Fò sí àkóónú

circa AD 30–62

The Early Church

Pentecost ignites a movement; Peter, Paul, and countless others carry the gospel from Jerusalem to the ends of the earth.

1,007 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Ìṣe àwọn Aposteli 1:26nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n sì dìbò fún wọn; ìbò sí mú Mattia; a sì kà á mọ́ àwọn aposteli mọ́kànlá.

  2. Ìṣe àwọn Aposteli 2:1nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ọjọ́ Pentikosti sì dé, gbogbo wọn fi ọkàn kan wà ní ibìkan.

  3. Ìṣe àwọn Aposteli 2:2nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Lójijì ìró sì ti ọ̀run wá, gẹ́gẹ́ bí ìró ẹ̀fúùfù líle, ó sì kún gbogbo ilé níbi tí wọ́n gbé jókòó.

  4. Ìṣe àwọn Aposteli 2:3nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ̀là ahọ́n bí i iná sì yọ sí wọn, ó pín, ó sì bà lé olúkúlùkù wọn.

  5. Ìṣe àwọn Aposteli 2:4nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Gbogbo wọn sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi èdè mìíràn sọ̀rọ̀, gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí ti fi fún wọn ni ohùn.

  6. Ìṣe àwọn Aposteli 2:5nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn Júù olùfọkànsìn láti orílẹ̀-èdè gbogbo lábẹ́ ọ̀run sì ń gbé Jerusalẹmu.

  7. Ìṣe àwọn Aposteli 2:6nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọn sì gbọ́ ìró yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn péjọ pẹ̀lú ìyàlẹ́nu, nítorí tí olúkúlùkù gbọ́ tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ ní èdè rẹ̀.

  8. Ìṣe àwọn Aposteli 2:7nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ẹnu sì yà wọ́n, wọn ń wí fún ara wọn pé, “Ǹjẹ́ ara Galili kọ́ ni gbogbo àwọn tí ń sọ̀rọ̀ wọ̀nyí jẹ́?

  9. Ìṣe àwọn Aposteli 2:8nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Èéha sì tí ṣe ti olúkúlùkù wa fi ń gbọ́ bí wọ́n tí ń fi èdè sọ̀rọ̀?

  10. Ìṣe àwọn Aposteli 2:9nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn ará Partia, àti Media, àti Elamu; àti àwọn tí ń gbé Mesopotamia, Judea, àti Kappadokia, Pọntu àti Asia.

  11. Ìṣe àwọn Aposteli 2:10nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Frigia, àti Pamfilia, Ejibiti, àti agbègbè Libia níhà Kirene; àti àwọn àtìpó Romu, àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe Júù

  12. Ìṣe àwọn Aposteli 2:11nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    (àti àwọn Júù àti àwọn tí a ti ipa ẹ̀sìn sọ di Júù); àwọn ará Krete àti Arabia; àwa gbọ́ tí wọ́n sọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu ńlá Ọlọ́run ni èdè wa.”

  13. Ìṣe àwọn Aposteli 2:12nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n sì wárìrì. Wọn wí fún ara wọn pé, “Kí ni èyí túmọ̀ sí?”

  14. Ìṣe àwọn Aposteli 2:13nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn ń ṣẹ̀fẹ̀, wọn sí wí pé, “Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí kún fún wáìnì tuntun”.

  15. Ìṣe àwọn Aposteli 2:14nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà ni Peteru dìde dúró pẹ̀lú àwọn mọ́kànlá yòókù, ó gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin Júù ènìyàn mi àti gbogbo ẹ̀yin tí ń gbé Jerusalẹmu, ẹ jẹ́ kí èyí kí ó yé yin; kí ẹ sì fetísí ọ̀rọ̀ mi.

  16. Ìṣe àwọn Aposteli 2:15nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn wọ̀nyí kò mu ọtí yó, bí ẹ̀yin tí rò ó; wákàtí kẹta ọjọ́ sá à ni èyí.

  17. Ìṣe àwọn Aposteli 2:16nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Bẹ́ẹ̀ kọ́, èyí ni ọ̀rọ̀ ti a ti sọ láti ẹnu wòlíì Joẹli wá pé:

  18. Ìṣe àwọn Aposteli 2:17nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Ọlọ́run wí pé, ‘Ní ìkẹyìn ọjọ́, Èmi yóò tú nínú Ẹ̀mí mí jáde sára ènìyàn gbogbo, àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin yóò máa sọtẹ́lẹ̀ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín yóò sì máa ríran, àwọn arúgbó yín yóò sì máa lá àlá,

  19. Ìṣe àwọn Aposteli 2:18nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    àti sára àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ mi ọkùnrin àti sára àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ mi obìnrin, ni Èmi yóò tú nínú Ẹ̀mí mi jáde ni ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì: wọn yóò sì máa sọtẹ́lẹ̀.

  20. Ìṣe àwọn Aposteli 2:19nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu hàn lójú ọ̀run, àti àwọn àmì nísàlẹ̀ ilẹ̀; ẹ̀jẹ̀ àti iná àti rírú èéfín;

  21. Ìṣe àwọn Aposteli 2:20nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    A ó sọ oòrùn di òkùnkùn, àti òṣùpá di ẹ̀jẹ̀, kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ ológo Olúwa tó dé.

  22. Ìṣe àwọn Aposteli 2:21nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Yóò sì ṣe, ẹnikẹ́ni tí ó bá ké pe orúkọ Olúwa ni a ó gbàlà.’

  23. Ìṣe àwọn Aposteli 2:22nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Ẹ̀yin ènìyàn Israẹli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí; Jesu tí Nasareti, ọkùnrin tí a mọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá nípa iṣẹ́ agbára àti tí ìyanu, àti àmì ti Ọlọ́run ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe láàrín yín, bí ẹ̀yin tìkára yín ti mọ̀ pẹ̀lú.

  24. Ìṣe àwọn Aposteli 2:23nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ẹni tí a ti fi lé yín lọ́wọ́ nípa ìpinnu ìmọ̀ àti ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run; àti ẹ̀yin pẹ̀lú, tí a sì pa á pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú, a kàn mọ́ àgbélébùú.

  25. Ìṣe àwọn Aposteli 2:24nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jí dìde kúrò nínú òkú, gbà á kúrò nínú ìrora ikú, nítorí tí kò ṣe é ṣe fún ikú láti dìímú.