Fò sí àkóónú

circa AD 30–62

The Early Church

Pentecost ignites a movement; Peter, Paul, and countless others carry the gospel from Jerusalem to the ends of the earth.

1,007 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Ìṣe àwọn Aposteli 19:14nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn méje kan sì wà, tí wọn ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ ẹnìkan tí a ń pè ni Sikẹfa, tí í ṣe olórí àlùfáà gíga láàrín àwọn Júù.

  2. Ìṣe àwọn Aposteli 19:15nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ̀mí búburú náà sì dáhùn, ó ní “Jesu èmi mọ̀ ọ́n, mo sì mọ Paulu pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ta ni ẹ̀yin?”

  3. Ìṣe àwọn Aposteli 19:16nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ọkùnrin tí ẹ̀mí búburú náà wà lára rẹ̀ sì fò mọ́ wọn, ó pa kúúrù mọ́ wọn, ó sì borí wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sá jáde kúrò ní ilé náà ní ìhòhò pẹ̀lú ni ìfarapa.

  4. Ìṣe àwọn Aposteli 19:17nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Ìròyìn yìí sì di mí mọ̀ fún gbogbo àwọn Júù àti àwọn ará Giriki pẹ̀lú tí ó ṣe àtìpó ní Efesu; ẹ̀rù sì ba gbogbo wọn, a sì gbé orúkọ Jesu Olúwa ga.

  5. Ìṣe àwọn Aposteli 19:18nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ sì wá, wọ́n jẹ́wọ́, wọ́n sì fi iṣẹ́ wọn hàn.

  6. Ìṣe àwọn Aposteli 19:19nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn tí ń ṣe alálúpàyídà ni ó kó ìwé wọn jọ, wọ́n dáná sun wọ́n lójú gbogbo ènìyàn. Wọ́n sì ṣírò iye wọn, wọ́n sì rí i, ó jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (50,000) ìwọ̀n fàdákà.

  7. Ìṣe àwọn Aposteli 19:20nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Olúwa gbèrú tí o sí gbilẹ̀ si í gidigidi.

  8. Ìṣe àwọn Aposteli 19:21nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Ǹjẹ́ bí nǹkan wọ̀nyí tí parí tan, Paulu pinnu nínú ọkàn rẹ̀ pé, nígbà tí òun bá kọjá ní Makedonia àti Akaia, òun ó lọ sí Jerusalẹmu, ó wí pé, “Lẹ́yìn ìgbà tí mo bá dé ibẹ̀, èmi kò lè ṣàìmá dé Romu pẹ̀lú.”

  9. Ìṣe àwọn Aposteli 19:22nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ó sì tí rán méjì nínú àwọn tí ń ṣe ìránṣẹ́ fún un lọ sí Makedonia, Timotiu àti Erastu, òun tìkára rẹ̀ dúró díẹ̀ ní ilẹ̀ Asia.

  10. Ìṣe àwọn Aposteli 19:23nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Ní àkókò náà ìrúkèrúdò díẹ̀ kan wà nítorí ọ̀nà náà.

  11. Ìṣe àwọn Aposteli 19:24nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí ọkùnrin kan tí a ń pè ní Demetriusi, alágbẹ̀dẹ fàdákà, tí o máa ń fi fàdákà ṣe ilé òrìṣà fún Artemisi, ó mú ère tí kò mọ níwọ̀n wá fún àwọn oníṣọ̀nà.

  12. Ìṣe àwọn Aposteli 19:25nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ó pè wọ́n jọ, àti irú àwọn oníṣẹ́-ọnà bẹ́ẹ̀, ó wí pé, “Alàgbà, ẹ̀yin mọ̀ pé nípa iṣẹ́ ọnà yìí ni àwa fi ní ọrọ̀ wa.

  13. Ìṣe àwọn Aposteli 19:26nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ̀yin sì rí i, ẹ sì gbọ́ pé, kì í ṣe ni Efesu nìkan ṣoṣo ni, ṣùgbọ́n ó fẹ́rẹ jẹ́ gbogbo Asia ni Paulu yìí ń yí ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́kàn padà, tí ó sì ń dárí wọn wí pé, ohun tí a fi ọwọ́ ṣe, kì í ṣe Ọlọ́run.

  14. Ìṣe àwọn Aposteli 19:27nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Kì í sì ṣe pé kìkì iṣẹ́ ọnà wa yìí ni ó wà nínú ewu dídí asán; ṣùgbọ́n tẹmpili Artemisi òrìṣà ńlá yóò di gígàn pẹ̀lú, àti gbogbo ọláńlá rẹ̀ yóò sì run, ẹni tí gbogbo Asia àti gbogbo ayé ń bọ.”

  15. Ìṣe àwọn Aposteli 19:28nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n kún fún ìbínú, wọ́n kígbe, wí pé, “Òrìṣà ńlá ni Artemisi ti ará Efesu!”

  16. Ìṣe àwọn Aposteli 19:29nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Gbogbo ìlú náà sì kún fún ìrúkèrúdò: wọ́n sì fi ọkàn kan rọ́ wọn sí inú ilé ìṣeré, wọ́n sì mú Gaiusi àti Aristarku ara Makedonia, àwọn ẹlẹgbẹ́ Paulu nínú ìrìnàjò.

  17. Ìṣe àwọn Aposteli 19:30nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà ti Paulu sì ń fẹ́ wọ àárín àwọn ènìyàn lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kọ̀ fún un.

  18. Ìṣe àwọn Aposteli 19:31nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn olórí kan ara Asia, tí i ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀, ránṣẹ́ sí i, wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó má ṣe fi ara rẹ̀ wéwu nínú ilé ìṣeré náà.

  19. Ìṣe àwọn Aposteli 19:32nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Ǹjẹ́ àwọn kan ń wí ohun kan, àwọn mìíràn ń wí òmíràn: nítorí àjọ di rúdurùdu; ọ̀pọ̀ ènìyàn ni kò sì mọ̀ ìdí ohun tí wọ́n tilẹ̀ fi péjọpọ̀.

  20. Ìṣe àwọn Aposteli 19:33nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn kan nínú àwùjọ Júù ti Aleksanderu síwájú, wọn si pàṣẹ fun láti sọ̀rọ̀. Ó juwọ́ sí wọn láti dákẹ́ kí ó ba lè wí tẹnu rẹ̀ fun àwọn ènìyàn.

  21. Ìṣe àwọn Aposteli 19:34nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n mọ̀ pé Júù ni, gbogbo wọn ni ohùn kan, bẹ̀rẹ̀ sí kígbe fún bi wákàtí méjì pé, “Òrìṣà ńlá ni Artemisi tí ará Efesu!”

  22. Ìṣe àwọn Aposteli 19:35nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí akọ̀wé ìlú sì mú kí ìjọ ènìyàn dákẹ́, “Ẹ̀yin ará Efesu, ta ni ẹni tí ó wà tí kò mọ̀ pé, ìlú Efesu ní í ṣe olùsìn Artemisi òrìṣà ńlá, àti tí ère tí ó ti ọ̀dọ̀ Jupiteri bọ́ sílẹ̀?

  23. Ìṣe àwọn Aposteli 19:36nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Ǹjẹ́ bi a kò tilẹ̀ sọ̀rọ̀-òdì sí nǹkan wọ̀nyí, ó yẹ kí ẹ dákẹ́, kí ẹ̀yin má ṣe fi ìkanra ṣe ohunkóhun.

  24. Ìṣe àwọn Aposteli 19:37nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí ti ẹ̀yin mú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí wá, wọn kò ja ilé òrìṣà lólè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sọ̀rọ̀-òdì sí òrìṣà wa.

  25. Ìṣe àwọn Aposteli 19:38nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Ǹjẹ́ nítorí náà tí Demetriusi, àti àwọn oníṣẹ́-ọnà tí o wà pẹ̀lú rẹ̀ bá ní gbólóhùn asọ̀ kan sí ẹnikẹ́ni, ilé ẹjọ́ ṣí sílẹ̀, àwọn onídàájọ́ sì ń bẹ: jẹ́ kí wọn lọ fi ara wọn sùn.