Fò sí àkóónú

circa AD 30–62

The Early Church

Pentecost ignites a movement; Peter, Paul, and countless others carry the gospel from Jerusalem to the ends of the earth.

1,007 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Ìṣe àwọn Aposteli 4:2nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Inú bí wọn, nítorí tí wọn kọ́ àwọn ènìyàn, wọ́n sì ń wàásù àjíǹde kúrò nínú òkú nínú Jesu.

  2. Ìṣe àwọn Aposteli 4:3nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Wọn sì nawọ́ mú wọn, wọn sì tì wọ́n mọ́ ilé túbú títí ó fi dí ọjọ́ kejì; nítorí tí alẹ́ ti lẹ́ tan.

  3. Ìṣe àwọn Aposteli 4:4nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà gbàgbọ́; iye àwọn ọkùnrin náà sì tó ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000).

  4. Ìṣe àwọn Aposteli 4:5nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì ṣe ní ọjọ́ kejì, àwọn olórí wọn àti àwọn alàgbà àti àwọn olùkọ́ni ní òfin péjọ sí Jerusalẹmu.

  5. Ìṣe àwọn Aposteli 4:6nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Àti Annasi olórí àlùfáà, àti Kaiafa, àti Johanu, àti Aleksanderu, àti iye àwọn tí i ṣe ìbátan olórí àlùfáà.

  6. Ìṣe àwọn Aposteli 4:7nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n mú Peteru àti Johanu dúró níwájú wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Nípa agbára tàbí orúkọ wo ni ẹ̀yin fi ṣe èyí?”

  7. Ìṣe àwọn Aposteli 4:8nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà ni Peteru kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin olórí àti ẹ̀yin alàgbà àwọn ènìyàn!

  8. Ìṣe àwọn Aposteli 4:9nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Bí ó bá ṣe pé a ń wádìí wa lónìí ní tí iṣẹ́ rere ti a ṣe lára abirùn náà, bí a ti ṣe mú ọkùnrin yìí láradá,

  9. Ìṣe àwọn Aposteli 4:10nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    kí èyí yé gbogbo yín àti gbogbo ènìyàn Israẹli pé, ni orúkọ Jesu Kristi ti Nasareti, tí ẹ̀yin kàn mọ́ àgbélébùú, tí Ọlọ́run jí dìde kúrò nínú òkú, nípa rẹ̀ ni ọkùnrin yìí fi dúró níwájú yín ni ara dídá-ṣáṣá.

  10. Ìṣe àwọn Aposteli 4:11nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Èyí ni “ ‘òkúta tí a ti ọwọ́ ẹ̀yin ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀, tí ó sì di pàtàkì igun ilé.’

  11. Ìṣe àwọn Aposteli 4:12nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Kò sì sí ìgbàlà lọ́dọ̀ ẹlòmíràn; nítorí kò sí orúkọ mìíràn lábẹ́ ọ̀run ti a fi fún ni nínú ènìyàn, nípa èyí tí a lè fi gbà wá là.”

  12. Ìṣe àwọn Aposteli 4:13nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọ́n sì kíyèsi ìgboyà Peteru àti Johanu, tí wọ́n mọ̀ pé, aláìkẹ́kọ̀ọ́ àti òpè ènìyàn ni wọn, ẹnu yà wọ́n, wọ́n sì wòye pé, wọ́n ti ń bá Jesu gbé.

  13. Ìṣe àwọn Aposteli 4:14nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọ́n sì ń wo ọkùnrin náà tí a mú láradá, tí ó bá wọn dúró, wọn kò rí nǹkan wí sí i.

  14. Ìṣe àwọn Aposteli 4:15nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n sì ti pàṣẹ pé kí wọn jáde kúrò ní ìgbìmọ̀, wọ́n bá ara wọn gbèrò.

  15. Ìṣe àwọn Aposteli 4:16nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Wí pé, “Kí ni a ó ṣe sí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí? Ní ti pé iṣẹ́ àmì tí ó dájú tí ọwọ́ wọn ṣe, ó hàn gbangba fún gbogbo àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu; àwa kò sì lè sẹ́ èyí.

  16. Ìṣe àwọn Aposteli 4:17nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n kí ó má ba à tànkálẹ̀ síwájú mọ́ láàrín àwọn ènìyàn, ẹ jẹ́ kí a kìlọ̀ fún wọn pé, láti ìsinsin yìí lọ kí wọn má ṣe fi orúkọ yìí sọ̀rọ̀ sí ẹnikẹ́ni mọ́.”

  17. Ìṣe àwọn Aposteli 4:18nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n sì pè wọ́n, wọ́n pàṣẹ fún wọn, kí wọn má ṣe sọ̀rọ̀ tàbí kọ́ni rárá mọ́ ní orúkọ Jesu.

  18. Ìṣe àwọn Aposteli 4:19nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n Peteru àti Johanu dáhùn, wọ́n sì wí fún wọn pé, “Bí ó bá tọ́ lójú Ọlọ́run láti gbọ́ tiyín ju ti Ọlọ́run lọ ẹ gbà á rò.

  19. Ìṣe àwọn Aposteli 4:20nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Àwa kò lè ṣàìmá sọ ohun tí àwa ń rí, tí a sì ti gbọ́.”

  20. Ìṣe àwọn Aposteli 4:21nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọ́n sì kìlọ̀ fún wọn sí i, wọn fi wọ́n sílẹ̀ lọ, nígbà tí wọn kò ì tí ì rí nǹkan tí wọn ìbá fi jẹ wọ́n ní ìyà, nítorí àwọn ènìyàn; nítorí gbogbo wọn ni wọ́n yin Ọlọ́run lógo fún ohun tí ó ṣe.

  21. Ìṣe àwọn Aposteli 4:22nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí ọkùnrin náà lára ẹni tí a ṣe iṣẹ́ àmì ìmúláradá, ju ẹni ogójì ọdún lọ.

  22. Ìṣe àwọn Aposteli 4:23nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọ́n sì ti fi wọ́n sílẹ̀ wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, wọ́n sì ròyìn ohun gbogbo tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn alàgbà sọ fún wọn.

  23. Ìṣe àwọn Aposteli 4:24nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n fi ọkàn kan gbé ohùn wọn sókè sí Ọlọ́run, wọ́n sì wí pé, “Olúwa Olódùmarè, ìwọ tí ó dá ọ̀run àti ayé, òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn.

  24. Ìṣe àwọn Aposteli 4:25nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ìwọ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó ti ẹnu Dafidi baba wa ìránṣẹ́ rẹ̀ wí pé: “ ‘E é ṣe tí àwọn kèfèrí fi ń bínú, àti tí àwọn ènìyàn ń gbèrò ohun asán?

  25. Ìṣe àwọn Aposteli 4:26nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn ọba ayé dìde, àti àwọn ìjòyè kó ara wọn jọ sí Olúwa, àti sí ẹni àmì òróró rẹ̀.’