Fò sí àkóónú

circa 1446 BC

Sinai & The Law

God meets Israel at Mount Sinai, reveals the Ten Commandments, and establishes the Tabernacle and the priestly covenant.

1,657 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Lefitiku 9:20nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    gbogbo rẹ̀ ni wọ́n kó lórí igẹ̀ ẹran náà. Aaroni sì sun ọ̀rá náà lórí pẹpẹ.

  2. Lefitiku 9:21nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Aaroni fi igẹ̀ àti itan ọ̀tún ẹran náà níwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì bí Mose ṣe pa á láṣẹ.

  3. Lefitiku 9:22nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Aaroni sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí àwọn ènìyàn, ó sì súre fún wọn. Lẹ́yìn tó sì ti rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ẹbọ sísun àti ẹbọ àlàáfíà, ó sọ̀kalẹ̀.

  4. Lefitiku 9:23nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Mose àti Aaroni sì wọ inú àgọ́ ìpàdé. Nígbà tí wọ́n jáde, wọ́n súre fún àwọn ènìyàn, ògo Olúwa sì farahàn sí gbogbo ènìyàn.

  5. Lefitiku 9:24nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Iná sì jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ó sì jó ẹbọ sísun àti ọ̀rá orí pẹpẹ. Nígbà tí gbogbo ènìyàn sì rí èyí wọ́n hó ìhó ayọ̀, wọ́n sì dojúbolẹ̀.

  6. Lefitiku 10:1nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Nadabu àti Abihu tí í ṣe ọmọ Aaroni sì mú àwo tùràrí kọ̀ọ̀kan, wọ́n fi iná àti tùràrí sínú rẹ̀, wọ́n sì rú iná àjèjì níwájú Olúwa, èyí tó lòdì sí àṣẹ Olúwa.

  7. Lefitiku 10:2nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Torí èyí, iná jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ó sì jó wọn pa, wọ́n sì kú níwájú Olúwa.

  8. Lefitiku 10:3nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Mose sì sọ fún Aaroni pé, “Ohun tí Olúwa ń sọ nípa rẹ̀ nìyìí nígbà tó wí pé, “ ‘Ní àárín àwọn tó súnmọ́ mi, Èmi yóò fi ara mi hàn ní mímọ́ ojú gbogbo ènìyàn Ní a ó ti bu ọlá fún mi.’ ” Aaroni sì dákẹ́.

  9. Lefitiku 10:4nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Mose pe Miṣaeli àti Elsafani ọmọ Usieli tí í ṣe arákùnrin Aaroni, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ wá, kí ẹ sì gbé àwọn arákùnrin yín jáde kúrò níwájú ibi mímọ́ lọ sí ẹ̀yìn ibùdó.”

  10. Lefitiku 10:5nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Wọ́n sì wá gbé wọn, pẹ̀lú ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọn ní ọrùn wọn lọ sí ẹ̀yìn ibùdó bí Mose ti sọ.

  11. Lefitiku 10:6nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Mose sọ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù, Eleasari àti Itamari pé, “ẹ má ṣe ṣọ̀fọ̀ nípa ṣíṣe aláìtọ́jú irun yín tàbí kí ẹ ṣí orí yín sílẹ̀, ẹ kò sì gbọdọ̀ ya aṣọ, bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó kùú, Olúwa yóò sì bínú sí gbogbo ìjọ ènìyàn. Ṣùgbọ́n àwọn ẹbí yín, àti gbogbo ilé Israẹli le è ṣọ̀fọ̀ lórí àwọn tí Olúwa fi iná parun.

  12. Lefitiku 10:7nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ẹ má ṣe kúrò ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, bí ẹ bá kúrò níbẹ̀, ẹ ó kù ú, nítorí pé òróró ìtasórí Olúwa wà lórí yín.” Wọ́n sì ṣe bí Mose ti wí.

  13. Lefitiku 10:8nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Olúwa sì sọ fún Aaroni pé.

  14. Lefitiku 10:9nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    “Ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ̀ kò gbọdọ̀ mu ọtí wáìnì tàbí ọtí líle mìíràn nígbàkígbà tí ẹ bá n lọ inú àgọ́ ìpàdé, bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó kù ú, èyí jẹ́ ìlànà títí láé fún un yín láti ìrandíran.

  15. Lefitiku 10:10nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ẹ gbọdọ̀ mọ ìyàtọ̀ láàrín mímọ́ àti àìmọ́, láàrín èérí àti àìléèérí.

  16. Lefitiku 10:11nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ẹ gbọdọ̀ kọ́ àwọn ara Israẹli ní gbogbo àṣẹ tí Olúwa fún wọn láti ẹnu Mose.”

  17. Lefitiku 10:12nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Mose sì sọ fún Aaroni, Eleasari àti Itamari àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù pé, “Ẹ mú ẹbọ ohun jíjẹ tó ṣẹ́kù láti inú ẹbọ àfinásun sí Olúwa, kí ẹ jẹ ẹ́ láìní ìwúkàrà nínú, lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ nítorí ó jẹ́ mímọ́ jùlọ.

  18. Lefitiku 10:13nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ẹ jẹ́ ní ibi mímọ́, nítorí pé òun ni ìpín rẹ àti ti àwọn ọmọ rẹ nínú ẹbọ tí a finá sun sí Olúwa nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe pa á láṣẹ.

  19. Lefitiku 10:14nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n ìwọ àti àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin rẹ le jẹ igẹ̀ ẹran tí a fì níwájú Olúwa àti itan tí wọ́n gbé síwájú Olúwa, kí ẹ jẹ wọ́n ní ibi tí a kà sí mímọ́, èyí ni a ti fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpín yín nínú ẹbọ àlàáfíà àwọn ara Israẹli.

  20. Lefitiku 10:15nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Itan tí wọ́n mú wá àti igẹ̀ ẹran tí ẹ fì ni ẹ gbọdọ̀ mú wá pẹ̀lú ọ̀rá ẹbọ tí a finá sun láti le è fì wọ́n níwájú Olúwa bí ẹbọ fífì. Èyí yóò sì jẹ́ ìpín tìrẹ àti ti àwọn ọmọ rẹ nígbà gbogbo bí Olúwa ṣe pàṣẹ.”

  21. Lefitiku 10:16nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Mose wádìí nípa ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tó sì rí i pé wọ́n ti sun ún, ó bínú sí Eleasari àti Itamari, àwọn ọmọ Aaroni yòókù, ó sì béèrè pé,

  22. Lefitiku 10:17nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    “Èéṣe tí ẹ kò jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà ní agbègbè ibi mímọ́? Ó jẹ́ mímọ́ jùlọ, a fi fún yín láti lè mú ẹ̀ṣẹ̀ ìjọ ènìyàn kúrò nípa fífi ṣe ètùtù fún wọn níwájú Olúwa.

  23. Lefitiku 10:18nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Níwọ́n ìgbà tí ẹ kò mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sí Ibi Mímọ́, ẹ̀ bá ti jẹ ewúrẹ́ náà ní agbègbè Ibi Mímọ́ bí mo ṣe pa á láṣẹ.”

  24. Lefitiku 10:19nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Aaroni sì dá Mose lóhùn pé, “Lónìí tí wọ́n rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ sísun wọn níwájú Olúwa ni irú èyí tún ṣẹlẹ̀ sí mi. Ǹjẹ́ inú Olúwa yóò wá dùn bí mo bá jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ lónìí?”

  25. Lefitiku 10:20nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Mose gbọ́ èyí, ọkàn rẹ̀ balẹ̀.