Skip to content

Achish

21 ẹsẹ · 1 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Abimelech

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Achish

  1. Dafidi sì dìde, o sì sá ni ọjọ́ náà níwájú Saulu, ó sì lọ sọ́dọ̀ Akiṣi, ọba Gati.

  2. Àwọn ìránṣẹ́ Akiṣi sì wí fún un pé, “Èyí ha kọ́ ní Dafidi ọba ilẹ̀ náà? Ǹjẹ́ wọn kò ha ti dárin ti wọ́n sì gbe orin nítorí rẹ̀, tí wọ́n sì jó pé, “ ‘Saulu pa ẹgbẹ̀rún tirẹ̀. Dafidi sì pa ẹgbàárùn-ún tirẹ̀’?”

  3. Dafidi sì pa ọ̀rọ̀ wọ̀nyí í mọ́ ni ọkàn rẹ̀, ó sì bẹ̀rù Akiṣi ọba Gati gidigidi.

  4. Nígbà náà ni Akiṣi wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Wó o, nítorí kín ni ẹ̀yin ṣe mú un tọ̀ mí wá.

  5. Dafidi sì dìde, ó sì rékọjá, òun pẹ̀lú ẹgbẹ̀ta (600) ọmọkùnrin tí o ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sí Akiṣi, ọmọ Maoki, ọba Gati.

  6. Dafidi sì bá Akiṣi jókòó ní Gati, òun, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ, olúkúlùkù wọn pẹ̀lú ará ilé rẹ̀; Dafidi pẹ̀lú àwọn aya rẹ̀ méjèèjì, Ahinoamu ará Jesreeli, àti Abigaili ará Karmeli aya Nabali.

  7. Dafidi sì wí fún Akiṣi pé, “Bí ó bá jẹ́ pé èmi rí oore-ọ̀fẹ́ lójú rẹ̀, jẹ́ kí wọn ó fún mi ní ibìkan nínú àwọn ìletò wọ̀nyí; èmi yóò máa gbé ibẹ̀, èéṣe tí ìránṣẹ́ rẹ yóò sì máa bá ọ gbé ní ìlú ọba.”

  8. Akiṣi sí fi Siklagi fún un ní ọjọ́ náà nítorí náà ni Siklagi fi dí ọba Juda títí ó fi dì òní yìí.

  9. Dafidi sì kọlu ilẹ̀ náà kò sì fi ọkùnrin tàbí obìnrin sílẹ̀ láààyè, ó sì kó àgùntàn, àti màlúù, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti ìbákasẹ, àti aṣọ, ó sì yípadà ó tọ Akiṣi wá.

  10. Akiṣi sì bi í pé, “Níbo ni ẹ̀yin gbé rìn sí lónìí?” Dafidi sì dáhùn pé, “Sí ìhà gúúsù ti Juda ni, tàbí sí ìhà gúúsù ti Jerahmeeli,” tàbí “Sí ìhà gúúsù ti àwọn ará Keni.”

  11. Akiṣi sì gba ti Dafidi gbọ́, wí pé, “Òun ti mú kí Israẹli àti àwọn ènìyàn rẹ̀ kórìíra rẹ̀ pátápátá, yóò si jẹ́ ìránṣẹ́ mi títí láé.”

  12. Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, àwọn Filistini sì kó àwọn ogun wọn jọ, láti bá Israẹli jà. Akiṣi sì wí fún Dafidi pé, “Mọ̀ dájúdájú pé, ìwọ yóò bá mi jáde lọ sí ibi ìjà, ìwọ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ.”

  13. Dafidi sì wí fún Akiṣi pé, “Nítòótọ́ ìwọ ó sì mọ ohun tí ìránṣẹ́ rẹ lè ṣe.” Akiṣi sì wí fún Dafidi pé, “Nítorí náà ni èmi ó ṣe fi ìwọ ṣe olùṣọ́ orí mi ni gbogbo ọjọ́.”

  14. Àwọn ìjòyè Filistini sì kọjá ní ọ̀rọ̀ọ̀rún àti lẹgbẹẹgbẹ̀rún; Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pẹ̀lú Akiṣi sì kẹ́yìn.

  15. Àwọn ìjòyè Filistini sì béèrè wí pé, “Kín ni àwọn Heberu ń ṣe níhìn-ín yìí?” Akiṣi sì wí fún àwọn ìjòyè Filistini pé “Dafidi kọ yìí, ìránṣẹ́ Saulu ọba Israẹli, tí ó wà lọ́dọ̀ mi láti ọjọ́ wọ̀nyí tàbí láti ọdún wọ̀nyí, èmi kò ì tì í rí àṣìṣe kan ni ọwọ́ rẹ̀ láti ọjọ́ tí ó ti dé ọ̀dọ̀ mi títí di òní yìí.”

  16. Akiṣi sì pe Dafidi, ó sì wí fún un pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ láààyè, ìwọ jẹ́ olóòótọ́ àti ẹni ìwà rere lójú mi, ní àlọ rẹ àti ààbọ̀ rẹ pẹ̀lú mi ní ogun: nítorí pé èmi ko tí ì ri búburú kan lọ́wọ́ rẹ́ láti ọjọ́ ti ìwọ ti tọ̀ mí wá, títí o fi dì òní yìí ṣùgbọ́n lójú àwọn ìjòyè, ìwọ kò ṣe ẹni tí ó tọ́.

  17. Dafidi sì wí fún Akiṣi pé, “Kín ni èmi ṣe? Kín ni ìwọ sì rí lọ́wọ́ ìránṣẹ́ rẹ láti ọjọ́ ti èmi ti ń gbé níwájú rẹ títí di òní yìí, tí èmi kì yóò fi lọ bá àwọn ọ̀tá ọba jà.”

  18. Akiṣi sì dáhùn, ó sì wí fún Dafidi pé, “Èmi mọ̀ pé ìwọ ṣe ẹni rere lójú mi, bi angẹli Ọlọ́run; ṣùgbọ́n àwọn ìjòyè Filistini wí pé, ‘Òun kì yóò bá wa lọ sí ogun.’

  19. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ Ṣimei méjì sì sálọ sọ́dọ̀ Akiṣi ọmọ Maaka, ọba Gati, a sì sọ fún Ṣimei pé, “Àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ méjì wà ní Gati.”

  20. Fún ìdí èyí, ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó sì lọ sọ́dọ̀ Akiṣi ní Gati láti wá àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni Ṣimei sì lọ, ó sì mú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ padà bọ̀ láti Gati.

  21. Tí Dafidi. Nígbà tí ó díbọ́n bí ẹni tí ń ṣe wèrè níwájú Abimeleki, ẹni tí ó lé e lọ, ó sì jáde lọ. Èmi yóò máa fi ìbùkún fún Olúwa nígbà gbogbo; ìyìn rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi títí láé.