Fò sí àkóónú

circa AD 30–62

The Early Church

Pentecost ignites a movement; Peter, Paul, and countless others carry the gospel from Jerusalem to the ends of the earth.

1,007 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Ìṣe àwọn Aposteli 3:3nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ó rí Peteru àti Johanu bí wọn tí fẹ́ wọ inú tẹmpili, ó ṣagbe.

  2. Ìṣe àwọn Aposteli 3:4nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Peteru sì tẹjúmọ́ ọn, pẹ̀lú Johanu, ó ní “Wò wá!”

  3. Ìṣe àwọn Aposteli 3:5nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì fiyèsí wọn, ó ń retí láti rí nǹkan láti gbà lọ́wọ́ wọn.

  4. Ìṣe àwọn Aposteli 3:6nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Peteru wí pé, “Wúrà àti fàdákà èmi kò ní, ṣùgbọ́n ohun tí mo ní èyí náà ni mo fi fún ọ. Ní orúkọ Jesu Kristi ti Nasareti, dìde kí o sì máa rìn.”

  5. Ìṣe àwọn Aposteli 3:7nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì fà á lọ́wọ́ ọ̀tún, ó sì gbé dìde; lójúkan náà ẹsẹ̀ rẹ̀ àti egungun kókósẹ̀ rẹ̀ sì mókun.

  6. Ìṣe àwọn Aposteli 3:8nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì ń fò sókè, ó dúró, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn, ó sì bá wọn wọ inú tẹmpili lọ, ó ń rìn, ó sì ń fò, ó sì yín Ọlọ́run.

  7. Ìṣe àwọn Aposteli 3:9nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Gbogbo ènìyàn sì rí i, ó ń rìn, ó sì yin Ọlọ́run,

  8. Ìṣe àwọn Aposteli 3:10nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Wọn sì mọ̀ pé òun ni ó ti jókòó tí ń ṣagbe ní ẹnu-ọ̀nà Dáradára ti tẹmpili náà; hà, sì ṣe wọn, ẹnu sì yà wọn gidigidi sí ohun tí ó ṣe lára rẹ̀.

  9. Ìṣe àwọn Aposteli 3:11nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Bí arọ ti a mú láradá sì ti di Peteru àti Johanu mú, gbogbo ènìyàn jùmọ̀ súre tọ̀ wọ́n lọ ni ìloro ti a ń pè ní ti Solomoni, pẹ̀lú ìyàlẹ́nu ńlá.

  10. Ìṣe àwọn Aposteli 3:12nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí Peteru sì rí i, ó dáhùn, ó wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ̀yin ènìyàn Israẹli, èéṣe tí háà fi ń ṣe yín sí èyí? Tàbí èéṣe ti ẹ̀yin fi tẹjúmọ́ wa, bí ẹni pé agbára tàbí ìwà mímọ́ wa ni àwa fi ṣe é ti ọkùnrin yìí fi ń rìn?

  11. Ìṣe àwọn Aposteli 3:13nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ọlọ́run Abrahamu, àti Isaaki, àti Jakọbu, Ọlọ́run àwọn baba wa, òun ni ó ti yin Jesu ìránṣẹ́ rẹ̀ lógo; ẹni tí ẹ̀yin ti fi lé wọn lọ́wọ́, tí ẹ̀yin sì sẹ́ níwájú Pilatu, nígbà tí ó ti pinnu rẹ̀ láti dá a sílẹ̀.

  12. Ìṣe àwọn Aposteli 3:14nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ṣẹ́ Ẹni Mímọ́ àti Olóòótọ́ náà, ẹ̀yin sì béèrè kí a fi apànìyàn fún un yín.

  13. Ìṣe àwọn Aposteli 3:15nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ̀yin sì pa ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìyè, ẹni tí Ọlọ́run sì ti jí dìde kúrò nínú òkú; ẹlẹ́rìí èyí ti àwa jẹ́.

  14. Ìṣe àwọn Aposteli 3:16nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nípa ìgbàgbọ́ nínú orúkọ Jesu, òun ni ó mú ọkùnrin yìí láradá, ẹni tí ẹ̀yin rí, tí ẹ sì mọ̀. Orúkọ Jesu àti ìgbàgbọ́ tí ó wá nípa rẹ̀ ni ó fún un ní ìlera pípé ṣáṣá yìí ni ojú gbogbo yín.

  15. Ìṣe àwọn Aposteli 3:17nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ará, mo mọ̀ pé nípa àìmọ̀ ni ẹ̀yin fi ṣe é, gẹ́gẹ́ bí àwọn olórí yín pẹ̀lú ti ṣe.

  16. Ìṣe àwọn Aposteli 3:18nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n báyìí ni Ọlọ́run ti ṣe ìmúṣẹ àwọn ohun tí ó ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu gbogbo àwọn wòlíì pé, Kristi rẹ̀ yóò jìyà.

  17. Ìṣe àwọn Aposteli 3:19nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà ẹ ronúpìwàdà, kí ẹ sì yípadà sí Ọlọ́run, kí a lè pa ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́, kí àkókò ìtura bá a lè ti ọ̀dọ̀ Olúwa wá,

  18. Ìṣe àwọn Aposteli 3:20nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    àti kí ó ba à lè rán Kristi tí a ti yàn fún yín tẹlẹ̀: àní Jesu.

  19. Ìṣe àwọn Aposteli 3:21nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ẹni tí ọ̀run kò lé ṣàìmá gbà títí di ìgbà ìmúpadà ohun gbogbo, tí Ọlọ́run ti sọ láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ tí wọn ti ń bẹ nígbà tí ayé ti ṣẹ̀.

  20. Ìṣe àwọn Aposteli 3:22nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Mose wí pé, ‘Olúwa Ọlọ́run yín yóò gbé wòlíì kan dìde fún yín nínú àwọn arákùnrin yín, bí èmi; òun ni ẹ̀yin yóò máa gbọ́ tirẹ̀ ní ohun gbogbo tí yóò máa sọ fún un yín.

  21. Ìṣe àwọn Aposteli 3:23nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Yóò sì ṣe, olúkúlùkù ọkàn ti kò bá gbọ́ ti wòlíì náà, òun ni a ó parun pátápátá kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.’

  22. Ìṣe àwọn Aposteli 3:24nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Àní, gbogbo àwọn wòlíì láti Samuẹli wá, àti àwọn tí ó tẹ̀lé e, iye àwọn tí ó ti sọ̀rọ̀, wọn sọ ti ọjọ́ wọ̀nyí pẹ̀lú.

  23. Ìṣe àwọn Aposteli 3:25nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ̀yin ni ọmọ àwọn wòlíì, àti ti májẹ̀mú tí Ọlọ́run ti bá àwọn baba yín dá nígbà tí ó wí fún Abrahamu pé, ‘Láti ipasẹ̀ irú àwọn ọmọ rẹ̀ ni a ó ti bùkún fún gbogbo ìdílé ayé.’

  24. Ìṣe àwọn Aposteli 3:26nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà ti Ọlọ́run jí Jesu Ọmọ rẹ̀ dìde, ó kọ́ rán an sí i yín láti bùkún fún un yín, nípa yíyí olúkúlùkù yín padà kúrò nínú ìwà búburú rẹ̀.”

  25. Ìṣe àwọn Aposteli 4:1nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Bí wọn sì tí ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, àwọn àlùfáà àti olórí ẹ̀ṣọ́ tẹmpili àti àwọn Sadusi dìde sí wọn.