Fò sí àkóónú

circa AD 30–62

The Early Church

Pentecost ignites a movement; Peter, Paul, and countless others carry the gospel from Jerusalem to the ends of the earth.

1,007 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Ìṣe àwọn Aposteli 2:25nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Dafidi tí wí nípa tirẹ̀ pé: “ ‘Mo rí Olúwa nígbà gbogbo níwájú mí, nítorí tí ó ń bẹ lọ́wọ́ ọ̀tún mi, a kì ó ṣí mi ní ipò.

  2. Ìṣe àwọn Aposteli 2:26nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà inú mi dùn, ahọ́n mi sì yọ̀, pẹ̀lúpẹ̀lú ara mi yóò sì sinmi ní ìrètí.

  3. Ìṣe àwọn Aposteli 2:27nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí tí ìwọ kí yóò fi ọkàn mi sílẹ̀ ni isà òkú, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kí yóò jẹ́ kí Ẹni Mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́.

  4. Ìṣe àwọn Aposteli 2:28nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ìwọ mú mi mọ ọ̀nà ìyè, ìwọ yóò mú mi kún fún ayọ̀ ni iwájú rẹ.’

  5. Ìṣe àwọn Aposteli 2:29nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Ará, èmí lè sọ fún yín pẹ̀lú ìgboyà pé Dafidi baba ńlá kú, a sì sin ín, ibojì rẹ̀ sì ń bẹ lọ́dọ̀ wa títí di òní yìí.

  6. Ìṣe àwọn Aposteli 2:30nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n ó jẹ́ wòlíì, àti bí ó mọ́ pé, Ọlọ́run ti ṣe ìlérí fún òun nínú ìbúra pé nínú irú-ọmọ inú rẹ̀, òun yóò mú ọ̀kan jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀.

  7. Ìṣe àwọn Aposteli 2:31nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ní rí rí èyí tẹ́lẹ̀, ó sọ ti àjíǹde Kristi, pé a kò fi ọkàn rẹ̀ sílẹ̀ ni isà òkú, bẹ́ẹ̀ ni ara rẹ̀ kò rí ìdíbàjẹ́.

  8. Ìṣe àwọn Aposteli 2:32nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Jesu náà yìí ni Ọlọ́run ti jí dìde sí ìyè, àwa pẹ̀lú sì jẹ́rìí sí èyí.

  9. Ìṣe àwọn Aposteli 2:33nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    A ti gbéga sí ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, ó ti gba ìlérí Ẹ̀mí Mímọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba, ó tu èyí tí ẹ̀yin rí àti gbọ́ nísinsin yìí síta.

  10. Ìṣe àwọn Aposteli 2:34nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí Dafidi kò gòkè lọ sí ọ̀run ṣùgbọ́n òun tìkára rẹ̀ wí pé, “ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé: “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi

  11. Ìṣe àwọn Aposteli 2:35nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ dí àpótí ìtìsẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ.” ’

  12. Ìṣe àwọn Aposteli 2:36nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Ǹjẹ́ kí gbogbo ilé Israẹli mọ̀ dájúdájú pé, Ọlọ́run ti fi Jesu náà, ti ẹ̀yin kàn mọ́ àgbélébùú, ṣe Olúwa àti Kristi.”

  13. Ìṣe àwọn Aposteli 2:37nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, ọkàn wọn gbọgbẹ́, wọn sì wí fún Peteru àti àwọn aposteli yòókù pé, “Ará, kín ni àwa yóò ṣe?”

  14. Ìṣe àwọn Aposteli 2:38nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Peteru sì wí fún wọn pé, “Ẹ ronúpìwàdà, kí a sì bamitiisi olúkúlùkù yín ní orúkọ Jesu Kristi fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ yín. Ẹ̀yin yóò sì gba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́.

  15. Ìṣe àwọn Aposteli 2:39nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí fún yín ni ìlérí náà, àti fún àwọn ọmọ yín, àti fún gbogbo àwọn tí ó jìnnà réré, àní gbogbo àwọn tí Olúwa Ọlọ́run wa yóò pè.”

  16. Ìṣe àwọn Aposteli 2:40nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ púpọ̀ mìíràn ni ó fi ń kìlọ̀ tí ó sì ń fi ń rọ̀ wọ́n wí pé, “Ẹ gba ara yín là lọ́wọ́ ìran àrékérekè yìí.”

  17. Ìṣe àwọn Aposteli 2:41nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà àwọn tí ó fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ a bamitiisi wọn, lọ́jọ́ náà a sì kà ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ọkàn kún wọn.

  18. Ìṣe àwọn Aposteli 2:42nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n sì dúró ṣinṣin nínú ẹ̀kọ́ àwọn aposteli, àti ní ìdàpọ̀, ní bíbu àkàrà àti nínú àdúrà.

  19. Ìṣe àwọn Aposteli 2:43nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ̀rù sí ba gbogbo ọkàn; iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ àmì púpọ̀ ni a ti ọwọ́ àwọn aposteli ṣe.

  20. Ìṣe àwọn Aposteli 2:44nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Gbogbo àwọn tí ó sì gbàgbọ́ wà ni ibìkan, wọn ní ohun gbogbo sọ́kàn;

  21. Ìṣe àwọn Aposteli 2:45nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Wọn si ń ta ohun ìní àti ẹrù wọn, wọn sì ń pín wọn fún olúkúlùkù, gẹ́gẹ́ bí ẹnikẹ́ni tí í ṣe aláìní sí.

  22. Ìṣe àwọn Aposteli 2:46nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n fi ọkàn kan dúró lójoojúmọ́ nínú tẹmpili. Wọ́n ń bu àkàrà ní ilé wọn, wọn ń fi inú dídùn àti ọkàn òtítọ́ jẹ oúnjẹ wọn.

  23. Ìṣe àwọn Aposteli 2:47nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n yín Ọlọ́run, wọn sì rí ojúrere lọ́dọ̀ ènìyàn gbogbo, Olúwa sí ń yàn kún wọn lójoojúmọ́, àwọn tí à ń gbàlà.

  24. Ìṣe àwọn Aposteli 3:1nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ní ọjọ́ kan Peteru àti Johanu jùmọ̀ ń gòkè lọ sí tẹmpili ní wákàtí àdúrà; tí í ṣe wákàtí mẹ́ta ọ̀sán.

  25. Ìṣe àwọn Aposteli 3:2nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Wọn sì gbé ọkùnrin kan ti ó yarọ láti inú ìyá rẹ̀ wá, tí wọ́n máa ń gbé kalẹ̀ lójoojúmọ́ ní ẹnu-ọ̀nà tẹmpili ti a ń pè ni Dáradára, láti máa ṣagbe lọ́wọ́ àwọn tí ń wọ inú tẹmpili lọ.