Fò sí àkóónú

circa AD 30–62

The Early Church

Pentecost ignites a movement; Peter, Paul, and countless others carry the gospel from Jerusalem to the ends of the earth.

1,007 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Ìṣe àwọn Aposteli 19:39nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n bí ẹ ba ń wádìí ohun kan nípa ọ̀ràn mìíràn, a ó parí rẹ̀ ni àjọ tí ó tọ́.

  2. Ìṣe àwọn Aposteli 19:40nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí àwa ṣa wà nínú ewu, nítorí rògbòdìyàn tí ó bẹ́ sílẹ̀ lónìí yìí; kò ṣáá ní ìdí kan tí rògbòdìyàn yìí fi bẹ́ sílẹ̀, nítorí èyí àwa kì yóò lè dáhùn fún ìwọ́jọ yìí.”

  3. Ìṣe àwọn Aposteli 19:41nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ó sì ti sọ bẹ́ẹ̀ tan, ó tú ìjọ náà ká.

  4. Ìṣe àwọn Aposteli 20:1nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ariwo náà sí rọlẹ̀, Paulu ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, ó sì gbà wọ́n ní ìyànjú, ó dágbére fún wọn, ó dìde láti lọ sí Makedonia.

  5. Ìṣe àwọn Aposteli 20:2nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ó sì tí la apá ìhà wọ̀nyí kọjá, tí ó sì ti fi ọ̀rọ̀ púpọ̀ gbà wọ́n ní ìyànjú, ó wá sí ilẹ̀ Giriki.

  6. Ìṣe àwọn Aposteli 20:3nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì dúró níbẹ̀ ní oṣù mẹ́ta, nígbà tí àwọn Júù sì dènà dè é, bí ó ti ń pète àti bá ọkọ̀ ojú omi lọ sí Siria, ó pinnu rẹ̀ láti gbà Makedonia padà lọ.

  7. Ìṣe àwọn Aposteli 20:4nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Sopateru ará Berea ọmọ Pirusi sì bá a lọ dé Asia, àti nínú àwọn ará Tẹsalonika, Aristarku àti Sekundu, àti Gaiusi ará Dabe, àti Timotiu; Tikiku àti Tirofimu ará Asia.

  8. Ìṣe àwọn Aposteli 20:5nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí tí lọ síwájú, wọ́n dúró dè wá ni Troasi.

  9. Ìṣe àwọn Aposteli 20:6nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Àwa sì ṣíkọ̀ láti Filipi lọ lẹ́yìn àjọ àìwúkàrà, a sì dé ọ̀dọ̀ wọn ní Troasi ni ọjọ́ méje.

  10. Ìṣe àwọn Aposteli 20:7nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ọjọ́ èkínní ọ̀sẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn péjọ láti bu àkàrà, Paulu sì wàásù fún wọn, ó múra láti lọ ní ọjọ́ kejì: ó sì fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ gùn títí di àárín ọ̀gànjọ́.

  11. Ìṣe àwọn Aposteli 20:8nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Fìtílà púpọ̀ sì wà ní iyàrá òkè náà, níbi tí wọn gbé péjọ sí.

  12. Ìṣe àwọn Aposteli 20:9nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí a ń pè ní Eutiku sì jókòó lójú fèrèsé, oorun sì wọ̀ ọ́ lára; bí Paulu sì ti pẹ́ ní ìwàásù, ó ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n lójú oorun, ó ṣubú láti òkè kẹta wá sílẹ̀, a sì gbé e dìde ní òkú.

  13. Ìṣe àwọn Aposteli 20:10nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí Paulu sì sọ̀kalẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ tì i, ó sì gbé e mọ́ra, ó ní, “Ẹ má ṣe yọ ara yín lẹ́nu; nítorí tí òun wà láààyè.”

  14. Ìṣe àwọn Aposteli 20:11nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ó sì tún gòkè lọ, ó sì jẹ oúnjẹ Olúwa, ó sì sọ̀rọ̀ pẹ́ títí ó fi di àfẹ̀mọ́júmọ́, nígbà náà ni ó sì lọ.

  15. Ìṣe àwọn Aposteli 20:12nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n sì mú ọmọkùnrin náà lọ sílẹ̀ láààyè, inú gbogbo wọn sì dùn lọ́pọ̀lọ́pọ̀.

  16. Ìṣe àwọn Aposteli 20:13nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà ti àwa sì ṣáájú, àwa sì ṣíkọ̀ lọ sì Asosi, níbẹ̀ ni a ti lérò láti gba Paulu sínú ọkọ̀: nítorí bẹ́ẹ̀ ni ó tí pinnu rẹ̀, òun tìkára rẹ̀ ń fẹ́ bá ti ọ̀nà-ẹsẹ̀ lọ.

  17. Ìṣe àwọn Aposteli 20:14nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ó sì pàdé wa ní Asosi, a gbà á sínú ọkọ̀, a sì wá sí Miletu.

  18. Ìṣe àwọn Aposteli 20:15nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí a sì ṣíkọ̀ kúrò níbẹ̀, ní ọjọ́ kejì a dé ọ̀kánkán Kiosi; ní ọjọ́ kejì rẹ̀ a dé Samosi, ni ọjọ́ kejì rẹ̀ a sì dé Miletu.

  19. Ìṣe àwọn Aposteli 20:16nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Paulu ṣa ti pinnu rẹ̀ láti bá ọkọ̀ ojú omi kọjá sí Efesu, nítorí ki ó má ba à lo àkókò kankan ni Asia: nítorí tí ó ń yára bí yóò ṣe ṣe é ṣe fún un láti wà ní Jerusalẹmu lọ́jọ́ Pentikosti.

  20. Ìṣe àwọn Aposteli 20:17nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ní àti Miletu ni Paulu ti ránṣẹ́ sí Efesu, láti pé àwọn alàgbà ìjọ wá sọ́dọ̀ rẹ̀.

  21. Ìṣe àwọn Aposteli 20:18nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin tìkára yín mọ̀, láti ọjọ́ kìn-ín-ní tí mo tí dé Asia, bí mo ti bá yín gbé, ní gbogbo àkókò náà.

  22. Ìṣe àwọn Aposteli 20:19nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Bí mo ti ń fi ìrẹ̀lẹ̀ inú gbogbo sin Olúwa, àti omijé púpọ̀, pẹ̀lú ìdánwò, tí ó bá mi, nípa rìkíṣí àwọn Júù.

  23. Ìṣe àwọn Aposteli 20:20nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Bí èmí kò ti fàsẹ́yìn láti sọ ohunkóhun tí ó ṣàǹfààní fún un yín, àti láti máa kọ́ ọ yín ní gbangba àti láti ilé dé ilé.

  24. Ìṣe àwọn Aposteli 20:21nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Tí mo ń sọ fún àwọn Júù, àti fún àwọn Giriki pẹ̀lú, ní ti ìrònúpìwàdà sí Ọlọ́run, àti ti ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi Olúwa wa.

  25. Ìṣe àwọn Aposteli 20:22nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, wò ó, ẹ̀mí mi ń fà sì Jerusalẹmu, láìmọ̀ ohun tí yóò bá mi níbẹ̀.