Fò sí àkóónú

circa AD 30–62

The Early Church

Pentecost ignites a movement; Peter, Paul, and countless others carry the gospel from Jerusalem to the ends of the earth.

1,007 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Ìṣe àwọn Aposteli 17:26nǹkan bí 53 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì tí tipasẹ̀ ẹnìkan dá gbogbo orílẹ̀-èdè láti tẹ̀dó sí ojú àgbáyé, ó sì ti pinnu àkókò tí a yàn tẹ́lẹ̀, àti ààlà ibùgbé wọn;

  2. Ìṣe àwọn Aposteli 17:27nǹkan bí 53 lẹ́yìn Kristi

    Ọlọ́run ṣe eléyìí kí wọn bá le máa wa, bóyá wọn yóò lè ṣàfẹ́rí rẹ̀, kí wọn sì rí í. Bí ó tilẹ̀ jẹ pé kò jìnnà sí olúkúlùkù wa.

  3. Ìṣe àwọn Aposteli 17:28nǹkan bí 53 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí nínú rẹ̀ ni àwa wà láààyè, tí a ń rìn kiri, tí a sì ní ẹ̀mí wa, bí àwọn kan nínú àwọn akéwì tí ẹ̀yin tìkára yín tí wí pé, ‘Àwa pẹ̀lú sì jẹ́ ọmọ rẹ̀.’

  4. Ìṣe àwọn Aposteli 17:29nǹkan bí 53 lẹ́yìn Kristi

    “Ǹjẹ́ bí àwa bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, kò yẹ fún wa láti rò pé, ẹni tí a wa n sìn dàbí wúrà, tàbí fàdákà, tàbí òkúta, tí a fi ọgbọ́n àti ìmọ̀ ènìyàn ya ère àwòrán rẹ̀.

  5. Ìṣe àwọn Aposteli 17:30nǹkan bí 53 lẹ́yìn Kristi

    Pẹ̀lúpẹ̀lú ìgbà àìmọ̀ yìí ni Ọlọ́run tí fojú fò dá; ṣùgbọ́n nísinsin yìí ó pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn níbi gbogbo láti ronúpìwàdà.

  6. Ìṣe àwọn Aposteli 17:31nǹkan bí 53 lẹ́yìn Kristi

    Níwọ́n bí ó ti dá ọjọ́ kan, nínú èyí tí yóò ṣe ìdájọ́ ayé lódodo nípasẹ̀ ọkùnrin náà tí ó ti yàn, nígbà tí ó ti fi ohun ìdánilójú fún gbogbo ènìyàn, ní ti pé ó jí dìde kúrò nínú òkú.”

  7. Ìṣe àwọn Aposteli 17:32nǹkan bí 53 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọ́n ti gbọ́ ti àjíǹde òkú, àwọn mìíràn ń ṣẹ̀fẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn mìíràn wí pé, “Àwa o tún nǹkan yìí gbọ́ lẹ́nu rẹ̀.”

  8. Ìṣe àwọn Aposteli 17:33nǹkan bí 53 lẹ́yìn Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni Paulu sì jáde kúrò láàrín wọn.

  9. Ìṣe àwọn Aposteli 17:34nǹkan bí 53 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin kan fi ara mọ́ ọn, wọ́n sì gbàgbọ́: nínú àwọn ẹni tí Dionisiu ara Areopagu wà, àti obìnrin kan tí a ń pè ni Damari àti àwọn mìíràn pẹ̀lú wọn.

  10. Ìṣe àwọn Aposteli 18:1nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Paulu jáde kúrò ni Ateni lọ sí Kọrinti.

  11. Ìṣe àwọn Aposteli 18:2nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì rí Júù kan tí a ń pè ní Akuila, tí a bí ni Pọntu, tí ó ti Itali dé ní lọ́ọ́lọ́ọ́, pẹ̀lú Priskilla aya rẹ̀; nítorí tí Kilaudiu pàṣẹ pé, kí gbogbo àwọn Júù jáde kúrò ní Romu. Ó sì tọ̀ wọ́n lọ láti rí wọn.

  12. Ìṣe àwọn Aposteli 18:3nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí tí òun náà jẹ́ oníṣẹ̀-ọwọ́ kan náà, ó bá wọn jókòó, ó sì ń ṣiṣẹ́: nítorí àgọ́ pípa ni iṣẹ́ ọwọ́ wọn.

  13. Ìṣe àwọn Aposteli 18:4nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì ń fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ pẹ̀lú wọn nínú Sinagọgu lọ́jọjọ́ ìsinmi, ó sì ń yí àwọn Júù àti àwọn Giriki lọ́kàn padà.

  14. Ìṣe àwọn Aposteli 18:5nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí Sila àti Timotiu sì tí Makedonia wá, ọ̀rọ̀ náà ká Paulu lára, ó ń fihàn fún àwọn Júù pé, Jesu ni Kristi náà.

  15. Ìṣe àwọn Aposteli 18:6nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọ́n sì sàtakò rẹ̀, tí wọ́n sì sọ̀rọ̀-òdì, ó gbọ́n aṣọ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀jẹ̀ yin ń bẹ lórí ara yin; ọrùn mi mọ́: láti ìsinsin yìí lọ, èmi yóò tọ àwọn aláìkọlà lọ.”

  16. Ìṣe àwọn Aposteli 18:7nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì lọ kúrò níbẹ̀, ó wọ ilé ọkùnrin kan tí a ń pé ní Titu Justu, ẹni tí o ń sin Ọlọ́run; ilé rẹ̀ sì wà lẹ́gbẹ̀ Sinagọgu tímọ́tímọ́.

  17. Ìṣe àwọn Aposteli 18:8nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Krisipu, olórí Sinagọgu, sì gba Olúwa gbọ́ pẹ̀lú gbogbo ilé rẹ̀, àti ọ̀pọ̀ nínú àwọn ara Kọrinti, nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n gbàgbọ́, a sì bamitiisi wọn.

  18. Ìṣe àwọn Aposteli 18:9nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Olúwa sì sọ fún Paulu lóru ni ojúran pé, “Má bẹ̀rù, ṣá máa sọ, má sì ṣe pa ẹnu rẹ̀ mọ́.

  19. Ìṣe àwọn Aposteli 18:10nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí tí èmí wà pẹ̀lú rẹ, kò sì sí ẹni tí yóò dìde sí ọ láti pa ọ lára: nítorí mo ní ènìyàn púpọ̀ ni ìlú yìí.”

  20. Ìṣe àwọn Aposteli 18:11nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì jókòó níbẹ̀ ní ọdún kan àti oṣù mẹ́fà, ó ń kọ́ni ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láàrín wọn.

  21. Ìṣe àwọn Aposteli 18:12nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí Gallioni sì jẹ baálẹ̀ Akaia, àwọn Júù fi ìfìmọ̀ṣọ̀kan dìde sí Paulu wọn sì mú un wá síwájú ìtẹ́ ìdájọ́.

  22. Ìṣe àwọn Aposteli 18:13nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n wí pé, “Ọkùnrin yìí ń yí àwọn ènìyàn lọ́kàn padà, láti máa sin Ọlọ́run lòdì sí òfin.”

  23. Ìṣe àwọn Aposteli 18:14nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí Paulu ń fẹ́ dáhùn, Gallioni wí fún àwọn Júù pé, “Ìbá ṣe pé ọ̀ràn búburú tàbí tí jàgídíjàgan kan ni, èmi ìbá gbè yín, ẹ̀yin Júù,

  24. Ìṣe àwọn Aposteli 18:15nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n bí ó ti ṣe ọ̀ràn nípa ọ̀rọ̀ àti orúkọ, àti ti òfin yín ni, ki ẹ̀yin bojútó o fúnra yín; nítorí tí èmi kò fẹ́ ṣe onídàájọ́ nǹkan báwọ̀nyí.”

  25. Ìṣe àwọn Aposteli 18:16nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì lé wọn kúrò ní ibi ìtẹ́ ìdájọ́.