Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Punishments: By the witnesses
Àwọn ẹsẹ nípa By the witnesses
Ṣùgbọ́n pípa ni kí o pa á. Ọwọ́ rẹ ni yóò kọ́kọ́ wà lára rẹ̀ láti pa á, lẹ́yìn náà ọwọ́ gbogbo ènìyàn.
Àwọn ẹlẹ́rìí ni kí ó kọ́kọ́ gbọ́wọ́ lé e láti pa á. Lẹ́yìn èyí ni kí gbogbo ènìyàn dáwọ́jọ láti pa á. Nípa báyìí, ẹ̀yin yóò sì fọ ohun búburú náà mọ́ kúrò ní àárín yín.
Nígbà tí wọ́n ń bi í léèrè lemọ́lemọ́, ó gbe orí rẹ sókè, ó sì wí fún wọn pé, “Jẹ́ kí ẹni tí ó wà láìní ẹ̀ṣẹ̀ nínú yín kọ́kọ́ sọ òkúta lù ú.”
wọ́n sì wọ́ ọ sẹ́yìn òde ìlú, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sísọ ọ́ ní òkúta; àwọn ẹlẹ́rìí sì fi aṣọ wọn lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ ọmọkùnrin kan tí a ń pè ní Saulu.
Bí wọ́n ti ń sọ Stefanu ní òkúta, ó sì ké pe Olúwa wí pé, “Jesu Olúwa, gba ẹ̀mí mi.”