- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa AD 30–62
The Early Church
Pentecost ignites a movement; Peter, Paul, and countless others carry the gospel from Jerusalem to the ends of the earth.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Ìṣe àwọn Aposteli 4:27nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Àní nítòótọ́ ní Herodu àti Pọntiu Pilatu, pẹ̀lú àwọn aláìkọlà àti àwọn ènìyàn Israẹli kó ara wọn jọ ní ìlú yìí láti dìtẹ̀ sí Jesu Ìránṣẹ́ mímọ́ rẹ, ẹni tí ìwọ ti fi àmì òróró yàn,
- Ìṣe àwọn Aposteli 4:28nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
láti ṣe ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ àti ìmọ̀ rẹ̀ ti pinnu ṣáájú pé yóò ṣe.
- Ìṣe àwọn Aposteli 4:29nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ǹjẹ́ nísinsin yìí, Olúwa, kíyèsi ìhàlẹ̀ wọn; kí ó sì fi fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ láti máa fi ìgboyà ńlá sọ ọ̀rọ̀ rẹ.
- Ìṣe àwọn Aposteli 4:30nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Kí ìwọ sì fi nína ọwọ́ rẹ ṣe ìmúláradá, àti kí iṣẹ́ ìyanu máa ṣẹ̀ ní orúkọ Jesu ìránṣẹ́ mímọ́ rẹ.”
- Ìṣe àwọn Aposteli 4:31nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí wọ́n gbàdúrà tan, ibi tí wọ́n gbé péjọpọ̀ sí mì tìtì; gbogbo wọn sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọ́n sì ń fi ìgboyà sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
- Ìṣe àwọn Aposteli 4:32nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ìjọ àwọn tí ó gbàgbọ́ sì wà ní ọkàn kan àti inú kan; kò sì ṣí ẹnìkan tí ó wí pé ohun kan nínú ohun ìní rẹ̀ jẹ́ ti ara rẹ̀; ṣùgbọ́n gbogbo wọn ní ohun gbogbo ní ìṣọ̀kan.
- Ìṣe àwọn Aposteli 4:33nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Agbára ńlá ni àwọn aposteli sì fi ń jẹ́rìí àjíǹde Jesu Olúwa, oore-ọ̀fẹ́ púpọ̀ sì wà lórí gbogbo wọn.
- Ìṣe àwọn Aposteli 4:34nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí kò sí ẹnìkan nínú wọn tí ó ṣe aláìní, nítorí iye àwọn tí ó ní ilẹ̀ tàbí ilé tà wọ́n, wọ́n sì mú owó ohun tí wọn tà wá.
- Ìṣe àwọn Aposteli 4:35nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n sì fi í lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aposteli, wọn sì ń pín fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe aláìní sí.
- Ìṣe àwọn Aposteli 4:36nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Àti Josẹfu, tí a ti ọwọ́ àwọn aposteli sọ àpèlé rẹ̀ ní Barnaba (ìtumọ̀ èyí tí ń jẹ ọmọ ìtùnú), ẹ̀yà Lefi, àti ará Saipurọsi.
- Ìṣe àwọn Aposteli 4:37nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó ní ilẹ̀ kan, ó tà á, ó mú owó rẹ̀ wá, ó sì fi í lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aposteli.
- Ìṣe àwọn Aposteli 5:1nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n ọkùnrin kan ti a ń pè ni Anania, pẹ̀lú Safira aya rẹ̀, ta ilẹ̀ ìní kan.
- Ìṣe àwọn Aposteli 5:2nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nípa ìmọ̀ aya rẹ̀ ó yan apá kan pamọ́ nínú owó náà, ó sì mú apá kan rẹ̀ wá, ó sì fi í lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aposteli.
- Ìṣe àwọn Aposteli 5:3nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, “Anania, èéṣe ti Satani fi kún ọkàn rẹ láti ṣèké sí Ẹ̀mí Mímọ́, tí ìwọ sì fi yan apá kan pamọ́ nínú owó ilẹ̀ náà?
- Ìṣe àwọn Aposteli 5:4nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí ó wà níbẹ̀ tìrẹ kọ́ ní í ṣe? Nígbà tí a sì ta á tan, kò ha wà ní ìkáwọ́ rẹ̀? Èéha ti ṣe tí ìwọ fi rò nǹkan yìí lọ́kàn rẹ? Ènìyàn kọ́ ni ìwọ ṣèké sí bí kò ṣe sí Ọlọ́run?”
- Ìṣe àwọn Aposteli 5:5nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí Anania sí gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó ṣubú lulẹ̀, ó sì kú, ẹ̀rù ńlá sí ba gbogbo àwọn tí ó gbọ́.
- Ìṣe àwọn Aposteli 5:6nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sí dìde, wọ́n dì í, wọn sì gbé è jáde, wọn sì sin ín.
- Ìṣe àwọn Aposteli 5:7nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó sì tó bí ìwọ̀n wákàtí mẹ́ta, aya rẹ̀ láìmọ̀ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ó wọlé.
- Ìṣe àwọn Aposteli 5:8nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Peteru sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Wí fún mi, ṣé iye yìí ni ìwọ àti Anania gbà lórí ilẹ̀?” Ó sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, iye rẹ̀ náà ni.”
- Ìṣe àwọn Aposteli 5:9nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Peteru sí wí fún un pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fohùn ṣọ̀kan láti dán Ẹ̀mí Olúwa wò? Wò ó, ẹsẹ̀ àwọn tí ó sìnkú ọkọ rẹ ń bẹ ní ẹnu-ọ̀nà, wọn ó sì gbe ìwọ náà jáde.”
- Ìṣe àwọn Aposteli 5:10nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Lójúkan náà ó sì ṣubú lulẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀, ó sì kú; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì wọlé wọ́n bá a ní òkú, wọ́n sì gbé e jáde, wọ́n sín in lẹ́bàá ọkọ rẹ̀.
- Ìṣe àwọn Aposteli 5:11nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ẹ̀rù ńlá sì bá gbogbo ìjọ àti gbogbo àwọn tí ó gbọ́ nǹkan wọ̀nyí.
- Ìṣe àwọn Aposteli 5:12nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
A sì ti ọwọ́ àwọn aposteli ṣe iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu púpọ̀ láàrín àwọn ènìyàn. Gbogbo wọn sì fi ọkàn kan wà ní ìloro Solomoni.
- Ìṣe àwọn Aposteli 5:13nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Kò sí nínú àwọn ìyókù tí ó jẹ́ gbìyànjú láti darapọ̀ mọ́ wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ń fi ọ̀wọ̀ gíga fún wọn.
- Ìṣe àwọn Aposteli 5:14nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n síbẹ̀síbẹ̀, a sì ń yan àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin tí ó gba Olúwa gbọ́ kún iye wọn sí i.