Fò sí àkóónú

circa 1446 BC

Sinai & The Law

God meets Israel at Mount Sinai, reveals the Ten Commandments, and establishes the Tabernacle and the priestly covenant.

1,657 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Lefitiku 8:6nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Mose mú Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá síwájú, ó sì fi omi wẹ̀ wọ́n.

  2. Lefitiku 8:7nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ó sì fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ Aaroni, ó fi àmùrè dì í, ó wọ̀ ọ́ ní efodu; aṣọ ìgúnwà, ó sì tún wọ̀ ọ́ ni aṣọ ìlekè oyè àlùfáà tí ó ní ìgbànú tí a ṣe ọnà dáradára sí.

  3. Lefitiku 8:8nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ó fi ìgbàyà sí àyà rẹ̀, ó sì fi Urimu àti Tumimu sí ibi ìgbàyà náà.

  4. Lefitiku 8:9nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ó dé e ní fìlà, ó sì fi àwo wúrà tí í ṣe adé mímọ́ síwájú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  5. Lefitiku 8:10nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Mose sì fi òróró ìtasórí ya àgọ́ àti ohun gbogbo tó wà nínú rẹ̀ sí mímọ́.

  6. Lefitiku 8:11nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ó wọ́n díẹ̀ nínú òróró yìí sórí pẹpẹ lẹ́ẹ̀méje, ó ta òróró sórí pẹpẹ àti gbogbo ohun èlò àti agbada pẹ̀lú ohun tó gbé agbada yìí dúró láti lè yà á sí mímọ́,

  7. Lefitiku 8:12nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    ó da díẹ̀ lára òróró ìtasórí yìí sórí Aaroni, ó sì yà á sí mímọ́.

  8. Lefitiku 8:13nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn èyí ló mú àwọn ọmọ Aaroni wá síwájú, ó sì fi ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀ wọ́n, ó fi àmùrè dìwọ́n lára, ó fi fìlà dé wọn lórí gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  9. Lefitiku 8:14nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ó sì mú akọ màlúù wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbọ́wọ́ lé orí ẹran náà.

  10. Lefitiku 8:15nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Mose pa akọ màlúù náà, ó sì ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà, ó fi sí orí gbogbo ìwo pẹpẹ láti wẹ pẹpẹ náà mọ́. Ó da ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ. Bẹ́ẹ̀ ní ó ṣe yà á sí mímọ́ láti ṣe ètùtù fún un.

  11. Lefitiku 8:16nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Mose tún mú gbogbo ọ̀rá tí ó bo nǹkan inú, èyí tí ó bo ẹ̀dọ̀, kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá wọn, ó sì sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ.

  12. Lefitiku 8:17nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n akọ màlúù yìí pẹ̀lú awọ àti ara ẹran àti ìgbẹ́ rẹ̀ ní ó sun lẹ́yìn ibùdó gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti paláṣẹ fún Mose.

  13. Lefitiku 8:18nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn náà ló mú àgbò wá fún ẹbọ sísun Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbọ́wọ́ lé orí àgbò náà.

  14. Lefitiku 8:19nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Mose sì pa àgbò náà, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yí pẹpẹ náà ká.

  15. Lefitiku 8:20nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ó gé àgbò náà sí wẹ́wẹ́, Mose sì sun orí àti àwọn ègé àti ọ̀rá rẹ̀.

  16. Lefitiku 8:21nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ó fi omi fọ gbogbo nǹkan inú àti ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì sun odidi àgbò náà lórí pẹpẹ bí ẹbọ sísun òórùn dídùn, ẹbọ tí a fi iná ṣe sí Olúwa gẹ́gẹ́ bí Olúwa tí pàṣẹ fún Mose.

  17. Lefitiku 8:22nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ó sì mú àgbò kejì wa, èyí ni àgbò ìfinijoyè àlùfáà, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbọ́wọ́ lé e lórí.

  18. Lefitiku 8:23nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Mose sì pa àgbò náà, ó sì mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀, ó tọ́ ọ sí etí ọ̀tún Aaroni, sórí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti ti ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀.

  19. Lefitiku 8:24nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Mose sì tún mú àwọn ọmọ Aaroni wá síwájú, ó sì mú ẹ̀jẹ̀ díẹ̀ ó fi sí etí ọ̀tún wọn, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ yí pẹpẹ náà ká.

  20. Lefitiku 8:25nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ó mú ọ̀rá ẹran náà, ìrù rẹ̀ tí ó lọ́ràá, gbogbo ọ̀rá tó wà lára nǹkan inú àti èyí tí ó bo ẹ̀dọ̀, kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá wọn pẹ̀lú itan ọ̀tún.

  21. Lefitiku 8:26nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn náà ló mú àkàrà aláìwú sí, èyí tó wà níwájú Olúwa àti àkàrà tí a fi òróró ṣe, àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́, ó sì kó gbogbo rẹ̀ sórí ọ̀rá àti itan ọ̀tún ẹran náà.

  22. Lefitiku 8:27nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ó kó gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí lé Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, wọ́n sì fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú Olúwa.

  23. Lefitiku 8:28nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn náà, Mose gba gbogbo rẹ̀ lọ́wọ́ wọn, ó sì sun wọn lórí ẹbọ sísun tó wà lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìfinijoyè àlùfáà òórùn dídùn, ẹbọ tí a fi iná sun sí Olúwa.

  24. Lefitiku 8:29nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Mose sì mú igẹ̀ ẹran náà, èyí tó jẹ́ ìpín rẹ̀ nínú àgbò fún ìfinijoyè, ó sì fì í níwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì, bi Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  25. Lefitiku 8:30nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Mose sì mú díẹ̀ lára òróró ìtasórí àti díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ láti orí pẹpẹ, ó wọ́n sára àwọn ọmọ Aaroni àti aṣọ rẹ̀, ó sì tún wọ́n sára àwọn ọmọ Aaroni àti aṣọ wọn. Bẹ́ẹ̀ ní Mose ya Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú aṣọ wọn sí mímọ́.