Fò sí àkóónú

circa 800–400 BC

The Hebrew Prophets

God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.

3,706 ẹsẹ · 14 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Isaiah 43:25nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    “Èmi, àní Èmi, Èmi ni ẹni tí ó wẹ àwọn àìṣedéédéé rẹ nù, nítorí èmi fún ara mi, tí n kò sì rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ mọ́.

  2. Isaiah 43:26nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Bojú wo ẹ̀yìn rẹ fún mi, jẹ́ kí a jọ ṣe àríyànjiyàn ọ̀rọ̀ náà papọ̀; ro ẹjọ́ láti fihàn pé o kò lẹ́sẹ̀ lọ́rùn.

  3. Isaiah 43:27nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Baba yín àkọ́kọ́ dẹ́ṣẹ̀; àwọn agbẹnusọ yín ṣọ̀tẹ̀ sí mi.

  4. Isaiah 43:28nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà, èmi ti sọ àwọn olórí ibi mímọ́ náà di àìmọ́, bẹ́ẹ̀ ni èmi ti fi Jakọbu fún ègún àti Israẹli fún ẹ̀gàn.

  5. Isaiah 44:1nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    “Ṣùgbọ́n gbọ́ nísinsin yìí, ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi, àti Israẹli, ẹni tí mo ti yàn.

  6. Isaiah 44:2nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Ohun tí Olúwa wí nìyìí ẹni tí ó dá ọ, ẹni tí ó ti mọ̀ ọ́n láti inú ìyá rẹ wá, àti ẹni tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ pẹ̀lú. Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu, ìránṣẹ́ mi, Jeṣuruni ẹni tí mo ti yàn.

  7. Isaiah 44:3nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Nítorí èmi yóò da omi sí ilẹ̀ tí ń pòǹgbẹ àti àwọn odò ní ilẹ̀ gbígbẹ, Èmi yóò tú Ẹ̀mí mi sí ara àwọn ọmọ rẹ, àti ìbùkún mi sórí àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ.

  8. Isaiah 44:4nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Wọn yóò dàgbàsókè gẹ́gẹ́ bí i koríko nínú pápá oko tútù, àti gẹ́gẹ́ bí igi Poplari létí odò tí ń sàn.

  9. Isaiah 44:5nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Ọ̀kan yóò wí pé, ‘Èmi jẹ́ ti Olúwa’; òmíràn yóò pe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orúkọ Jakọbu; bẹ́ẹ̀ ni òmíràn yóò kọ ọ́ sí ọwọ́ rẹ̀, ‘Ti Olúwa,’ yóò sì máa jẹ́ orúkọ náà Israẹli.

  10. Isaiah 44:6nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    “Ohun tí Olúwa wí nìyìí ọba Israẹli àti Olùdáǹdè, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn, lẹ́yìn mi kò sí Ọlọ́run kan.

  11. Isaiah 44:7nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Ta ni ó dàbí ì mi? Jẹ́ kí o kéde rẹ̀. Jẹ́ kí ó wí kí ó sì gbé síwájú mi kí ni ó ti ṣẹlẹ̀ láti ìgbà tí mo fi ìdí àwọn ènìyàn ìṣẹ̀ǹbáyé kalẹ̀, àti kí ni ohun tí ń sì ń bọ̀, bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí ń bọ̀ wá.

  12. Isaiah 44:8nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Má ṣe wárìrì, má ṣe bẹ̀rù. Ǹjẹ́ èmi kò ti kéde èyí tí mo sì ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ tipẹ́tipẹ́? Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi. Ǹjẹ́ Ọlọ́run kan ha ń bẹ lẹ́yìn mi? Bẹ́ẹ̀ kọ́, kò sí àpáta mìíràn; Èmi kò mọ ọ̀kankan.”

  13. Isaiah 44:9nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Gbogbo àwọn tí ń gbẹ́ ère jásí asán, àti àwọn ohun tí wọn ń kó pamọ́ kò jámọ́ nǹkan kan. Àwọn tí yóò sọ̀rọ̀ fún wọn fọ́ lójú; wọ́n jẹ́ aláìmọ̀kan sí ìtìjú ara wọn.

  14. Isaiah 44:10nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Ta ni ó mọ òrìṣà kan tí ó sì ya ère, tí kò lè mú èrè kankan wá fún un?

  15. Isaiah 44:11nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Òun àti nǹkan rẹ̀ wọ̀nyí ni a ó dójútì; àwọn oníṣọ̀nà kò yàtọ̀, ènìyàn ni wọ́n. Jẹ́ kí gbogbo wọn gbárajọ kí wọ́n sì fi ìdúró wọn hàn; gbogbo wọn ni a ó mú bọ́ sínú ìpayà àti àbùkù.

  16. Isaiah 44:12nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Alágbẹ̀dẹ mú ohun èlò, ó fi ń ṣiṣẹ́ nínú èédú; ó fi òòlù ya ère kan, ó ṣe é pẹ̀lú agbára apá rẹ̀, ebi ń pa á, àárẹ̀ sì mú un; kò mu omi rárá, ìrẹ̀wẹ̀sì dé bá a.

  17. Isaiah 44:13nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Gbẹ́nàgbẹ́nà fi ìwọ̀n wọ́n ọ́n ó sì fi lẹ́ẹ̀dì ṣe àmì sí ara rẹ̀, Ó tún fi ìfà fá a jáde ó tún fi òsùwọ̀n ṣe àmì sí i. Ó gbẹ́ ẹ ní ìrí ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ènìyàn nínú ògo rẹ̀, kí ó lè máa gbé nínú ilé òrìṣà.

  18. Isaiah 44:14nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Ó gé igi kedari lulẹ̀, tàbí bóyá ó mú sípírẹ́ṣì tàbí igi óákù. Ó jẹ́ kí ó dàgbà láàrín àwọn igi inú igbó, ó sì le gbin igi páínì, èyí tí òjò mú kí ó dàgbà.

  19. Isaiah 44:15nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Ohun èlò ìdáná ni fún ènìyàn; díẹ̀ nínú rẹ̀ ni ó mú láti mú kí ara rẹ̀ lọ́wọ́ọ́rọ́, ó dá iná ó sì fi ṣe àkàrà. Ṣùgbọ́n bákan náà ni ó ṣe òrìṣà tí ó sì ń sìn ín; ó yá ère, ó sì ń foríbalẹ̀ fún un.

  20. Isaiah 44:16nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Ìlàjì igi náà ni ó jó nínú iná; lórí i rẹ̀ ni ó ti ń tọ́jú oúnjẹ rẹ̀, ó dín ẹran rẹ̀ ó sì jẹ àjẹyó. Ó tún mú ara rẹ̀ gbóná ó sì sọ pé, “Á à! Ara mi gbóná, mo rí iná.”

  21. Isaiah 44:17nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Nínú èyí tí ó kù ni ó ti ṣe òrìṣà, ère rẹ̀; ó foríbalẹ̀ fún un, ó sì sìn ín. Ó gbàdúrà sí i, ó wí pé, “Gbà mí, ìwọ ni Ọlọ́run mi.”

  22. Isaiah 44:18nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Wọn kò mọ nǹkan kan, nǹkan kan kò yé wọn; a fi ìbòjú bo ojú wọn, wọn kò lè rí nǹkan kan; bẹ́ẹ̀ ni àyà wọn sébọ́, wọn kò lè mọ nǹkan kan.

  23. Isaiah 44:19nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Kò sí ẹni tí ó dúró láti ronú, kò sí ẹni tí ó ní ìmọ̀ tàbí òye láti sọ wí pé, “Ìlàjì rẹ̀ ni mo fi dáná; mo tilẹ̀ ṣe àkàrà lórí èédú rẹ̀, mo dín ẹran, mo sì jẹ ẹ́. Ǹjẹ́ ó wá yẹ kí n ṣe ohun ìríra kan nínú èyí tí ó ṣẹ́kù bí? Ǹjẹ́ èmi yóò ha foríbalẹ̀ fún ìtì igi?”

  24. Isaiah 44:20nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Ó ń jẹ eérú, ọkàn ẹlẹ́tàn ni ó ṣì í lọ́nà; òun kò lè gba ara rẹ̀ là, tàbí kí ó wí pé, “Ǹjẹ́ nǹkan tí ó wà lọ́wọ́ ọ̀tún mi yìí irọ́ kọ́?”

  25. Isaiah 44:21nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    “Rántí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ìwọ Jakọbu, nítorí ìránṣẹ́ mi ni ìwọ, ìwọ Israẹli. Èmi ti dá ọ, ìránṣẹ́ mi ni ìwọ ṣe, ìwọ Israẹli, Èmi kì yóò gbàgbé rẹ.