Fò sí àkóónú

circa 1050–1010 BC

Samuel & King Saul

Israel demands a king; Samuel anoints Saul, whose disobedience leads to his rejection as God chooses a man after his own heart.

810 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. 1 Samuẹli 27:8nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi

    Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì gòkè lọ, wọ́n sì gbé ogun ti àwọn ará Geṣuri, àti àwọn ará Gesri, àti àwọn ará Amaleki àwọn wọ̀nyí ni ó sì tí ń gbé ní ilẹ̀ náà, láti ìgbà àtijọ́, bí ó ti fẹ̀ lọ sí Ṣuri títí ó fi dé ilẹ̀ Ejibiti.

  2. 1 Samuẹli 27:9nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi

    Dafidi sì kọlu ilẹ̀ náà kò sì fi ọkùnrin tàbí obìnrin sílẹ̀ láààyè, ó sì kó àgùntàn, àti màlúù, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti ìbákasẹ, àti aṣọ, ó sì yípadà ó tọ Akiṣi wá.

  3. 1 Samuẹli 27:10nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi

    Akiṣi sì bi í pé, “Níbo ni ẹ̀yin gbé rìn sí lónìí?” Dafidi sì dáhùn pé, “Sí ìhà gúúsù ti Juda ni, tàbí sí ìhà gúúsù ti Jerahmeeli,” tàbí “Sí ìhà gúúsù ti àwọn ará Keni.”

  4. 1 Samuẹli 27:11nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi

    Dafidi kò sì dá ọkùnrin tàbí obìnrin sí láààyè, láti mú ìròyìn wá sí Gati, wí pé, “Ki wọn máa bá à sọ ọ̀rọ̀ wa níbẹ̀, pé, ‘Báyìí ni Dafidi ṣe,’ ” àti bẹ́ẹ̀ ni ìṣe rẹ̀, yóò sì rí ni gbogbo ọjọ́ ti yóò fi jókòó ni ìlú àwọn Filistini.

  5. 1 Samuẹli 27:12nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi

    Akiṣi sì gba ti Dafidi gbọ́, wí pé, “Òun ti mú kí Israẹli àti àwọn ènìyàn rẹ̀ kórìíra rẹ̀ pátápátá, yóò si jẹ́ ìránṣẹ́ mi títí láé.”

  6. 1 Samuẹli 28:1nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi

    Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, àwọn Filistini sì kó àwọn ogun wọn jọ, láti bá Israẹli jà. Akiṣi sì wí fún Dafidi pé, “Mọ̀ dájúdájú pé, ìwọ yóò bá mi jáde lọ sí ibi ìjà, ìwọ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ.”

  7. 1 Samuẹli 28:2nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi

    Dafidi sì wí fún Akiṣi pé, “Nítòótọ́ ìwọ ó sì mọ ohun tí ìránṣẹ́ rẹ lè ṣe.” Akiṣi sì wí fún Dafidi pé, “Nítorí náà ni èmi ó ṣe fi ìwọ ṣe olùṣọ́ orí mi ni gbogbo ọjọ́.”

  8. 1 Samuẹli 28:3nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi

    Samuẹli sì ti kú, gbogbo Israẹli sì sọkún rẹ̀, wọ́n sì sin ín ní Rama ní ìlú rẹ̀. Saulu sì ti mú àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ọkùnrin, àti àwọn abókùúsọ̀rọ̀ obìnrin kúrò ní ilẹ̀ náà.

  9. 1 Samuẹli 28:4nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi

    Àwọn Filistini sì kó ara wọn jọ, wọ́n wá, wọ́n sì dó sí Ṣunemu: Saulu sì kó gbogbo Israẹli jọ, wọ́n sì tẹ̀dó ní Gilboa.

  10. 1 Samuẹli 28:5nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Saulu sì rí ogun àwọn Filistini náà òun sì bẹ̀rù, àyà rẹ̀ sì wárìrì gidigidi.

  11. 1 Samuẹli 28:6nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Saulu sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa, Olúwa kò dá a lóhùn nípa àlá, nípa Urimu tàbí nípa àwọn wòlíì.

  12. 1 Samuẹli 28:7nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi

    Saulu sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ bá mi wá obìnrin kan tí ó ní ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀ èmi yóò sì tọ̀ ọ́ lọ, èmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!” Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Wò ó, obìnrin kan wà ní Endori tí ó ní ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀.”

  13. 1 Samuẹli 28:8nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi

    Saulu sì pa ara dà, ó sì mú aṣọ mìíràn wọ̀, ó sì lọ, àwọn ọmọkùnrin méjì sì pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ obìnrin náà lóru: òun sì wí pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, fi ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀ wo nǹkan fún mi, kí o sì mú ẹni tí èmí ó dárúkọ rẹ̀ fún ọ wá sókè fún mi.”

  14. 1 Samuẹli 28:9nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi

    Obìnrin náà sì dá a lóhùn pé, “Wò ó, ìwọ sá à mọ ohun tí Saulu ṣe, bí òun ti gé àwọn abókùúsọ̀rọ̀ obìnrin, àti àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ọkùnrin kúrò ní ilẹ̀ náà; ǹjẹ́ èéha ṣe tí ìwọ dẹkùn fún ẹ̀mí mi, láti mú kí wọ́n pa mí.”

  15. 1 Samuẹli 28:10nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi

    Saulu sì búra fún un nípa Olúwa pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ láààyè, ìyà kan kì yóò jẹ́ ọ́ nítorí nǹkan yìí.”

  16. 1 Samuẹli 28:11nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi

    Obìnrin náà sì bi í pé, “Ta ni ẹ̀mí ó mú wá sókè fún ọ?” Òun sì wí pé, “Mú Samuẹli gòkè wá fún mi.”

  17. 1 Samuẹli 28:12nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí obìnrin náà sì rí Samuẹli, ó kígbe lóhùn rara: obìnrin náà sì bá Saulu sọ̀rọ̀ pè, “Èéṣe tí ìwọ fi tàn mí jẹ? Nítorí pé Saulu ni ìwọ jẹ́.”

  18. 1 Samuẹli 28:13nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi

    Ọba sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù; kín ni ìwọ rí?” Obìnrin náà sì wí fún Saulu pé, “Èmi rí ọlọ́run kan tí ń ti ilẹ̀ wá.”

  19. 1 Samuẹli 28:14nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi

    Ó sì bi í pé, “Báwo ni ó ti rí i sí.” Ó sì wí pé, “Ọkùnrin arúgbó kan ni ó ń bọ; ó sì fi agbádá bora.” Saulu sì mọ̀ pé, Samuẹli ni; ó sì tẹríba, ó sì wólẹ̀.

  20. 1 Samuẹli 28:15nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi

    Samuẹli sì i wí fún Saulu pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń yọ mí lẹ́nu láti mú mi wá sókè?” Saulu sì dáhùn ó sì wí pé, “Ìpọ́njú ńlá bá mi; nítorí tí àwọn Filistini ń bá mi jagun, Ọlọ́run sì kọ̀ mí sílẹ̀, kò sì dá mi lóhùn mọ́, nípa ọwọ́ àwọn wòlíì, tàbí nípa àlá; nítorí náà ni èmi ṣe pè ọ́, kí ìwọ lè fi ohun tí èmi yóò ṣe hàn mi.”

  21. 1 Samuẹli 28:16nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi

    Samuẹli sì wí pé, “Ó ti ṣe ń bi mí léèrè nígbà tí ó jẹ́ pé, Olúwa ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, o sì di ọ̀tá rẹ̀.

  22. 1 Samuẹli 28:17nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi

    Olúwa sì ṣe fún ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ti ipa ọwọ́ mi sọ: Olúwa sì yá ìjọba náà kúrò ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi fún aládùúgbò rẹ́, àní Dafidi.

  23. 1 Samuẹli 28:18nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi

    Nítorí pé ìwọ kò gbọ́ ohùn Olúwa ìwọ kò sì ṣe iṣẹ́ ìbínú rẹ̀ sí Amaleki nítorí náà ni Olúwa sì ṣe nǹkan yìí sí ọ lónìí yìí.

  24. 1 Samuẹli 28:19nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi

    Olúwa yóò sì fi Israẹli pẹ̀lú ìwọ lé àwọn Filistini lọ́wọ́, ní ọ̀la ni ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin yóò pẹ̀lú mi: Olúwa yóò sì fi ogun Israẹli lé àwọn Filistini lọ́wọ́.”

  25. 1 Samuẹli 28:20nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi

    Lójúkan náà ni Saulu ṣubú lulẹ̀ gbalaja níbí ó ṣe gùn tó, ẹ̀rù sì bà á gidigidi nítorí ọ̀rọ̀ Samuẹli; agbára kò sí fún un; nítorí pé kò jẹun ní ọjọ́ náà tọ̀sán tòru.