- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Isaiah 45:19nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Èmi kò sọ̀rọ̀ níbi tí ó fi ara sin, láti ibìkan ní ilẹ̀ òkùnkùn, Èmi kò tí ì sọ fún àwọn ìran Jakọbu pé, ‘Ẹ wá mi lórí asán.’ Èmi Olúwa sọ òtítọ́, Mo sì sọ èyí tí ó tọ̀nà.
- Isaiah 45:20nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
“Ẹ kó ara yín jọ kí ẹ sì wá; ẹ kórajọ, ẹ̀yin ìsáǹsá láti àwọn orílẹ̀-èdè wá. Aláìmọ̀kan ni àwọn tí ó ń ru ère igi káàkiri, tí wọ́n gbàdúrà sí àwọn òrìṣà tí kò le gba ni.
- Isaiah 45:21nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Jẹ́ kí a mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀, fihàn wá, jẹ́ kí wọn jọ dámọ̀ràn papọ̀. Ta ló ti sọ èyí lọ́jọ́ tí o ti pẹ́, ta ló ti wí èyí láti àtètèkọ́ṣe? Kì í ha á ṣe Èmi, Olúwa? Àti pé kò sí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi, Ọlọ́run olódodo àti olùgbàlà; kò sí ẹlòmíràn àfi èmi.
- Isaiah 45:22nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
“Yípadà sí mi kí a sì gbà ọ́ là, ẹ̀yin ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé; nítorí Èmi ni Ọlọ́run kò sì ṣí ẹlòmíràn.
- Isaiah 45:23nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Nípa èmi tìkára mi ni mo ti búra, ẹnu mi ni ó ti sọ ọ́ pẹ̀lú gbogbo ipá mi, ọ̀rọ̀ náà tí a kì yóò lè parẹ́. Níwájú mi ni gbogbo orúnkún yóò wólẹ̀; nípa mi ni gbogbo ahọ́n yóò búra.
- Isaiah 45:24nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Wọn yóò sọ ní ti èmi, ‘Nínú Olúwa nìkan ni òdodo àti agbára wà.’ ” Gbogbo àwọn tí ó ti bínú sí; yóò wá sọ́dọ̀ rẹ̀ a ó sì dójútì wọn.
- Isaiah 45:25nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n nínú Olúwa gbogbo àwọn ìran Israẹli ni a ó rí ní òdodo, a o sì gbé wọn ga.
- Isaiah 46:1nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Beli tẹrí i rẹ̀ ba, Nebo bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀; àwọn ère wọn ni àwọn ẹranko rù. Àwọn ère tí wọ́n ń rù káàkiri ti di àjàgà sí wọn lọ́rùn, ẹrù fún àwọn tí àárẹ̀ mú.
- Isaiah 46:2nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Wọ́n bẹ̀rẹ̀ wọ́n sì foríbalẹ̀ papọ̀; wọn kò lè gba ẹrù náà, àwọn pẹ̀lú ni a kó lọ ní ìgbèkùn.
- Isaiah 46:3nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
“Tẹ́tí sí mi, ìwọ ilé Jakọbu, gbogbo ẹ̀yin tí ó ṣẹ́kù nínú ilé Israẹli, ìwọ tí mo ti gbéró láti ìgbà tí o ti wà nínú oyún, tí mo sì ti ń pọ̀n láti ìgbà tí a ti bí ọ.
- Isaiah 46:4nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Pẹ̀lúpẹ̀lú sí àwọn arúgbó àti ewú orí yín, Èmi ni ẹni náà, Èmi ni ẹni tí yóò gbé ọ ró. Èmi ti mọ ọ́, èmi yóò sì gbé ọ; Èmi yóò dì ọ́ mú èmi ó sì gbà ọ́ sílẹ̀.
- Isaiah 46:5nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
“Ta ni ìwọ yóò fi mí wé tàbí ta ni èmi yóò bá dọ́gba? Ta ni ìwọ yóò fi ṣe àkàwé mi tí àwa yóò jọ fi ara wé ara?
- Isaiah 46:6nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ọ̀pọ̀ da wúrà sílẹ̀ nínú àpò wọn wọ́n sì wọn fàdákà lórí òsùwọ̀n; wọ́n bẹ alágbẹ̀dẹ lọ́wẹ̀ láti fi wọ́n ṣe òrìṣà, wọn sì tẹríba láti sìn ín.
- Isaiah 46:7nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Wọ́n gbé e lé èjìká wọn, wọ́n rù wọ́n, wọ́n sì gbé e sí ààyè rẹ̀ níbẹ̀ ni ó sì dúró sí. Láti ibẹ̀ náà kò le è paradà. Bí ènìyàn tilẹ̀ pariwo lé e lórí, òun kò le è dáhùn; òun kò lè gbà á nínú ìyọnu rẹ̀.
- Isaiah 46:8nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
“Rántí èyí, fi í sí ọkàn rẹ, fi sí ọkàn rẹ, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀.
- Isaiah 46:9nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Rántí àwọn nǹkan àtẹ̀yìnwá, àwọn ti àtijọ́-tijọ́; Èmi ni Ọlọ́run, kò sì sí ẹlòmíràn; Èmi ni Ọlọ́run, kò sí ẹlòmíràn bí ì mi.
- Isaiah 46:10nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Mo fi òpin hàn láti ìbẹ̀rẹ̀ wá, láti àtètèkọ́ṣe, ohun tí ó sì ń bọ̀ wá. Mo wí pé, Ète mi yóò dúró, àti pé èmi yóò ṣe ohun tí ó wù mí.
- Isaiah 46:11nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Láti ìlà-oòrùn wá ni mo ti pe ẹyẹ ajẹran wá; láti ọ̀nà jíjìn réré, ọkùnrin kan tí yóò mú ète mi ṣẹ. Ohun tí mo ti sọ, òun ni èmi yóò mú ṣẹ; èyí tí mo ti gbèrò, òun ni èmi yóò ṣe.
- Isaiah 46:12nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Gbọ́ tèmi, ẹ̀yin alágídí ọkàn, ìwọ tí ó jìnnà sí òdodo.
- Isaiah 46:13nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Èmi ń mú òdodo mi bọ̀ nítòsí, kò tilẹ̀ jìnnà rárá; àti ìgbàlà mi ni a kì yóò dádúró. Èmi yóò fún Sioni ní ìgbàlà ògo mi fún Israẹli.
- Isaiah 47:1nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
“Sọ̀kalẹ̀, jókòó nínú eruku, wúńdíá ọmọbìnrin Babeli; jókòó ní ilẹ̀ láìsí ìtẹ́, ọmọbìnrin àwọn ará Babeli. A kì yóò pè ọ́ ní aláìlókun àti ẹlẹgẹ́ mọ́.
- Isaiah 47:2nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Mú òkúta-ọlọ kí o sì lọ ìyẹ̀fun; mú ìbòjú rẹ kúrò. Ká aṣọ ẹsẹ̀ rẹ sókè, ká aṣọ itan, kí o sì la odò wọ̀n-ọn-nì kọjá.
- Isaiah 47:3nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ìhòhò rẹ ni a ó sí síta àti ìtìjú rẹ ni a ó ṣí sílẹ̀. Èmi yóò sì gba ẹ̀san, Èmi kì yóò sì dá ẹnìkan sí.”
- Isaiah 47:4nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Olùràpadà wa Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀ òun ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.
- Isaiah 47:5nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
“Jókòó ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, lọ sínú òkùnkùn, ọmọbìnrin àwọn ará Babeli; a kì yóò pè ọ́ ní ọbabìnrin àwọn ilẹ̀ ọba mọ́.