradá.
- Isaiah 53:6nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Gbogbo wa bí àgùntàn, ti ṣìnà lọ, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ti yà sí ọ̀nà ara rẹ̀; Olúwa sì ti gbé e ka orí ara rẹ̀ gbogbo àìṣedéédéé wa.
- Isaiah 53:7nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
A jẹ ẹ́ ní yà, a sì pọ́n ọn lójú, síbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀; a mú un wá gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́-àgùntàn sọ́dọ̀ alápatà, àti gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí ó dákẹ́ níwájú olùrẹ́run rẹ̀, síbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀.
- Isaiah 53:8nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Pẹ̀lú ìpọ́nlójú àti ìdánilẹ́jọ́ ni a mú un jáde lọ, ta ni ó sì le sọ nípa ìrànlọ́wọ́ rẹ̀? Nítorí a ké e kúrò ní ilẹ̀ àwọn alààyè; nítorí àìṣedéédéé àwọn ènìyàn mi ni a ṣe lù ú.
- Isaiah 53:9nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
A fún un ní ibojì pẹ̀lú àwọn ìkà, àti pẹ̀lú àwọn ọlọ́rọ̀ ní ikú rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò hùwà jàgídíjàgan kan, tàbí kí a rí ẹ̀tàn kan ní ẹnu rẹ̀.
- Isaiah 53:10nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Síbẹ̀, ó wu Olúwa láti pa á lára àti láti mú kí ó jìyà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa fi ayé rẹ̀ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, Òun yóò rí àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ àti ọjọ́ ayé rẹ̀ yóò pẹ́ títí, àti ète Olúwa ni yóò gbèrú ní ọwọ́ rẹ̀.
- Isaiah 53:11nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Lẹ́yìn ìpọ́njú ẹ̀mí rẹ̀, òun yóò rí ìmọ́lẹ̀, ààyè yóò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn; nípa ìmọ̀ rẹ̀ ìránṣẹ́ mi olódodo yóò dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ láre, Òun ni yóò sì ru àìṣedéédéé wọn.
- Isaiah 53:12nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Nítorí náà èmi yóò fún un ní ìpín pẹ̀lú àwọn ẹni ńlá òun yóò sì pín ìkógun pẹ̀lú àwọn alágbára, nítorí pé òun jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ fún ikú, tí a sì kà á mọ́ àwọn alárékọjá. Nítorí ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀, ó sì ṣe ìlàjà fún àwọn alárékọjá.
- Isaiah 54:1nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
“Kọrin, ìwọ obìnrin àgàn, ìwọ tí kò tí ì bímọ rí; bú sí orin, ẹ hó fún ayọ̀, ẹ̀yin tí kò tí ì rọbí rí; nítorí pé púpọ̀ ni ọmọ àwọn obìnrin ìsọdahoro ju ti ẹni tí ó ní ọkọ,” ni Olúwa wí.
- Isaiah 54:2nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Fẹ ibi àgọ́ rẹ lójú sí i, fẹ aṣọ àgọ́ rẹ kí ó gbòòrò sí i, má ṣe dá a dúró; sọ okùn rẹ di gígùn, mú òpó rẹ lágbára sí i.
- Isaiah 54:3nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Nítorí ìwọ ó fẹ̀ sọ́tùn àti sí òsì; ìrandíran rẹ yóò jogún àwọn orílẹ̀-èdè, wọn yóò sì dó sí ahoro àwọn ìlú wọn.
- Isaiah 54:4nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
“Má ṣe bẹ̀rù, ìtìjú kò ní ṣubú lù ọ́. Má ṣe bẹ̀rù ìdójútì, a kì yóò kàn ọ́ lábùkù. Ìwọ yóò gbàgbé ìtìjú ìgbà èwe e rẹ, ìwọ kì yóò sì rántí ẹ̀gàn ìgba-opo rẹ mọ́.
- Isaiah 54:5nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Nítorí Ẹlẹ́dàá rẹ ni ọkọ rẹ Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀ Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà rẹ; a sì ń pè é ní Ọlọ́run gbogbo ayé.
- Isaiah 54:6nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Olúwa yóò pè ọ́ padà àfi bí ẹni pé obìnrin tí a kọ̀sílẹ̀ tí a sì bà lọ́kàn jẹ́ obìnrin tí a fẹ́ ní ọ̀dọ́, tí a sì wá jákulẹ̀,” ni Olúwa wí.