Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Punishments

133 ẹsẹ · 47 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Kaini wí fún Olúwa pé, “Ẹrù ìyà ẹ̀ṣẹ̀ mi pọ̀ ju èyí tí mo le rù lọ.

  2. Lónìí, ìwọ lé mi kúrò lórí ilẹ̀, mó sì di ẹni tí ó fi ara pamọ́ kúrò ní ojú rẹ, èmi yóò sì di ìsáǹsá àti alárìnkiri ní ayé, ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi, yóò sì pa mí.”

  3. Lẹ́yìn nǹkan bí oṣù mẹ́ta, wọn sọ fún Juda pé, “Tamari aya ọmọ rẹ̀ ṣe àgbèrè, ó sì ti lóyún.” Juda sì wí pé, “Ẹ mú un jáde, kí ẹ sì dá iná sun ún.”

  4. Láàrín ọjọ́ mẹ́ta, Farao yóò tú ọ sílẹ̀, yóò sì bẹ́ orí rẹ, yóò sì gbé ara rẹ kọ́ sí orí igi. Àwọn ẹyẹ yóò sì jẹ ara rẹ.”

  5. “Bí àwọn ènìyàn ti ń jà bá pa aboyún lára, tí aboyún náà bá bímọ láìpé ọjọ́, ṣùgbọ́n tí kò sí aburú mìíràn mọ́ lẹ́yìn rẹ̀, ẹni tí ó fa ìpalára yìí yóò san iyekíye tí ọkọ aboyún náà bá béèrè fún, bí ilé ẹjọ́ bá ṣe gbà láààyè gẹ́gẹ́ bí owó ìtánràn.

  6. Ojú fún ojú, eyín fún eyín, ọwọ́ fún ọwọ́, ẹsẹ̀ fún ẹsẹ̀,

  7. Ṣùgbọ́n tí ó bá ti di ìgbà gbogbo ti akọ màlúù náà ti máa ń kan ènìyàn, tí a sì ti ń kìlọ̀ fún olówó rẹ̀, ti olówó rẹ̀ kò sì mú un so, tí ó bá kan ọkùnrin tàbí obìnrin pa, a ó sọ akọ màlúù náà ní òkúta pa, a ó sì pa olówó rẹ̀ pẹ̀lú.

  8. Bí àwọn ará ilé ẹni tí ó kú bá béèrè fún owó ìtánràn, yóò san iye owó tí wọ́n bá ní kí ó san fún owó ìtánràn láti fi ra ẹ̀mí ara rẹ̀ padà.

  9. Ṣùgbọ́n tí ó bá ti di ìgbà gbogbo tí akọ màlúù náà máa ń kan òmíràn, tí olówó rẹ̀ kò sì mú un so, olówó rẹ̀ yóò san ẹran dípò ẹran. Ẹran tí ó kú yóò sì jẹ́ tirẹ̀.

  10. “Bí ọkùnrin kan bá jí akọ màlúù tàbí àgùntàn, tí ó sì pa á tàbí tà á. Ó gbọdọ̀ san akọ màlúù márùn-ún padà fún ọ̀kan tí ó jí, àti àgùntàn mẹ́rin mìíràn fún ọ̀kan tí ó jí.

  11. “Bí a bá mú olè níbi ti ó ti ń fọ́lé, ti a sì lù ú pa, ẹni tí ó lù ú pa náà kò ní ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀.

  12. Ṣùgbọ́n ti ó bá ṣẹlẹ̀ ni ojú ọ̀sán, a ó kà á si ìpànìyàn. Ọkùnrin ti ó lù ú pa náà yóò ni ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀. “Olè gbọdọ̀ san ohun tí ó jí padà. Ṣùgbọ́n tí kò bá ni ohun ti ó lè fi san án padà, a ó tà á, a ó sì fi sanwó ohun tí ó jí gbé padà.

  13. Bí a bá rí ẹran tí ó jí gbé náà ni ọwọ́ rẹ̀ ní ààyè: ìbá ṣe akọ màlúù, akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí àgùntàn, yóò san án padà ní ìlọ́po méjì.

  14. Bí ó bá dẹ́ṣẹ̀ báyìí tó sì jẹ̀bi, ó gbọdọ̀ dá ohun tó jí tàbí ohun tó fi agbára gbà, tàbí ohun tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ̀, tàbí ohun tó sọnù tó rí he,

  15. tàbí ohunkóhun tó búra èké lé lórí. Ó gbọdọ̀ dá gbogbo rẹ̀ padà ní pípé, kí ó fi ìdámárùn-ún iye rẹ̀ kún, kí ó sì dá gbogbo rẹ̀ padà fún ẹni tí ó ni í, ní ọjọ́ tó bá ń rú ẹbọ ẹ̀bi rẹ̀.

  16. “Sọ fún àwọn ará Israẹli pé, ‘Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ará Israẹli tàbí àwọn àlejò tí ń gbé láàrín Israẹli, tí ó bá fi èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ rẹ̀ fún Moleki, kí wọ́n pa á, kí àwọn olùgbé ilẹ̀ náà sọ ọ́ ní òkúta pa.

  17. “ ‘Bí ọkùnrin kan bá fẹ́ tìyátọmọ papọ̀, ìwà búburú ni èyí: iná ni kí ẹ fi sun wọ́n, òun àti àwọn méjèèjì, kí ìwà búburú má ba à gbilẹ̀ láàrín yín.

  18. “Mú asọ̀rọ̀-òdì náà jáde wá sẹ́yìn àgọ́, kí gbogbo àwọn tí ó gbọ́ pé ó ṣépè gbé ọwọ́ wọn lórí ọkùnrin náà láti fihàn pé ó jẹ̀bi. Lẹ́yìn náà ni kí gbogbo àpéjọpọ̀, sọ ọ́ ní òkúta pa.

  19. Ẹni tí ó bá gba ẹ̀mí ẹran ọ̀sìn ẹlòmíràn, kí ó dá a padà—ẹ̀mí dípò ẹ̀mí.

  20. wọ́n fi sí ìpamọ́ nítorí pé ohun tí wọn ó ṣe fún un kò tí ì yé wọn.

  21. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Kíkú ni ọkùnrin náà yóò kú kí gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli sọ ọ́ lókùúta pa ní ẹ̀yìn ibùdó.”

  22. Wọ́n mú un jáde sí ẹ̀yìn ibùdó, gbogbo ìjọ ènìyàn sì sọ ọ́ lókùúta pa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  23. Olúwa sọ fún Mose pé, “Mú gbogbo àwọn olórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, pa wọ́n kí o sì fi wọ́n kọ́ sórí igi ní gbangba nínú oòrùn níwájú Olúwa, kí ìbínú Olúwa lè kúrò ní ọ̀dọ̀ Israẹli.”

  24. “ ‘Má ṣe gba ohun ìràpadà fún ẹ̀mí apànìyàn, tí ó jẹ̀bi kí ó kú. Ṣùgbọ́n pípa ni kí a pa á.

  25. “ ‘Má ṣe gba ìràsílẹ̀ fún ẹnikẹ́ni tí ó bá lọ sí ìlú ìsásí, pe kí ó padà máa gbé ní ilẹ̀ tirẹ̀ kí ó tó di ìgbà ikú olórí àlùfáà.