- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1446 BC
Sinai & The Law
God meets Israel at Mount Sinai, reveals the Ten Commandments, and establishes the Tabernacle and the priestly covenant.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Lefitiku 7:19nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
“ ‘Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran tí ó bá ti kan ohun tí a kà sí àìmọ́, sísun ni kí ẹ sun ún. Ẹnikẹ́ni tí a ti kà sí mímọ́ le è jẹ nínú ẹran tí ó kù.
- Lefitiku 7:20nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n bí ẹni tí kò mọ́ bá jẹ́ ẹran ọrẹ àlàáfíà tí ó jẹ́ tí Olúwa, a ó gé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ̀.
- Lefitiku 7:21nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Bí ẹnikẹ́ni bá fọwọ́ kan ohun aláìmọ́ yálà ohun àìmọ́ ti ènìyàn, ẹranko aláìmọ́, ohun àìmọ́ yówù kí ó jẹ́ tàbí ohunkóhun tí ó jẹ́ ìríra, tí ó sì tún jẹ́ ẹran ọrẹ àlàáfíà tó jẹ́ ti Olúwa, a ó gé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ.’ ”
- Lefitiku 7:22nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Olúwa sọ fún Mose pé,
- Lefitiku 7:23nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ẹ má ṣe jẹ ọ̀rá màlúù, àgùntàn tàbí ewúrẹ́.
- Lefitiku 7:24nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Ẹ lè lo ọ̀rá ẹran tó kú fúnra rẹ̀ tàbí èyí tí ẹranko igbó pa, fún nǹkan mìíràn, ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́.
- Lefitiku 7:25nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Ẹnikẹ́ni tó bá jẹ ọ̀rá ẹran tí a fi rú ẹbọ sísun sí Olúwa ni ẹ gbọdọ̀ gé kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ̀.
- Lefitiku 7:26nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Ẹ kò sì gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ tàbí ẹran ní gbogbo ibi tí ẹ bá ń gbé.
- Lefitiku 7:27nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ ẹ̀jẹ̀, a ó gé ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ̀.’ ”
- Lefitiku 7:28nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Olúwa sọ fún Mose pé,
- Lefitiku 7:29nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ẹnikẹ́ni tó bá mú ọrẹ àlàáfíà wá fún Olúwa.
- Lefitiku 7:30nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Pẹ̀lú ọwọ́ ara rẹ̀ ni kí ó fi mú ọrẹ tí a fi iná sun wá fún Olúwa, kí ó mú ọ̀rá àti igẹ̀, kí ó sì fi igẹ̀ yìí níwájú Olúwa bí ọrẹ fífì.
- Lefitiku 7:31nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Àlùfáà yóò sun ọ̀rá náà lórí pẹpẹ ṣùgbọ́n igẹ̀ ẹran náà jẹ́ ti Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀,
- Lefitiku 7:32nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
kí ẹ fún àlùfáà ní itan ọ̀tún lára ọrẹ àlàáfíà yín gẹ́gẹ́ bí ìpín tiyín fún àlùfáà.
- Lefitiku 7:33nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Ọmọ Aaroni ẹni tí ó rú ẹbọ ẹ̀jẹ̀ àti ọ̀rá ọrẹ àlàáfíà ni kí ó ni itan ọ̀tún gẹ́gẹ́ bí ìpín tirẹ̀.
- Lefitiku 7:34nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Nínú ọrẹ àlàáfíà àwọn ọmọ Israẹli, mo ti ya igẹ̀ tí a fi àti itan tí ẹ mú wá sọ́tọ̀ fún Aaroni àlùfáà àti àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn ní gbogbo ìgbà láti ọ̀dọ̀ ara Israẹli.’ ”
- Lefitiku 7:35nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Èyí ni ìpín tí a yà sọ́tọ̀ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ nínú ẹbọ tí a finá sun sí Olúwa lọ́jọ́ tí wọ́n mú wọn wá láti sin Olúwa gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.
- Lefitiku 7:36nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Lọ́jọ́ tí a fi òróró yàn wọ́n, ni Olúwa ti pa á láṣẹ pé kí àwọn ọmọ Israẹli máa fún wọn ní àwọn nǹkan wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn ìgbà gbogbo fún àwọn ìran tó ń bọ̀.
- Lefitiku 7:37nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Nítorí náà, àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ìlànà fún ẹbọ sísun, ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ẹbọ ẹ̀bi, ìfinijoyè àlùfáà àti ẹbọ àlàáfíà
- Lefitiku 7:38nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
èyí tí Olúwa fún Mose lórí òkè Sinai lọ́jọ́ tí Olúwa pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n máa mú ọrẹ wọn wá fún Olúwa ni ijù Sinai.
- Lefitiku 8:1nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Olúwa sọ fún Mose pé,
- Lefitiku 8:2nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
“Mú Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, aṣọ wọn, òróró ìtasórí, akọ màlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àgbò méjì àti apẹ̀rẹ̀ tí a kó àkàrà aláìwú sínú rẹ̀.
- Lefitiku 8:3nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Kí o sì kó gbogbo ìjọ ènìyàn jọ sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.”
- Lefitiku 8:4nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Mose sì ṣe bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún un, gbogbo ènìyàn sì péjọ sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ.
- Lefitiku 8:5nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Mose sì sọ fún ìjọ ènìyàn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa ti pàṣẹ pé kí á ṣe.”