- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1446 BC
Sinai & The Law
God meets Israel at Mount Sinai, reveals the Ten Commandments, and establishes the Tabernacle and the priestly covenant.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Lefitiku 5:18nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
kí ó mú àgbò kan láti inú agbo ẹran wá sọ́dọ̀ àlùfáà, fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àgbò tí kò lábùkù tí ó sì níye lórí bí iye owó ibi mímọ́. Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún ẹni náà, fún àṣìṣe tí ó ṣe láìmọ̀, a ó sì dáríjì í.
- Lefitiku 5:19nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Ẹbọ ẹ̀bi ni, ó ti jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀ sí Olúwa.”
- Lefitiku 6:1nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Olúwa sọ fún Mose pé,
- Lefitiku 6:2nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
“Bí ẹnikẹ́ni bá dẹ́ṣẹ̀ tí ó sì ṣe àìṣòótọ́ sí Olúwa nípa títan ẹnìkejì rẹ̀ lórí ohun tí wọ́n fi sí ìkáwọ́ tàbí tí wọ́n fi pamọ́ sí i lọ́wọ́, tàbí bí ó bá jalè, tàbí kí ó yan ẹnìkejì rẹ̀ jẹ,
- Lefitiku 6:3nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
tàbí kí ó rí ohun tó sọnù he tó sì parọ́ tàbí kí ó búra èké, tàbí kí ó tilẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ kan, irú èyí tí ènìyàn lè ṣẹ̀.
- Lefitiku 6:4nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Bí ó bá dẹ́ṣẹ̀ báyìí tó sì jẹ̀bi, ó gbọdọ̀ dá ohun tó jí tàbí ohun tó fi agbára gbà, tàbí ohun tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ̀, tàbí ohun tó sọnù tó rí he,
- Lefitiku 6:5nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
tàbí ohunkóhun tó búra èké lé lórí. Ó gbọdọ̀ dá gbogbo rẹ̀ padà ní pípé, kí ó fi ìdámárùn-ún iye rẹ̀ kún, kí ó sì dá gbogbo rẹ̀ padà fún ẹni tí ó ni í, ní ọjọ́ tó bá ń rú ẹbọ ẹ̀bi rẹ̀.
- Lefitiku 6:6nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Fún ìtánràn rẹ̀, ó gbọdọ̀ mú àgbò kan láti inú agbo ẹran wá fún àlùfáà, àní síwájú Olúwa, ẹbọ ẹ̀bi, àgbò aláìlábùkù, tó sì níye lórí bí iye owó ibi mímọ́.
- Lefitiku 6:7nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Báyìí ní àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún un ètùtù ìwẹ̀nùmọ́ níwájú Olúwa, a ó sì dáríjì í nítorí ohun tó ti ṣe tó sì mú un jẹ̀bi.”
- Lefitiku 6:8nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Olúwa sọ fún Mose pé,
- Lefitiku 6:9nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
“Pàṣẹ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, ‘Èyí ni ìlànà fún ẹbọ sísun; ẹbọ sísun gbọdọ̀ wà lórí pẹpẹ láti alẹ́ di òwúrọ̀, kí iná sì máa jó lórí pẹpẹ
- Lefitiku 6:10nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
kí àlùfáà sì wọ ẹ̀wù funfun rẹ̀ pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ lára rẹ̀, yóò sì kó eérú tó wà níbi ẹbọ sísun tí iná ti jó lórí pẹpẹ, sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ.
- Lefitiku 6:11nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni yóò bọ́ aṣọ rẹ̀, yóò sì wọ òmíràn, yóò wá gbé eérú náà lọ sí ẹ̀yìn ibùdó níbi tí a kà sí mímọ́.
- Lefitiku 6:12nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Iná tó wà lórí pẹpẹ gbọdọ̀ máa jó, kò gbọdọ̀ kú, ní àràárọ̀ ni kí àlùfáà máa to igi si, kí ó sì to ẹbọ sísun sórí iná, kí ó sì máa sun ọ̀rá ẹran ẹbọ àlàáfíà níbẹ̀.
- Lefitiku 6:13nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Iná gbọdọ̀ máa jó lórí pẹpẹ títí, kò gbọdọ̀ kú.
- Lefitiku 6:14nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
“ ‘Ìwọ̀nyí ni ìlànà fún ẹbọ ohun jíjẹ, kí àwọn ọmọ Aaroni gbé ẹbọ sísun náà wá síwájú Olúwa níwájú pẹpẹ.
- Lefitiku 6:15nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Kí àlùfáà bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára àti òróró pẹ̀lú gbogbo tùràrí tó wà lórí ẹbọ ohun jíjẹ náà kí ó sì sun ẹbọ ìrántí náà lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí Olúwa.
- Lefitiku 6:16nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóò jẹ ìyókù ṣùgbọ́n wọ́n gbọdọ̀ jẹ ẹ́ láìsí máa wú máa wú ohun tí ń mú àkàrà wú nínú rẹ̀ ní ibi mímọ́, ní àgbàlá àgọ́ ìpàdé ni kí wọn ó ti jẹ ẹ́.
- Lefitiku 6:17nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Ẹ má ṣe ṣè é pẹ̀lú ìwúkàrà. Èmi ti fún àwọn àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn nínú ẹbọ tí a fi iná sun sí mi. Ó jẹ́ mímọ́ jùlọ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ ẹ̀bi náà ṣe jẹ́.
- Lefitiku 6:18nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Èyíkéyìí nínú àwọn ọmọkùnrin ìran Aaroni ló le jẹ ẹ́. Èyí ni ìpín rẹ tí ó gbọdọ̀ máa ṣe déédé lára àwọn ẹbọ tí a fi iná sun sí Olúwa láti ìrandíran. Ohunkóhun tí ó bá kàn án yóò di mímọ́.’ ”
- Lefitiku 6:19nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Olúwa sọ fún Mose pé,
- Lefitiku 6:20nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
“Èyí ni ọrẹ tí Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ gbọdọ̀ mú wá fún Olúwa ní ọjọ́ tí a bá fi òróró yan ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn; ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára fún ẹbọ ohun jíjẹ lójoojúmọ́, ìdajì rẹ̀ ní àárọ̀ àti ìdajì rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́.
- Lefitiku 6:21nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Ẹ pèsè rẹ̀ pẹ̀lú òróró nínú àwo fífẹ̀, ẹ pò ó pọ̀ dáradára, kí ẹ sì gbé ọrẹ ohun jíjẹ náà wá ní ègé kéékèèké bí òórùn dídùn sí Olúwa.
- Lefitiku 6:22nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Ọmọkùnrin Aaroni tí yóò rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà tí a fi òróró yàn ni yóò rú ẹbọ náà. Ó jẹ́ ìpín ti Olúwa títí láé, wọn sì gbọdọ̀ sun ún pátápátá.
- Lefitiku 6:23nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi
Gbogbo ọrẹ ohun jíjẹ ti àlùfáà ni wọ́n gbọdọ̀ sun pátápátá, wọn kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́.”