Fò sí àkóónú

circa 1446 BC

Sinai & The Law

God meets Israel at Mount Sinai, reveals the Ten Commandments, and establishes the Tabernacle and the priestly covenant.

1,657 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Lefitiku 11:1nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé,

  2. Lefitiku 11:2nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    “Ẹ sọ fún àwọn ara Israẹli pé, ‘Nínú gbogbo ẹranko tí ń gbé lórí ilẹ̀, àwọn wọ̀nyí ni ẹ le jẹ.

  3. Lefitiku 11:3nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Gbogbo ẹranko tí pátákò ẹsẹ̀ rẹ̀ bá là tí ó sì ń jẹ àpọ̀jẹ.

  4. Lefitiku 11:4nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    “ ‘Àwọn mìíràn wà tó ń jẹ àpọ̀jẹ nìkan. Àwọn mìíràn wà tó jẹ́ pé pátákò ẹsẹ̀ wọn nìkan ni ó là, ìwọ̀nyí ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ fún àpẹẹrẹ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbákasẹ ń jẹ àpọ̀jẹ kò ya pátákò ẹsẹ̀, àìmọ́ ni èyí jẹ́.

  5. Lefitiku 11:5nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gara (ẹranko tí ó dàbí ehoro tí ń gbé inú àpáta) ń jẹ àpọ̀jẹ; aláìmọ́ ni èyí jẹ́ fún yín.

  6. Lefitiku 11:6nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ehoro ń jẹ àpọ̀jẹ, ṣùgbọ́n kò ya pátákò ẹsẹ̀; aláìmọ́ ni èyí jẹ́ fún yín.

  7. Lefitiku 11:7nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́dẹ̀ ya pátákò ẹsẹ̀ ṣùgbọ́n kì í jẹ àpọ̀jẹ; aláìmọ́ ni èyí jẹ́ fún yín.

  8. Lefitiku 11:8nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ẹ má ṣe jẹ ẹran wọn, ẹ kò sì gbọdọ̀ fọwọ́ kan òkú wọn. Àìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fún yín.

  9. Lefitiku 11:9nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    “ ‘Nínú gbogbo ohun tí Ọlọ́run dá tí ń gbé inú omi Òkun, àti nínú odò: èyíkéyìí tí ó bá ní lẹbẹ àti ìpẹ́ ni ẹ lè jẹ́.

  10. Lefitiku 11:10nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n nínú gbogbo ẹ̀dá tí ń gbé inú òkun àti nínú odò tí kò ní lẹbẹ àti ìpẹ́, yálà nínú gbogbo àwọn tí ń rákò tàbí láàrín gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè yòókù tí ń gbé inú omi àwọn ni kí ẹ kórìíra.

  11. Lefitiku 11:11nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí ẹ ti kórìíra wọn ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran wọn: ẹ gbọdọ̀ kórìíra òkú wọn.

  12. Lefitiku 11:12nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ohunkóhun tí ń gbé inú omi tí kò ní lẹbẹ àti ìpẹ́ gbọdọ̀ jásí ìríra fún yín.

  13. Lefitiku 11:13nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    “ ‘Àwọn ẹyẹ wọ̀nyí ni ẹ gbọdọ̀ kórìíra tí ẹ kò gbọdọ̀ jẹ wọ́n torí pé ohun ìríra ni wọ́n: idì, oríṣìíríṣìí igún,

  14. Lefitiku 11:14nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    àwòdì àti onírúurú àṣá,

  15. Lefitiku 11:15nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    onírúurú ẹyẹ ìwò,

  16. Lefitiku 11:16nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Òwìwí, onírúurú ògòǹgò, onírúurú ẹ̀lúùlú, onírúurú àwòdì,

  17. Lefitiku 11:17nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Òwìwí kéékèèké, onírúurú òwìwí,

  18. Lefitiku 11:18nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Òwìwí funfun àti òwìwí ilẹ̀ pápá, àti àkàlà,

  19. Lefitiku 11:19nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    àkọ̀, onírúurú òòdẹ̀, atọ́ka àti àdán.

  20. Lefitiku 11:20nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    “ ‘Gbogbo kòkòrò tí ń fò tí ó sì ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn ni wọ́n jẹ́ ìríra fún yín,

  21. Lefitiku 11:21nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    irú àwọn kòkòrò oniyẹ̀ẹ́ tí wọn sì ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn tí ẹ le jẹ nìyí, àwọn kòkòrò tí wọ́n ní ìṣẹ́po ẹsẹ̀ láti máa fi fò lórí ilẹ̀.

  22. Lefitiku 11:22nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Nínú àwọn wọ̀nyí ni ẹ lè jẹ onírúurú eṣú, onírúurú ìrẹ̀ àti onírúurú tata.

  23. Lefitiku 11:23nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n gbogbo ohun ìyókù tí ń fò, tí ń rákò, tí ó ní ẹsẹ̀ mẹ́rin, òun ni kí ẹ̀yin kí ó kà sí ìríra fún yín.

  24. Lefitiku 11:24nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    “ ‘Nípa àwọn wọ̀nyí ni ẹ le fi sọ ara yín di àìmọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú wọn yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.

  25. Lefitiku 11:25nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé òkú wọn gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.