Fò sí àkóónú

circa 800–400 BC

The Hebrew Prophets

God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.

3,706 ẹsẹ · 14 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Isaiah 41:29nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Kíyèsi i, irọ́ ni gbogbo wọn! Gbogbo ìṣe wọn jásí asán; àwọn ère wọn kò ṣé kò yà fún afẹ́fẹ́ àti dàrúdàpọ̀.

  2. Isaiah 42:1nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    “Ìránṣẹ́ mi nìyìí, ẹni tí mo gbéró, àyànfẹ́ mi nínú ẹni tí mo láyọ̀; Èmi yóò fi Ẹ̀mí mi sínú rẹ̀ òun yóò sì mú ìdájọ́ wá sórí àwọn orílẹ̀-èdè.

  3. Isaiah 42:2nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Òun kì yóò pariwo tàbí kígbe sókè, tàbí kí ó gbóhùn rẹ̀ sókè ní òpópónà.

  4. Isaiah 42:3nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Koríko odò títẹ̀ kan ni òun kì yóò fọ́, àti òwú-fìtílà tí ń jó tan an lọ lòun kì yóò fẹ́ pa. Ní òdodo ni yóò mú ìdájọ́ wá;

  5. Isaiah 42:4nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    òun kì yóò kọsẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò ní rẹ̀wẹ̀sì títí tí yóò fi fi ìdájọ́ múlẹ̀ ní ayé. Nínú òfin rẹ̀ ni àwọn erékùṣù yóò fi ìrètí wọn sí.”

  6. Isaiah 42:5nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí Ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run tí ó sì tẹ́ wọ́n sóde, tí ó tẹ́ ilẹ̀ ayé àti ohun gbogbo tí ó jáde nínú wọn, Ẹni tí ó fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní èémí àti ẹ̀mí fún gbogbo àwọn tí ń rìn nínú rẹ̀:

  7. Isaiah 42:6nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    “Èmi, Olúwa, ti pè ọ́ ní òdodo, Èmi yóò di ọwọ́ rẹ mú. Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́ láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn àti ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà

  8. Isaiah 42:7nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    láti la àwọn ojú tí ó fọ́, láti tú àwọn òǹdè kúrò nínú túbú àti láti tú sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n àwọn tí ó jókòó nínú òkùnkùn.

  9. Isaiah 42:8nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    “Èmi ni Olúwa; orúkọ mi nìyìí! Èmi kì yóò fi ògo mi fún ẹlòmíràn tàbí ìyìn mi fún ère òrìṣà.

  10. Isaiah 42:9nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Kíyèsi i, àwọn nǹkan àtijọ́ ti wáyé, àti àwọn nǹkan tuntun ni mo ti wí pé; kí wọn tó hù jáde mo ti kéde rẹ̀ fún ọ.”

  11. Isaiah 42:10nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Kọ orin tuntun sí Olúwa ìyìn rẹ̀ láti òpin ilẹ̀ ayé wá, ẹ̀yin tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú Òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀, ẹ̀yin erékùṣù, àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú wọn.

  12. Isaiah 42:11nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Jẹ́ kí aginjù àti àwọn ìlú rẹ̀ kí ó gbé ohùn wọn sókè; jẹ́ kí ibùdó ti àwọn ìlú Kedari ń gbé máa yọ̀. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn Sela kọrin fún ayọ̀; jẹ́ kí wọn pariwo láti orí òkè.

  13. Isaiah 42:12nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Jẹ́ kí wọn fi ògo fún Olúwa àti kí wọn sì kéde ìyìn rẹ̀ ní erékùṣù.

  14. Isaiah 42:13nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Olúwa yóò rìn jáde gẹ́gẹ́ bí i ọkùnrin alágbára, yóò ru owú sókè bí ológun; yóò kígbe nítòótọ́, òun yóò ké igbe ogun, òun yóò sì ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀.

  15. Isaiah 42:14nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    “Fún ìgbà pípẹ́ ni mo ti dákẹ́ jẹ́ẹ́, mo ti wà ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, mo sì kó ara ró. Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí, gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó ń rọbí, mo sọkún, mo sì ń mí hẹlẹ hẹlẹ.

  16. Isaiah 42:15nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò sọ òkè ńlá àti kékeré di ahoro tí n ó sì gbẹ gbogbo ewéko rẹ̀ dànù, Èmi yóò sọ àwọn odò di erékùṣù n ó sì gbẹ àwọn adágún.

  17. Isaiah 42:16nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò tọ àwọn afọ́jú ní ọ̀nà tí wọn kò tí ì mọ̀, ní ipa ọ̀nà tí ó ṣàjèjì sí wọn ni èmi yóò tọ́ wọn lọ; Èmi yóò sọ òkùnkùn di ìmọ́lẹ̀ níwájú wọn àti ibi pálapàla ni èmi ó sọ di kíkúnná. Àwọn nǹkan tí máa ṣe nìyìí; Èmi kì yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀.

  18. Isaiah 42:17nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé òrìṣà, tí wọ́n wí fún ère pé, ‘Ẹ̀yin ni Ọlọ́run wa,’ ni a ó dá padà pẹ̀lú ìtìjú.

  19. Isaiah 42:18nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    “Gbọ́, ìwọ adití, wò ó, ìwọ afọ́jú, o sì rí!

  20. Isaiah 42:19nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Ta ló fọ́jú bí kò ṣe ìránṣẹ́ mi, àti odi gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ tí mo rán? Ta ni ó fọ́jú gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a fi jìnmí, ó fọ́jú gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Olúwa?

  21. Isaiah 42:20nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Ẹ̀yin ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan, ṣùgbọ́n ẹ kò ṣe àkíyèsí; etí yín yà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ kò gbọ́ nǹkan kan.”

  22. Isaiah 42:21nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Ó dùn mọ́ Olúwa nítorí òdodo rẹ̀ láti mú òfin rẹ lágbára àti ògo.

  23. Isaiah 42:22nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn kan nìyìí tí a jà lógun tí a sì kó lẹ́rú, gbogbo wọn ni ó wà nínú ọ̀gbun, tàbí tí a fi pamọ́ sínú ẹ̀wọ̀n. Wọ́n ti di ìkógun, láìsí ẹnìkan tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀; wọ́n ti di ìkógun, láìsí ẹni tí yóò sọ pé, “Dá wọn padà.”

  24. Isaiah 42:23nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Ta ni nínú yín tí yóò tẹ́tí sí èyí tàbí kí ó ṣe àkíyèsí gidi ní àsìkò tí ó ń bọ̀?

  25. Isaiah 42:24nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Ta ni ó fi Jakọbu lélẹ̀ fún ìkógun, àti Israẹli sílẹ̀ fún onísùnmọ̀mí? Kì í ha ṣe Olúwa ni, ẹni tí àwa ti ṣẹ̀ sí? Nítorí pé wọn kò ní tẹ̀lé ọ̀nà rẹ̀; wọn kò mú òfin rẹ̀ ṣẹ.