- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1050–1010 BC
Samuel & King Saul
Israel demands a king; Samuel anoints Saul, whose disobedience leads to his rejection as God chooses a man after his own heart.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- 1 Samuẹli 25:27nǹkan bí 1060 ṣáájú Kristi
Ǹjẹ́ èyí ni ẹ̀bùn tí ìránṣẹ́bìnrin rẹ mú wá fún olúwa mi, jẹ́ kí a sì fi fún àwọn ọmọkùnrin ti ń tọ olúwa mi lẹ́yìn.
- 1 Samuẹli 25:28nǹkan bí 1060 ṣáájú Kristi
“Èmi bẹ̀ ọ́, fi ìrékọjá arábìnrin rẹ jìn ín, nítorí Olúwa yóò sá ṣe ilé òdodo fún olúwa mi, nítorí pé ó ja ogun Olúwa. Nítorí náà kí a má ri ibi kan ni ọwọ́ rẹ níwọ̀n ìgbà tí ó wà láààyè.
- 1 Samuẹli 25:29nǹkan bí 1060 ṣáájú Kristi
Bí ọkùnrin kan bá sì dìde láti máa lépa rẹ, àti máa wá ẹ̀mí rẹ, a ó sì di ẹ̀mí olúwa mi nínú ìdì ìyè lọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run rẹ; àti ẹ̀mí àwọn ọ̀tá rẹ ni a ó sì gbọ̀n sọnù gẹ́gẹ́ bí kànnàkànnà jáde.
- 1 Samuẹli 25:30nǹkan bí 1060 ṣáájú Kristi
Yóò sì ṣe, Olúwa yóò ṣe sí olúwa mi gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìre tí ó ti wí nípa tirẹ̀, yóò sì yàn ọ́ ni aláṣẹ lórí Israẹli.
- 1 Samuẹli 25:31nǹkan bí 1060 ṣáájú Kristi
Èyí kì yóò sì jásí ìbànújẹ́ fún ọ, tàbí ìbànújẹ́ ọkàn fún olúwa mi, nítorí pé ìwọ ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, tàbí pé olúwa mi gba ẹ̀san fún ara rẹ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí Olúwa ba ṣe oore fún olúwa mi, ǹjẹ́ rántí ìránṣẹ́bìnrin rẹ!”
- 1 Samuẹli 25:32nǹkan bí 1060 ṣáájú Kristi
Dafidi sì wí fún Abigaili pé, “Alábùkún fún ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli, tí ó rán ọ lónìí yìí láti pàdé mi.
- 1 Samuẹli 25:33nǹkan bí 1060 ṣáájú Kristi
Ìbùkún ni fún ọgbọ́n rẹ, alábùkún sì ni ìwọ, tí ó da mi dúró lónìí yìí láti wá ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, àti láti fi ọwọ́ mi gba ẹ̀san fún ara mi.
- 1 Samuẹli 25:34nǹkan bí 1060 ṣáájú Kristi
Nítòótọ́, bí Olúwa Ọlọ́run Israẹli tí ń bẹ, tí ó da mi dúró láti pa ọ́ lára bí kò ṣe pé bí ìwọ ti yára tí ó sì wá pàdé mi, nítòótọ́ kì bá tí kù fún Nabali di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nínú àwọn ọkùnrin rẹ̀.”
- 1 Samuẹli 25:35nǹkan bí 1060 ṣáájú Kristi
Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì gba nǹkan tí ó mú wá fún un lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Gòkè lọ ni àlàáfíà sí ilé rẹ, wò ó, èmi ti gbọ́ ohùn rẹ, inú mi sì dùn sí ọ.”
- 1 Samuẹli 25:36nǹkan bí 1060 ṣáájú Kristi
Abigaili sì tọ Nabali wá, sì wò ó, òun sì ṣe àsè ni ilé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àsè ọba: inú Nabali sì dùn nítorí pé, ó ti mú ọtí ni àmupara; òun kò si sọ nǹkan fún un, díẹ̀ tàbí púpọ̀: títí di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀
- 1 Samuẹli 25:37nǹkan bí 1060 ṣáájú Kristi
Ó sì ṣe; ni òwúrọ̀, nígbà ti ọtí náà si dá tán lójú Nabali, obìnrin rẹ̀ sì ro nǹkan wọ̀nyí fún un, ọkàn rẹ sì kú nínú rẹ̀, òun sì dàbí òkúta.
- 1 Samuẹli 25:38nǹkan bí 1060 ṣáájú Kristi
Ó sì ṣe lẹ́yìn ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́wàá, Olúwa lu Nabali, ó sì kú.
- 1 Samuẹli 25:39nǹkan bí 1060 ṣáájú Kristi
Dafidi sì gbọ́ pé Nabali kú, ó sì wí pé, “Ìyìn ni fún Olúwa tí o gbèjà gígàn mi láti ọwọ́ Nabali wá, tí ó sì dá ìránṣẹ́ rẹ̀ dúró láti ṣe ibi: Olúwa sì yí ìkà Nabali sí orí òun tìkára rẹ̀.” Dafidi sì ránṣẹ́, ó sì ba Abigaili sọ̀rọ̀ láti mú un fi ṣe aya fún ara rẹ̀.
- 1 Samuẹli 25:40nǹkan bí 1060 ṣáájú Kristi
Àwọn ìránṣẹ́ Dafidi sì lọ sọ́dọ̀ Abigaili ni Karmeli, wọn sì sọ fún un pé, “Dafidi rán wá si ọ láti mu ọ ṣe aya rẹ̀.”
- 1 Samuẹli 25:41nǹkan bí 1060 ṣáájú Kristi
Ó sì dìde, ó sì dojúbolẹ̀, ó sì wí pé, “Wò ó, jẹ́ kí ìránṣẹ́bìnrin rẹ ó jẹ́ ìránṣẹ́ kan láti máa wẹ ẹsẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ olúwa mi.”
- 1 Samuẹli 25:42nǹkan bí 1060 ṣáájú Kristi
Abigaili sì yára, ó sì dìde, ó sì gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ márùn-ún sì tẹ̀lé e lẹ́yìn; òun sì tẹ̀lé àwọn ìránṣẹ́ Dafidi, o sì wá di aya rẹ̀.
- 1 Samuẹli 25:43nǹkan bí 1060 ṣáájú Kristi
Dafidi sì mú Ahinoamu ará Jesreeli; àwọn méjèèjì sì jẹ́ aya rẹ̀.
- 1 Samuẹli 25:44nǹkan bí 1060 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n Saulu ti fi Mikali ọmọ rẹ̀ obìnrin aya Dafidi, fún Palti ọmọ Laiṣi tí i ṣe ara Galimu.
- 1 Samuẹli 26:1nǹkan bí 1060 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni àwọn ará Sifi tọ Saulu wá sí Gibeah, wọn wí pé, “Dafidi kò ha fi ara rẹ̀ pamọ́ níbi òkè Hakila, èyí tí ó wà níwájú Jeṣimoni?”
- 1 Samuẹli 26:2nǹkan bí 1060 ṣáájú Kristi
Saulu sì dìde ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ijù Sifi ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) àṣàyàn ènìyàn ni Israẹli sì pẹ̀lú rẹ̀ láti wá Dafidi ni ijù Sifi.
- 1 Samuẹli 26:3nǹkan bí 1060 ṣáájú Kristi
Saulu sì pàgọ́ rẹ̀ ní ibi òkè Hakila tí o wà níwájú Jeṣimoni lójú ọ̀nà, Dafidi sì jókòó ni ibi ijù náà, ó sì rí pé Saulu ń tẹ̀lé òun ni ijù náà.
- 1 Samuẹli 26:4nǹkan bí 1060 ṣáájú Kristi
Dafidi sì rán ayọ́lẹ̀wò jáde, ó sì mọ nítòótọ́ pé Saulu ń bọ̀.
- 1 Samuẹli 26:5nǹkan bí 1060 ṣáájú Kristi
Dafidi sì dìde, ó sì wá sí ibi ti Saulu pàgọ́ sí: Dafidi rí ibi tí Saulu gbé dùbúlẹ̀ sí, àti Abneri ọmọ Neri, olórí ogun rẹ̀: Saulu sì dùbúlẹ̀ láàrín àwọn kẹ̀kẹ́, àwọn ènìyàn náà sì pàgọ́ wọn yí i ká.
- 1 Samuẹli 26:6nǹkan bí 1060 ṣáájú Kristi
Dafidi sì dáhùn, ó sì wí fún Ahimeleki, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Hiti, àti fún Abiṣai ọmọ Seruiah ẹ̀gbọ́n Joabu, pé, “Ta ni yóò ba mi sọ̀kalẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Saulu ni ibùdó?” Abiṣai sì wí pé, “Èmi yóò ba ọ sọ̀kalẹ̀ lọ.”
- 1 Samuẹli 26:7nǹkan bí 1060 ṣáájú Kristi
Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi àti Abiṣai sì tọ àwọn ènìyàn náà wá lóru: sì wò ó, Saulu dùbúlẹ̀ ó sì ń sùn láàrín kẹ̀kẹ́, a sì fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ gúnlẹ̀ ni ibi tìmùtìmù rẹ̀: Abneri àti àwọn ènìyàn náà sì dùbúlẹ̀ yí i ká.