Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Punishments: Scourging

5 ẹsẹ · 47 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Scourging

  1. Bí ó bá tọ́ láti na ẹlẹ́bi, kí onídàájọ́ dá a dọ̀bálẹ̀ kí a sì nà án ní ojú u rẹ̀ ní iye pàṣán tí ó tọ́ sí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sẹ̀.

  2. Ṣùgbọ́n kò gbọdọ̀ fún un ju ogójì pàṣán lọ. Bí ó bá nà án ju bẹ́ẹ̀ lọ, arákùnrin rẹ̀ yóò di ẹni ìrẹ̀sílẹ̀ ní ojú rẹ̀.

  3. Nígbà náà ni Pilatu dá Baraba sílẹ̀ fún wọn. Lẹ́yìn tí òun ti na Jesu tán, ó fi í lé wọn lọ́wọ́ láti mú un lọ kàn mọ́ àgbélébùú.

  4. Bí wọ́n sí tí fi ọṣán dè é, Paulu bí balógun ọ̀rún tí ó dúró tì í pé, “Ó ha tọ́ fún yín láti na ẹni tí i ṣe ará Romu ni àìdálẹ́bi bí?”

  5. Nígbà márùn-ún ni mo gba pàṣán ogójì dín ẹyọ kan lọ́wọ́ àwọn Júù.